Ìdílé ọba Fusengbuwa n'Ijebu Ode kéde pé àwọn kò mọ Wasiu Ayinde rí, kìí ṣe ọmọ ìdílé àwọn

Oríṣun àwòrán, Wasiu Ayinde/Instagram
Ìdílé Fusengbuwa ti ìlú Ijebu Ode ti kéde pé gbajúmọ̀ olórin Fuji nnì Wasiu Ayinde tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí K1 De Ultimate kìí ṣe ọmọ ìdílé àwọn àti pé kò lè díje du oyè Awujale ilẹ̀ Ijebu lábẹ́ ìdílé náà.
Ìkéde yìí ló ń wáyé níbi ìpàdé àwọn olórí ìdílé náà tí wọ́n ṣe ní Ile Nla lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kejìlá, ọdún 2025.
Agbẹnusọ ìdílé Fusengbuwa, Abiodun Ogidan nínú àtẹ̀jáde kan tó gbórí ayélujára lọ́jọ́bọ̀ sọ pé àwọn ti ṣe àgbéyẹ̀wò ìwé tí Wasiu Ayinde gbé kalẹ̀ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ ìdílé náà lòun.
Ó ní ìwé náà ṣàfihàn rẹ̀ pé K1 kìí ṣe ara àwọn ní ìdílé oyè Fusengbuwa.
Ogidan fi kun pé àwọn kò fún Wasiu Ayinde ní fọ́ọ̀mù láti du oyè Awujale, pé gbígba fọ́ọ̀mù náà ti parí ṣáájú kó tó kéde pé òun fẹ́ jẹ Awujale ilẹ̀ Ijebu àti pé ọmọ ìdílé Fusengbuwa lòun.
"Báwo ni èèyàn tí kò báwa ṣèpàdé ẹbí wa rí tàbí dá sí ọ̀rọ̀ ẹbí wa nígbà kankan rí ṣe máa ṣàdédé jí lọ́sàn-án kan òru kan láti máa sọ àwọn nǹkan tí kò ṣẹlẹ̀?
"Wasiu Ayinde fẹ́ gbìyànjú láti tún ìtàn kọ ni àmọ́ 2025 la wà yìí, kò le fi òwú bò wá lójú. Kìí ṣe ara wa, àwọn tí kìí bá sì ṣe ojúlówó ọmọ ìdílé wa kò lè dá sí nǹkan tí à ń ṣe."
Bákan náà ni ìdí igi míì nínú ìdílé Fusengbuwa ìyẹn ìdí igi Oduneye náà sọ pé àgbà olórin Fuji náà kìí ṣe ọmọ ìdílé Jadiara tó sọ pé òun ti wá.

Oríṣun àwòrán, Others
'A ò mọ nǹkankan nípa Setejoye tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, irọ́ ló ń pa kiri nítorí Wasiu Ayinde kìí ṣe ọmọ ìdílé Oduneye tàbí ẹbí Jadiara'
Nígbà tó ń gbẹnu ìdílé Jadiara sọ̀rọ̀, Alhaja Adesumbo Oduneye sọ pé ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn nígbà tí àwọn rí fọ́ọ̀mù tí K1 fi ṣọwọ́ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ ìdílé Fusengbuwa lòun, pé ọmọ bàbá òun, Adetayo Oduneye ló tọwọ́bọ ìwé náà.
Ó ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni àwọn mọ Adetayo Oduneye Eruobodo ṣùgbọ́n kìí ṣe olórí ẹbí ìdí igi ẹbí Oduneye.
"A ò mọ nǹkankan nípa Setejoye tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, irọ́ ló ń pa kiri nítorí Wasiu Ayinde kìí ṣe ọmọ ìdílé Oduneye tàbí ẹbí Jadiara.
"Gbogbo ohun tó bá wù kí Adetayo Oduneye máa sọ, ti ẹ̀ nìyẹn, gbogbo ẹbí ìdílé Oduneye nílé àti lẹ́yìn odi ló rán mi wá láti sọ fún gbogbo ayé pé Wasiu Ayinde kìí ṣe ara wa, kò sì wá láti ìdílé Jadiara."

Oríṣun àwòrán, WhatsApp
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Wasiu Ayinde gbé ìwé kan kalẹ̀ èyí tí Adetayo Oduneye, ẹni tí ó pe ara rẹ̀ ní olórí ẹ̀ka Setejoye ní ìdílé oyè Jadiara buwọ́lu pé òun jẹ́ ọmọ ìdílé náà.
Nínú ìwé náà ni Wasiu ti sọ pé ẹ̀ka Setejoye ti ìdílé Jadiar ani òun ti jáde àti pé ìdílé bàbá òun nibẹ̀.
Ó sọ pé, nínú fọ́ọ̀mù náà, pé òun ti ṣetán láti parí aáwọ̀ tó bá wà láàárín òun àtàwọn olórí ìdílé náà.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Wasiu Ayinde kéde pé lọ́sẹ̀ tó kọjá pé òun fẹ́ du oyè Awujale ilẹ̀ Ijebu lábẹ́ ìdílé Fusengbuwa, ìdílé tó kàn láti pèsè Awujale tuntun lẹ́yìn ìpapòdà Ọba Sikiru Adetona tó lọ ọdún márùndínláàádọ́rin lórí ipò náà.
Lẹ́yìn náà ni olórí ìdílé Fusengbuwa, Abdulateef Owoyemi sọ pé kí Wasiu Ayinde lọ tọwọ́bọ ìwé láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ojúlówó ọmọ ìdílé náà lòun.
Wasiu, tó jẹ́ olórí ọmọ ọba ilẹ̀ iJebu sọ pé èròńgbà òun láti du oyè náà wà ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àti òfin tó de jijẹ Awujale àti jíjẹ oyè ìpínlẹ̀ Ogun.















