Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà tún gbé ìdájọ́ ikú kalẹ̀ fún Maryam Sanda

Maryam Sanda n wo ẹrọ ayaworan

Oríṣun àwòrán, AONANUGA1956/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ to ga julọ Naijiria ti ni idajọ iku ti wọn da fun Maryam Sanda ṣi duro.

Awọn adajọ mẹrin ninu adajọ marun-un ti ile ẹjọ naa sọ pe idajọ to ni ki wọn lọ yẹgi fun-un ti ẹmi fi maa bọ lọrun rẹ ṣi duro.

Ile ẹjọ naa ni ẹjọ Kotẹmilọrun ti obinrin naa pe lati yi idajọ iku ti wọn fun pada ko rẹsẹ walẹ, ti wọn si da ẹjọ kotẹmilọrun naa nu.

Idajọ naa, ti Adajọ Moore Adumein ṣaaju rẹ sọ pe awọn to olupẹjọ ṣe iṣẹ rẹ bo ṣe yẹ, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe Maryam Sanda ṣẹṣẹ to ṣẹ naa ti wọn fi dajọ iku fun-un.

Bakan naa lo ni idajọ ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun gbe kalẹ dára, tí kò sí ohunkóhun tó ṣe ìdájọ́ náà.

Ile ẹjọ naa fi kun pe ko yẹ ki Aarẹ Tinubu lo agbara rẹ lati mu adinku tabi mu ayipada ba idajọ ti ile ẹjọ fun Maryam Sanda nitori ẹjọ kotẹmilọrun ti Sanda pe ṣi wa nile ẹjọ.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ẹ o ranti pe ni oṣu Kẹwaa ni Aarẹ Tinubu ti kede pe oun da Sanda to gun ọkọ rẹ lọbẹ pa silẹ lẹyin ọdun mẹfa to ti lo lẹwọn.

Bakan naa ni Aarẹ kede orukọ awọn eeyan miran ti wọn n jiya idajọ lọwọ, pẹlu awon miran to tilẹ ti ku tipẹ bii Herbert Macaulay, Tinubu ni oun mu oju kuro ninu ẹṣẹ wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣugbọn ẹni ti ẹnu kun ju lori idariji ẹṣẹ naa ni Mariam Sanda, kaluku lo n sọ pe obinrin naa ko yẹ lẹni to yẹ ki ijọba dariji rara, nitori ọkọ to fẹ ẹ sile, to bimọ meji fun lo gun pa ni 2017.

Bakan naa ni awọn eeyan ti ẹsun wọn le pupọ bii apaayan, awọn to gbe oogun oloro, awọn to n ko ọmọ ọlọmọ ṣowo ẹrú, awọn awakusa lọna aitọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ti ẹnikẹni ko lero pe wọn le gba itusilẹ, ri aanu gba ninu ikede akọkọ ti Tinubu ṣe.

Eyi fa oniruuru awuyewuye lori ayelujara.

Lẹyin naa ni Aarẹ Bola Tinubu tun ṣe atunṣe si idajọ awọn eeyan to n jiya ofin to kede aforiji fun tẹlẹ.

Ohun to kọkọ gbode ni pe wọn ti yọ orukọ Maryam Sanda, obinrin to gun ọkọ rẹ pa ni 2017 kuro lara awọn ti yoo ri aanu naa gba.

Iroyin naa sọ pe atẹjade ti Bayo Onanuga, Olugbani-nimọran Tinubu lori eto iroyin fi sita, ti yọ orukọ Maryam ati awọn ọdanran ti ẹṣẹ wọn le gan-an kuro ninu awọn ti yoo ri idariji gba.

Eyi lo mu ọpọ eeyan maa ro pe idajọ iku ti kootu da fun obinrin naa ni 2020 yoo pada ṣẹ lori rẹ niyẹn

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọwọ alẹ, ti afikun orukọ tun jade wa lati ọfiisi Aarẹ, ọrọ naa yipada.

Iwe orukọ tuntun to jade ṣafihan orukọ Maryam Sanda gẹgẹ bii ọkan lara awọn ti ijọba din ijiya ẹṣẹ wọn ku, ki i ṣe pe wọn yoo pa a rẹ.

Ọwọ isalẹ pẹpẹ ni orukọ naa wa ninu atẹjade orukọ tuntun ti ijọba fi lede.

Lodi si bi ọpọ eeyan ṣe ti ro pe Maryam Sanda ti padanu anfaani naa nigba ti orukọ rẹ ko ti jade lakọkọ, ti wọn ro pe iku ni eyi tumọ si fun obinrin naa, ileeṣẹ Aarẹ ṣalaye pe ki i ṣe idajọ iku.

Ẹwọn odun mejila ni Aarẹ sọ ijiya Maryam da, dipo idajọ iku tabi ai ri idariji gba rara to kọkọ jade.