Tinubu gbé ìgbésẹ̀ báwọn aṣòfin ṣe fọ́nmú pé ojúṣàájú wà nídi kíkó àwọn ọlọ́páá kúro lẹ́yìn àwọn èèkànlú

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga
Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti ke si olubadamọran pataki rẹ lori eto abo lati lati jawe sobi idanilẹkọọ awọn ẹṣọ aṣọgbo Naijiria lọna ati dẹkun ijinigbe to ti di tọrọkọbọ ni Naijiria.
Aṣẹ yii lo jade lẹyin ti Aarẹ ti kọkọ kede idasilẹ awọn ẹṣọ aṣọgbo lati daabo bo awọn igbo Naijiria ti awọn agbesunmọmi n fara pamọ si.
Tinubu sọ pe "Ni gbogbo igba la n koju iṣoro igbesunmọmi ati ijinigbe, a nilo gbogbo awọn ẹsọ ti a le lo. A gbọdọ daabo bo awọn eeyan wa."
Ọọfisi Aarẹ ni igbesẹ naa ko ṣẹyin riro eto abo awọn ilu to wa ni igberiko ti awọn kọlọrọsi ẹda n ba si lagbara.
Ireti wa pe ọọfisi Ribadu yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ileeṣẹ agbofinro mii lati ri daju pe erongba Aarẹ fun eto abo to peye di ṣiṣẹ nipa idanilẹkọ naa.
Tinubu ni afojusun oun ni lati daabo bo araalu ki iṣẹlẹ ijinigbe ati gbesunmọmi si di ohun itan ni Naijiria.
Awọn ọlọpaa to n ṣọ awọn eeyan nla-nla gbọdọ kuro lẹyin wọn ni kankan – Tinubu
Tinubu sọ siwaju si pe ọrọ oun ko ni yẹ nipa awọn ọlọpaa to n ṣọ awọn eeyan nla-nla ni Naijiria ki awọn ọlọpaa naa le lọ ṣisẹ lawọn ibi ti awọn mẹkunu ti nilo wọn fun abo.
Nigba to n sọrọ lọjọru, Tinubu ni ko tọ ki awọn ọlọpaa maa ṣọ iwọnba eeyan perete ti wọn jẹ eeyan nla nigba ti ọpọ araalu wa ninu ewu eto abo to mẹhẹ.
Ọrọ yii ni Tinubu sọ ki wọn to bẹrẹ ipade ilu to waye ni ọọfisi Aarẹ niluu Abuja.
O ni "Mo ni igbagbọ ninu nnkan ti mo sọ, mo si ti pe ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa… ti ẹ ba ni isọro kankan latari awọn iṣẹ kan ti ẹ n ṣe, ẹ pe IGP lati gba aṣẹ lọwọ mi."
Aarẹ ni awọn eeyan nla kan le gba ọlọpaa fun abo amọ aṣẹ kọkọ gbọdọ jade lati ọọfisi Aarẹ.
Tinubu paṣe fun ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC) ki wọn jiroro lori bi wọn yoo ṣe fi awọn oṣiṣẹ NSCDC rọpọ awọn ọlọpaa ti wọn fẹ ko kuro lẹyin awọn eeyan nla naa.
Lẹyin naa lo paṣẹ fun olubadamọran lori eto abo, NSA, ati adari ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS lati ṣe ipade lori bi igbesẹ naa yoo ṣe ya kankan.
Ojuṣaju wa ninu bi wọn ṣe ko ọlọpaa kuro lẹyin wa - Abdul Ningi
Ẹwẹ, Sẹnetọ to n ṣoju aringbungbun ipinlẹ Bauchi ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti ke gbajare sita pe ojuṣaju wa ninu igbesẹ kiko ọlọpaa kuro lẹyin awọn alẹnulọrọ naa.
Ningi ni titi di asiko yii ni ọlọpaa ṣi n tẹle awọn ọmọ oloṣelu kan kiri, to fi mọ awọn oniṣowo nla-nla atawọn olorin kan.
O ni aṣẹ Aarẹ lati ko awọn ọlọpaa naa kuro lẹyin awọn eeyan nla dara amọ niṣẹ lo da bii pe awọn aṣofin nikan lo n jiya aṣẹ ọhun latari bi ọlọpaa ṣe n tẹle awọn eeyan mii kiri.
Ningi sọ pe gbogbo wọn lo yẹ ki ọrọ naa kan bẹrẹ lati ori Aarẹ, si igbakeji rẹ titi de ori adari ile igbimọ aṣofin.
O ni "Lati ọdun1999 ni mo ti n sin ilu, ọlọpaa kan pere lo si n tẹle mi kiri amọ iyalẹnu lo jẹ pe wọn ti gbe ọlọpaa naa kuro lẹyin mi lai kọkọ bun mi gbọ."
Ningi wa rọ ile igbimọ aṣofin naa ki wọn ṣe iwadii bi ọrọ naa ṣe ri ko ma jẹ pe ori awọn nikan ni ijọba yoo ti fọ agbọn ọrọ ọhun.















