Ipa wo ni ìgbésẹ̀ Tinubu láti kó ọmọ ogun lọ Benin yóò ní lórí ìgbógun ti agbébọn ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, Defence headquarters Nigeria/X
Ile aṣofin agba l'Abuja ti buwọlu ẹbẹ Aarẹ Bola Tinubu lati ko ọmogun Naijiria lọ si orilẹede Benin.
Erongba Aarẹ Tinubu ni lati ko ọmogun ranṣẹ si orilẹede naa lati le jẹ ki alaafia jọba nibẹ lẹyin tawọn ọmogun ọlọtẹ fẹ ditẹ gbajọba Aarẹ Patrice Talon lọjọ Aiku to kọja.
Aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, lo kede ibuwọlu ile si ẹbẹ Aarẹ Tinubu, lẹyin ti gbogbo ile fontẹ lu igbesẹ naa tan.
Bi Tinubu ṣe kan si ile aṣofin lori ọrọ naa ni i ṣe pẹlu alakalẹ ofin orilẹede Naijiria.
Aarẹ ni lati gba iyọnda ile igbimọ aṣofin agba laarin ọjọ mẹrinla lati ko ọmogun Naijiria lọ si orilẹede miran, gẹgẹ bi o ti wa ni akọsilẹ labala karun un apa karun un iwe ofin Naijiria.
Awọn ọmogun ofurufu Naijiria ti lọ sorilẹede Benin bayii lati lọ ṣeranwọ fun ijọba nibẹ lori igbiyanju rẹ lati jẹ ki alaafia jọba daadaa.
Ẹwẹ, wọn ti kede pe olori awọn ọmogun to fẹ ditẹ gbajọba naa, Tigril Pascal, gẹgẹ bi ọdaran ti ijọba n wa.
Ninu ọrọ rẹ, aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnẹtọ Akpabio sọ pe igbesẹ Aarẹ Tinubu lati ko omogun lọ si Benin yoo dena kawọn ọmọ Benin wa di ogunlende ni Naijiria.
Akpabio ni igbesẹ yii yoo tun daabo bo ibode orilẹede Naijiria lọwọ awọn ọmogun ọlọtẹ.
O wa gboṣuba fun Tinubu lori bi o ti tẹle iwe ofin Naijiria nipa bi o ti beere iyọnda lọwọ ile aṣofin lati ko ọmogun lọ si orilẹede Benin.
Oju wo ni ofin Naijiria fi wo igbesẹ Tinubu lati kọmogun lọ si Benin?
Agbẹjọro agba Monday Ubani (SAN) ṣalaye fun BBC Yoruba wi pe Aarẹ Tinubu tẹle ofin Naijiria nipa bo ṣe beere iyọnda ile aṣofin lati ko ọmogun ranṣẹ si orilẹede Benin.
Amofin agba Ubani sọ pe iṣẹlẹ pajawiri ni igbiyanju awọn ọmogun ọlọtẹ lati gbajọba ni Benin, eyi to nilo ki aarẹ gbe igbesẹ lori rẹ ni kiakia.
O ni ile aṣofin to n ṣoju araalu gbọdọ ṣe agbeyẹwo igbesẹ aarẹ lati mọ bo ya nnkan ti ko ni ṣe akoba fun orilẹede ni igbesẹ naa, eyi si ni ile ti ṣe ki wọn to buwọlu igbesẹ Aarẹ Tinubu.
''Ko si ẹni to reti wi pe awọn ọmogun ọlọtẹ yoo gbiyanju lati ditẹ gbajọba.
Ojiji lo ṣẹlẹ, ati pe orilẹede Benin lo wa lẹgbẹẹ Naijiria, eyi to tumọ si pe iru nnkan bayii le ṣẹlẹ ni Naijiria naa to ba n ṣẹlẹ ni Benin.
Naijiria gẹgẹ bi orilẹede aṣaaju ni Afirika ko le maa woran kawọn ologun maa ditẹ gbajọba layika rẹ, papaa julọ pẹlu nnkan to n ṣẹlẹ lawọn orilẹede iwọ oorun Afirika mii bii Mali, Burkina Faso ati Niger,'' Amofin Ubani lo sọ bẹẹ.
Agbẹjọro agba naa fikun ọrọ rẹ pe kii ṣe pe awọn ọmogun Naijiria to n lọ si Benin ko ni pada wale mọ.
O ni iṣẹ iranwọ ni wọn lọ ṣe nibẹ ki alaafia ati ijọba awarawa le fẹsẹ mulẹ si i ni wọn ba lọ.
Agbẹjọro Ubani sọ pe igbesẹ to ṣe pataki ni Aarẹ Tinubu gbe tori bawọn ọmogun ọlọtẹ ṣe fẹ ditẹ gbajọba ni Benin mu ewu dani fun orilẹede naa ati fun Naijiria.
''Ara wa la n daabo bo nipa kiko ọmogun lọ si Benin''
Ninu ọrọ tiẹ, onimọ nipa ọrọ eto aabo, Akin Adeyi, naa sọ pe igbesẹ to ṣe pataki ni Aarẹ Tinubu gbe nipa bi o ti ko ọmogun ranṣẹ lọ si Benin.
Ọgbẹni Adeyi to tun jẹ oṣiṣẹfẹyinti lẹnu iṣẹ ologun sọ pe ''ara wa la n daabo bo nipa kiko ọmogun lọ si Benin lati le ri pe alaafia jọba nibẹ.
''Ti Benin Republic ko ba ni alaafia, orilẹede Naijiria naa ko le ni alaafia.
Ninu orilẹede ti a jọ n ṣowo julọ ni Benin wa, tori naa, ohun to ba de ba oju ti de ba imu.
Ti Benin Republic ba daru, ṣe Naijiria le gbawọn ọmọ orilẹede naa to ba fẹ wa ṣatipo tan?
Nitori naa, kii ṣe wi pe a n ṣe Benin ni oore pẹlu bi Aarẹ Tinubu ṣe ko ọmogun lọ sibẹ, ara wa la n daabo bo,'' Ọgbẹni Adeyi ṣalaye.
Ọgbẹni Adeyi ni ogun abẹle to waye ni Libya ṣi n nipa lori awọn orilẹede Afirika yooku to fi mọ Naijria.
O ni lati Libya lọpọ awọn agbesunmọmi to n ṣọṣẹ ni Naijiria ti n ra nnkan ijagun.
Onimọ nipa ọrọ aabo naa sọ pe ti orilẹede kan ba n ṣeranwọ fun orilẹede to wa layika rẹ, ko tumọ si pe o n ṣe e loore bi ko ṣe pe o n daabo bo ara rẹ ni.
Lori wi pe ipa ti kun awọn ọmogun Naijiria ti aarẹ tun ko lọ si Benin, Ọgbẹni Adeyi ni bo ba ti gba naa ni Naijiria yoo maa ṣe e tori iṣẹlẹ pajawiri ni nnkan to ṣẹlẹ ni Benin Republic.















