Àlàyé rèé lórí ohun tó rọ̀ mọ́ ikú igbákejì gómìnà ni Bayelsa, Lawrence Ewhrudjakpo, àti bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń ṣe ìdárò rẹ̀

Oloogbe Lawrence Ewhrudjakpo

Oríṣun àwòrán, @Lawrence Ewhrudjakpo

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Lawrence Ewhrudjakpo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹgbẹ awọn gomina ekun Guusu orilẹede yii titi to fi mọ ẹgbẹ PDP ati awọn oloṣelu to sunmọ Igbakeji gomina ipinlẹ Bayelsa, Lawrence Ewhrudjakpo to jade laye ni wọn ti bẹrẹ si i daro iku rẹ lati ana ti iroyin iku naa ti gbode.

Ọjọbọ, ọjọ kọkanla oṣu Kejila ọdun 2025 ni iroyin iku Igbakeji Ewhrudjakpo, gbode lojiji.

Lara awọn gomina to ti ranṣẹ ibanikẹdun lori iku naa ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun.

Awọn alabaṣiṣẹ rẹ sọ pe aarẹ kankan ko ṣe Oloogbe naa ṣaaju iku rẹ yii, ati pe o ṣiṣẹ wọ akoko ti titan de ba a naa ni.

Iroyin sọ pe ipade kan ti wọn ti tako ara wọn ni Oloogbe naa ti kuro to si n pada si ọfiisi rẹ, ko too di pe o ṣubu lulẹ.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Iroyin sọ pe niṣe ni Igbakeji gomina ipinlẹ Bayelsa yii ṣadeede ṣubu lulẹ ni ọfiisi rẹ to wa nile ijọba Bayelsa, ni nnkan bii aago kan aabọ ọsan ana.

Wọn sare gbe e lọ sile iwosan Federal Medical Centre, Yenagoa, nibi ti wọn ti gba a si ẹka itọju awọn eeyan to wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun (ICU).

Yara itọju naa ni awọn dokita ti pada fidi rẹ mulẹ pe Lawrence Ewhrudjakpo ti jade laye.

Ṣaaju ikede iku naa ni Akọwe iroyin fun Igbakeji gomina naa, Doubara Atasi, ti fidi ẹ mulẹ fun ẹka iroyin kan pe ipo ilera to lewu ni ọga oun wa.

O ni wọn ti gbe e lọ sile iwosan, ẹka itọju to lagbara si ni wọn fi i si.

Bo si tilẹ jẹ pe ijọba Bayelsa ko tete kede iku naa, o ti n lu jade nigba ti yoo fi di irọlẹ mọ ọwọ alẹ.

PDP kéde ikú Ewhrudjakpo

Nigba ti wọn n fidi iku Igbakeji gomina Bayelsa naa mulẹ ninu atẹjade ti Akọwe ikede apapọ PDP, Ini Ememobong, fi sita, ẹgbẹ naa ṣalaye pe iku Lawrence ti fi awọn sinu ọfọ nla .

Igun ti Kabiru Turaki( SAN) n ṣoju fun ṣapejuwe Oloogbe bii oloṣelu to ṣee fọkan tan, to si tun jẹ ọmọluabi gidi.

Bakan naa ni Gomina Dapo Abiodun fi atẹjade ibanikẹdun sita pẹlu, nibi to ti ni iku Ewhrudjakpo ba oun lojiji pupọ, to si ba Gomina Duoye Diri kẹdun iku alabaṣiṣẹ pọ rẹ naa.

Bakan naa ni awọn araalu ipinlẹ Bayelsa ti n fi ibanujẹ han lori iroyin naa lori ayelujara, ọpọ wọn lo n sọ pe yoo wu awọn ki iroyin naa ma jẹ otitọ

Ta a ni Oloogbe Lawrence Ewhrudjakpo?

Ọjọ karun-un oṣu Kẹsan-an ọdun 1965 ni wọn bi Lawrence Ewhrudjakpo ninu idile Awhowho Ewhrudjakpo ti wọn jẹ obi rẹ.

Ilu Ofoni, Sagbama, ni Ila-Oorun Bayelsa ni wọn ti bi i.

O lọ sileewe alakọọbẹrẹ Ebikimiye Primary School, Kpakiama ati ti girama Government College Bomadi, ni 1982, o si pari rẹ si Community Secondary School, Ofoni.

Oloogbe Lawrence gba iwe eri Diploma ninu ẹkọ ilera agbegbe ni Rivers State College of Health Science and Technology, Port Harcourt, o tun lọ si yunifasiti ipinlẹ Rivers, o si tun kẹkọọ imọ ofin.

Lawrence Ewhrudjakpo ni Igbakeji gomina ipinlẹ Bayelsa lati ọdun 2020 titi di asiko iku rẹ.

Ọdun 2019 ni wọn kọkọ yan an bii igbakeji Gomina Douye Diri, wọn si tun jọ pada ṣiṣẹ nigba ti wọn yege ibo ni 2013.