Wo àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́fà tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìdíje Afcon 2025

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika ikarundinlogoji rẹ yoo bẹrẹ ni Morocco lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2025 yii, ti wọn yoo si gba aṣekagba rẹ niluu Rabat lọjọ kejidinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2026.
Orilẹede Morocco to n gbalejo awọn akẹgbẹ rẹ ni Afrika gbagbọ pe asiko ti to fun awọn lati bori idije naa lati ọdun 1976.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn agbabọọlu ti irawọ wọn kan nilẹ Afrika ni yoo kopa ninu rẹ, BBC Sport ṣe akojọpọ awọn mẹfa ti yoo fakọyọ nibẹ.
Azzedine Ounahi (agbabọọlu aarin, Morocco)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni bayii ti Ashraf Hakimi to jẹ adari awọn agbabọọlu Morocco n koju awọn iṣoro kan, o da bii pe wọn yoo fi ireti wọn si ibomii.
Bo tilẹ jẹ agbọọlu aarin fun Real Madrid, Brahim Diaz jẹ goolu meje lasiko igbaradi fun idije yii, inu Azzedine Ounahi, to n gba bọọlu aarin fun Girona ni La Liga ni ireti ọpọ ọmọ orilẹede naa wa.
Ounahi to bẹrẹ si n gba bọọlu fun wọn lẹyin to kuro ni Mohammed VI Academy ti n Farahan bii agbabọọlu ti ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin.
Lati igba to ti darapọ mọ Girona ni La Liga lo ti n fakọyọ.
Morocco yoo koju Comoros, Mali ati Zambia ni iṣi wọn, bẹẹ ni wọn ni Yassine Bonou, to jẹ aṣọle to dantọ julọ ni Afrika, amọ se Ounahi le fakọyọ ti Asharaf Hakimi ko ba si lori papa?
Maxamed Amoura (atamatase, Algeria)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amoura lo sọ goolu sinu awọn julọ l'Afrika lasiko igbaradi fun idije ifẹ ẹyẹ agbaye.
Ninu igba mẹjọ to gba bọọlu fun orilẹede rẹ, agbabọọlu Wolfburg naa sọ boolu sinu awọn nigba mọkanla.
Awọn idan to danwo lori papa lo mu ki ẹgbẹ agbabọọlu Les Verts ni France ri gẹgẹ bii ẹn I ti wọ n fẹ.
Victor Osimhem (atamatase, Nigeria)

Oríṣun àwòrán, Reuters
O daabi pe ikọ agbabọọlu Najiria kii ṣe daadaa ni gbogbo igba ti agbabọọlu Galatasaray yii ko ba si lori papa.
Lasiko igbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye, Naijiria fara gbọgbẹ nigba mẹrin ti ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn naa ko si lori papa.
Naijiria, to ti gba ife ẹyẹ ilẹ Afrika nigba mẹta ọtọtọ yoo koju Tanzania, Uganda ati Tunisia.
Ibrahim Mbaye (agbabọọlu iwaju, Senegal)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbabọọlu yii ti gba bọọlu fun orilẹede France ri gẹgẹ bi ọdọ, o si ti n lewaju ninu agbabọọlu Paris St-Germain fun saa yii lasiko ti wọn bori Barcelona.
Oṣu to kọja ni Mbaye kọkọ gba bọọlu koju Brazil, o si di agbabọọlu ti ọjọ ori rẹ kere julọ lẹni ọdun mẹtadinlogun lasiko to jẹ goolu ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Kenya ninu eyii ti wọn ti di ẹru goolu mẹjọ si odo le Kenya lori.
Rogers Mato (agbabọọlu ọwọ iwaju, Uganda)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Uganda ti pada si idije ifẹ ẹyẹ ilẹ Afrika lati ọdun 2019.
Aṣọle ẹni ọdun mejilelogun naa jẹ goolu meji lasiko ti wọn koju Mozambique ninu oṣu Kẹsan an, o si n ṣe daadaa fun ikọ Vardar to n gba bọọlu fun ni North Macedonia.
Uganda yoo koju Naijiria ati Tunisia to jẹ orilẹede ti ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin ninu idije naa, to fi mọ Tanzania ti yoo gbalejo idijẹ ọhun lọdun 2027.
Reinildo (Mozambique)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun igba akọkọ, agbabọọlu Premier League wa ninu ikọ orilẹede Mozambique.
Ẹni naa ni Reinildo to n gba bọọlu fun Atletico Madrid lẹyin to kuro ni Sunderland ninu oṣu Keje ọdun yii.
Ireti awọn ololufẹ rẹ ni pe yoo fakọyọ ninu idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ naa.












