Ṣé lóòótọ́ làwọn agbébọn ya wọ àdúgbò kan ní ìpínlẹ̀ Eko?

Agbebọn to gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, ANADOLU AJANSI

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe irọ ni iroyin kan to n lọ nigboro pe awọn agbebọn ya bo agbegbe Ajebo, lẹba Agbowa, to wa ni Ikosi-Ejirin LCDA nibi ti wọn ti ṣina ibọn bolẹ, ṣe araalu leṣẹ ti wọn tun ko ọpọ dukia wọn lọ.

Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ gbode pe awọn agbebọn ya bo Ajebo ti wọn si sẹ awọn olugbe agbagbe naa leṣe ki ọlọpaa to yọju sibẹ.

Iroyin naa ni fun nnkan bii wakati mẹwaa o le lawọn agbebọn naa fi ṣọṣe eyii to mu ki ọpọ awọn olugbe agbegbe naa sa fi ile wọn silẹ ki wọn ma ba a fara gbọta ibọn.

Gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ, awọn agbebọn naa tun ko ohun ija oloro mii bi aake ati ada lọwọ.

Iroyin naa ni olori agbegbe ọhun juwe ikọlu naa bii eyi to ba awọn lẹru gidi gan, wọn ni o tun sọ pe awọn janduku naa ko igi dina lasiko ti ọlọpaa de lati da si ọrọ naa.

Irọ ni, ko si ohun to jọ bẹẹ - Ọlọpaa

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Abimbola Adebisi,

Oríṣun àwòrán, SP Abimbola Adebisi,

Amọ ṣa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti juwe iroyin naa gẹgẹ bii eyii ti ko si ootọ kankan ninu rẹ ati iroyin ẹlẹjẹ paraku.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, SP Abimbola Adebisi, sọ ninu atẹjade kan pe ija ilẹ laarin mọlẹbi meji lo waye kii ṣe ikọlu awọn janduku.

Abimbola ni irọ ni iroyin to gba iboro pe awọn janduku lo kọlu adugbo naa, iroyin aṣinilọna si ni pẹlu.

O ni apapọ akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa to fi mọ awọn oṣiṣẹ PMF anti-riot lo pana rogbodiyan naa.

Ọlọpaa ni "ija ilẹ laarin mọlẹbi meji lo waye ni Ajebo eyii to fa wahala ati rogbodiyan labule naa.

"Awọn ọlọpaa da alaafia pada si agbegbe naa, gbogbo awọn olugbe ibẹ si ti n gbe ni ayọ ati laafia bayii."

Ẹwẹ, o ni Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa rogbodiyan haa.

Kọmiṣọna ọhun tun kilọ fun awọn araalu ki wọn ṣọra fun gbigbe iroyin ẹlẹjẹ kiri.