Olórí ọ̀dọ́, Afọbajẹ àti ẹgbẹ́ obìnrin ní Epe Ekiti ṣàlàyé ìwà ẹ̀gbin tí ọba hù, tí wọ́n ṣe lé e kúrò nínú ìlú

Oríṣun àwòrán, @ekititrends/screenshot
Awọn ara ilu Epe-Ekiti ni ijoba ibile Ijero ni ipinlẹ Ekiti ti ke si ijoba Ekiti lati bawọn fi aṣẹ si igbesọ ti wọn gbe lati rọ Ọba wọn Ayọdeji Williams Adesoye lóye.
Ṣaaju ni awọn ọmọ ilu Epe Ekiti ti fi ẹsun oriṣiriṣi kan Ọba Ayọdeji nipa aṣilo ipo rẹ lori itẹ awọn babanla rẹ.
Wọn si fariga pe eewọ nla ni iru iwa yii nilẹ Yoruba, ti wọn si taku pe lilọ ni oriade naa yoo lọ kuro ninu ilu naa fun awọn tori oriṣiriṣi ajalu ibi ti o le ti ẹyin rẹ yọ.
Ninu ọrọ rẹ pẹlu Akọroyin BBC News Yoruba, Oloye agba Olajide Dada, ti o jẹ igbakeji Ọba ati Olori awọn Afọbajẹ ni ilu Epe-Ekiti ṣalaye orisirisi awọn iwa ẹgbin tí oríadé náà hu bii fifi aṣẹ ilu ṣepe fun awọn Ọmọ ìlú.
O ni awọn araalu lo taku pẹlu ifẹhonuhan pe ki ìjọba ipinle Ekiti rọ Ọba Ayọdeji loye, ki ilu Epe-Ekiti ma ba a tuka.
"Gbogbo Ori Ade ni ìjọba ìbílẹ̀ Ijero ti pe ipade alaafia laaarin Ọba Adesoye ati awọn ara Epe-Ekiti, sugbọn wọn fariga pe lilọ ni Ọba naa yoo lọ fun awọn"
Olori awọn Afọbajẹ naa tun fidi rẹ mulẹ pẹlu awọn aworan pé, Ọba Adesoye tapa si awọn eewọ ti o rọ mọ aṣẹ ìlú, lẹyin ti wọn gbe fun-un loju gbogbo ilu pẹlu ọpọlọpọ ikilọ, pe ti o ba tapa si gbogbo ikilọ yii, awọn ara ilu yo o kọ ọ ni Ọba.
O tẹsiwaju pé, ọpọlọpọ igba ni wọn ti pe akiyesi Ọba Adesoye si awọn iwa ti o n tabuku ilu ṣugbọn to ni Ọba naa kọ eti ikun sawọn ipade Alafia ti wọn ti pe e si ko to di pe gbogbo rẹ di isu ata yanyan.
Agba Oye Dada ni, gbogbo ilu ti gba aṣẹ naa kuro lọwọ Ọba Adesoye, ti aṣẹ naa nikan si gbọdọ da wa ninu aafin fun oṣupa mẹta, ki wọn to le mọ boya aṣẹ naa pe iye rẹ bi wọn ṣe gbe fun Ọba ti wọn le kuro lori itẹ naa.
Saaju naa ni gbogbo awọn Ori Ade ati lọbalọba ni ìjọba ìbílẹ̀ Ijero ti pe ipade alaafia laaarin Ọba Adesoye ati awọn ara ilu Epe-Ekiti, sugbọn ti awọn ara ilu naa fariga pe lilọ ni Ọba naa yoo lọ fun awọn.
"Awọn ọdọ ilu koju Ọba Adesoye tori bi gbogbo awọn ti ọba ba ja, ṣe n ku iku ọsan gangan laipe ọjọ"
Igba kẹta Obinrinle ilu Epe-Ekiti, Bamidele Ajayi, tun salaye lori bi Ọba Adesoye ṣe gbe àṣẹ ilu jade loju gbogbo ara ilu to fi ṣepe ni kíkankíkan pẹlu aṣọ pupa lara.
O sọ nipa bi awọn ọdọ ilu ṣe koju Ọba Adesoye tori bi gbogbo awọn ti ọba ba ja, ṣe n ku iku ọsan gangan laipe ọjọ.
Igbakẹta Obinrinle naa wa parọwa si ìjọba ipinlẹ Ekiti pe ki wọn ma ṣe yi ipinnu awọn ara ilu Epe-Ekiti pada tori ewu nla to ro mọ.
Olori awọn ọdọ ilu Epe-Ekiti, Ogbeni Akinyemi Kayode, salaye awọn iwa idojutini ati asilo agbara aṣẹ ilu ti Ọba Adesoye lo lọna aitọ èyí ti n pa ilu naa lara pẹlu iwa ibi rẹ, ti ko si jẹ ki alaafia jọba ninu ilu Epe Ekiti.
Aṣaaju awọn Ọdọ ilu naa ti n fi ẹhonu han pe ki wọn gba apere nidi ọba tori awọn iwa to n hu.
O ni o mu ki awọn Ọdọọ ilu Epe yari pe eewọ nla ni iru iwa yii nilẹ Yoruba, ti wọn si taku pe lilọ ni oriade naa yoo lọ kuro ninu ilu naa fun awọn.
Igbesẹ wọn yii lo ti n kọ ọpọ eeyan lominu, tawọn araalu naa si taku pẹlu ifẹhonuhan wọn pe ododo gbọdọ leke pẹlu ifọwọsowọpọ ijọba ipinlẹ Ekiti.
Nigba ti Ọba Ayọdeji Adesoye fi esi ọrọ ilu nibi ipe alaafia ti awọn ara ilu Epe ti rọ Ọba naa loye ṣáájú, ni Ọba Adesoye ti rawo ẹbẹ si ara ilu lati fi iyedenu lori gbogbo rògbòdìyàn naa.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí wọn ṣe lé odidi ọba, ẹni ọdún 37 kúrò láàrin ìlu, gbẹ́sẹ̀ lé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀
Kí ló le mu ki ẹgbẹlẹgbẹ araalu le odidi ọba kuro ni ilu, ti wọn si tun gbẹsẹle ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, jo taya ọkọ naa?
Ki ni ọba naa se to bẹẹ to fi kan abuku bii eyi, se idojuti yii ko wa buru jai?
Ibeere ti ọpọ eeyan ti kii se ọmọ Epe Ekiti, to wa nijọba ibilẹ Ijero nipìnlẹ Ekiti n beere ree nitori isẹlẹ nla to waye nilu naa laipẹ yii.
Ẹgbẹlẹgbẹ araalu naa lo sin Elepe tilu Epe, Ọba Ayọdeji Williams Adesoye jade kuro laarin ilu naa.
Fidio kan to gba ori ayelujara kan wa se afihan bi oriade naa se kuro ninu ilu ọhun pẹlu idojuti nla, tawọn agbofinro si sin lọwọọwọ pẹlu rẹ.
Koda, wọn ko tun jẹ ki oriade naa gbe ọkọ ayọkẹlẹ Lexus rẹ kuro ninu ilu naa, se ni awọn araalu gbẹsẹle ọkọ naa, ti wọn si tun jo taya rẹ mẹrẹẹrin.

Oríṣun àwòrán, @ekititrends/Screeshot
Ki ni Elepe se ti wọn fi le kuro nilu?
Nigba ti wọn n salaye awọn ẹsẹ Ọba Adesoye, ti wọn se le kuro ninu ilu Epe, awọn ọdọ ilu naa fi oniruuru ẹsun kan oriade naa, ti wọn lo fi sẹ awọn.
Wọn ni ọjọ ti pẹ ti awọn ti n fi ẹhonu han pe ki wọn gba apere nidi ọba ọhun tori awọn iwa to n hu.
Awọn ọdọ naa ni se ni Ọba Adesoye n pa ilu naa lara pẹlu iwa ibi rẹ, ti ko si jẹ ki alaafia jọba ninu ilu Epe Ekiti.
Gẹgẹ bi a se gbọ, ọrọ aawọ ilẹ lo sokunfa ibẹrẹ wahala naa, amọ ti ọrọ naa fọn ina soju lẹyin o rẹyin.
Idi ni pe wọn ni Elepe gbe àfọ̀ṣẹ jade, to si n fi sepe fawọn ọdọ ilu ti ọrọ ilẹ naa kan.
Awọn olugbe ilu Epe Ekiti ni eewọ nla ni iru iwa yii nilẹ Yoruba, ti wọn si taku pe lilọ ni oriade naa yoo lọ kuro ninu ilu naa fun awọn.
Igbesẹ wọn yii lo ti n kọ ọpọ eeyan lominu, tawọn araalu naa si taku pẹlu ifẹhonuhan wọn pe ododo gbọdọ leke.
Isẹlẹ yii di isu ata yan-an-yan-an, tawọn ti isẹlẹ naa si soju wọn salaye pe awọn ọdọ ati gbogbo ilu lapapọ lo kopa ninu iwọde lati le ọba naa kuro lori allefa.
Se ni wọn gbe akọle oniruuru lọwọ, ti wọn si ya bo aafin Elepe pe ko kuro lori apere ọba.
Bakan naa, wọn rọ ijọba ipinlẹ Ekiti ati igbimọ lọbalọba nipinlẹ naa lati bawọn da si ọrọ yii, ki wọn si wa ojutu si.

Oríṣun àwòrán, Ayodeji Williams Adesoye/Facebook
Ta ni Ọba Ayodeji Williams Adesoye, Elepe tilu Epe?
Ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kẹsan ọdun 1988 ni wọn bi Ayodeji Williams Adesoye sile aye, eyiun ọ̀dun mẹtadinlogoji sẹyin.
Idile ọba Arowosapo nilu Epe Ekiti nijọba ibilẹ Ijero, si ni wọn bi si.
O lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, ko to gba ile ẹkọ fasiti Ibadan lọ lati kọ nipa ẹkọ nipa igbe aye ẹda, Philosophy.
Ọdun 2020 ni Ayodeji Adesoye di Elepe tilu Epe lẹni ọdun mejilelọgbọn, oun si ni Elepe Kẹẹdogun fun ilu naa.
Asiko isejọba gomina Kayode Fayemi si ni o jẹ Ọba, ẹni to gbe ade le lori.
Ipo Elepe lo sofo nigba ti Ọba Emmanuel Agbeoba, to wa lati idile Ọba Ogodulose waja ni ọgbọnjọ osu Kọkanla ọdun 2018.














