Ariwo gbòde pé Wasiu Ayinde kì í ṣe ọmọ ìdílé Fusengbuwa tó pe ara rẹ̀, KWAM 1 gbé ẹ̀rí kalẹ̀

Oríṣun àwòrán, Wasiu Ayinde (K1)
Erongba gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde (K1) lati dije fun ipo ọba Awujalẹ ilẹ Ijẹbu ti n ba ọna miran yọ bayii.
Eyi n waye pẹlu bi awuyewuye ṣe gbode, pe olorin Fuji naa ko ba ẹbi Fusengbuwa ti ipo naa kan tan, ati pe irọ ni bo ṣe pe ara rẹ ni ọmọ idile naa.
Yatọ si ẹbi Fusengbuwa to ni ki Wasiu Ayinde waa sọ bo ṣe ba ẹbi naa tan, lati iran akọkọ de ikeje, nipa iwe kan ti yoo fidi eyi mulẹ, ẹbi Bubiadé to jẹ ọkan lara awọn idile ọmọ oye, ti ni Wasiu ko ba Fusengbuwa tan rara.
Ẹ o ranti pe lọjọ kẹta, oṣu Kejila ọdun 2025 ni K1 kọ lẹta si idile Fusengbuwa ti yoo fa Awujalẹ tuntun kalẹ, pẹlu alaye pe ọmọ idile naa ni oun, lati iran Jadiara.
Wasiu ni oun ṣetan lati jẹ Awujalẹ tuntun gẹgẹ bii ojulowo ọmọ ile naa, ni ibamu pẹlu ofin oye jijẹ ibilẹ ati ti ijọba ipinlẹ Ogun.
O fiwe erongba rẹ naa ranṣẹ, Alaga ile ọmọ oye Fusengbuwa, Abdulateef Owoyemi, si tẹwọ gba a pẹlu afikun ọjọ fun olorin Fuji naa lati to gbogbo iwe to yẹ ṣaaju Ọjọru ọsẹ yii.
Owoyemi ni bi Wasiu ba ti ri iwe to fidi rẹ mulẹ bii ọmọ ọkọ ile Fusengbuwa gbe kalẹ, igbesẹ to ku yoo bẹrẹ pẹlu awọn oludije.
O ni afojusun awọn ni lati ni Awujale tuntun laaarin ọsẹ keji si ikẹta ninu oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.
Wasiu Ayinde kò bá ẹbí Fusengbuwa tan- Omoba Salami Agoro-Odunsi
Ninu lẹta kan to gba ori ayelujara kan lori ọrọ yii, eyi ti
Orukọ Omoba Salami Agoro-Odunsi wa nibẹ bii ẹni to kọ ọ ni wọn ti ni Wasiu Ayinde ki i ṣe ọmọ ile Fusengbuwa.
Lẹta naa ka pe Agarawu, nipinlẹ Eko, ni wọn bi Wasiu si lọjọ keta,oṣu Kẹta odun 1957.
Ati pe Alhaji Ayinde Anifowoshe to jẹ oniṣowo ni baba rẹ.
Atẹjade naa tẹsiwaju pe Baba Wasiu wa lati Ijebu-Ode ṣugbọn ki i ṣe ọmọ ọba. O ni iya re wa lati Ilupeju -Ekiti.
"Ko si akọsilẹ ẹbi kan tabi itan atẹnudẹnu kan to so baba rẹ pọ mọ igun Jadiara tabi igun Fusengbuwa kankan.
"Oye Ọ̀túnba Afìdípọ̀tẹ̀mọ́lẹ̀ ti Ìjẹ̀bú-Òde lo fi I han bi ara awọn igun ọmọ oye Afidipọtẹmọlẹ to jẹ ikẹta ninu awọn idile to n fi ọba jẹ.
"Kika ara rẹ mọ ọkan lara idile Jádíàrà lasiko yii ko ṣee fi ẹsẹ rẹ mulẹ, ko si ṣee tẹwọ gba labẹ ofin."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka.
Ni itẹsiwaju alaye naa ni wọn ti yanna-na idile mẹrin to n fa ọmọ oye kalẹ fun ipo Awujalẹ, awọn naa ni :
Anikinaiya, Fusengbuwa (ti ipo naa kan bayii), Fidipote ati Gbélégbùwà.
Atẹjade ti wọn dari rẹ si awọn ẹka tọrọ naa kan ati Gomina Dapo Abiodun, rọ wọn lati ma ṣe yi ilana ipo ọba to wa nilẹ pada.
Wọn kilọ pe ki wọn ma fi aaye silẹ fun ajeji lati gba ipo ọba Awujalẹ, nitori o lewu.
Lẹta ti Awujale Kayode Adetola kọ si Wasiu Ayinde ṣafihan rẹ bii ọmọ idile Afidipọtẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Bi ọrọ yii ṣe n lọ lọwọ naa ni lẹta kan to n fidi ẹ mulẹ, pe ọmọ Afidipọtẹ ni Wasiu Ayinde, eyi ti Awujale to waja, Ọba Sikiru Adetona kọ, jade sori ayelujara.
Lẹta naa bẹrẹ pẹlu alaye pe Wasiu Ayinde fifẹ han lati jẹ oye Olori Ọmọ Ọba Akilẹ Ijebu, ati pe Idile Fidipọtẹ lo ti wa.
Kabiyesi Adetona lo buwọ lu iwe naa ti won kọ lọjọ karun-un, oṣu Keje ọdun 2023.
Ninu rẹ ni ọba to gbesẹ naa ti ki Wasiu Ayinde kuu oriire, to si ni aaye wa fun un lati gba ipo naa to ṣofo lasiko ọhun, to si tun jẹ pe ile Fidipọtẹ lo kan lati fa eeyan kalẹ fun.
Eyi ati bi Wasiu funra rẹ ṣe ti fi kọrin lọpọ igba, pe ọmọ Afidipọtẹmọlẹ n'Ijebu- Ode loun, ni awọn to n tako pipe ara rẹ ni ọmọ Fusengbuwa bayii n lo lati fi tako o.
Wọn n sọ pe ko mu ẹri wa to ba jẹ pe ọmọ ile oye ti ipo Awujale kan bayii ni.
Ṣaa, ọrọ naa ṣi n tẹsiwaju, a o si maa mu un wa fun yin wa bo ba ṣe n lọ.
Wasiu Ayinde kéde èróngbà rẹ̀ láti jẹ Awujalẹ Ijebu

Oríṣun àwòrán, Alaaji Wasiu Ayinde (K1)/Facebook
Gbajumọ olorin Fuji, Alaaji Wasiu Ayinde Omogbolahan (K1), ti kede erongba rẹ lati du ipo ọba Awujalẹ ilẹ Ijebu.
Ninu lẹta kan ti Wasiu Ayinde fi ranṣẹ si Alaga ile ọmọ oye Fusengbuwa, n'Ijebu-Ode, lo ti kede erongba rẹ lati jẹ Awujalẹ Ijebu.
Ninu lẹta to kọ lọjọ kẹta, oṣu Kejila ọdun 2025 naa ni Wasiu to tun jẹ Mayegun ilẹ Yoruba, ti ni ojulowo ọmọ ile oye naa ni oun.
"Emi, Otunba Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe, MON, fi asiko yii kede fun ile ọmọ oye Fusengbuwa, erongba mi lati jẹ ki wọn wo mi ṣe fun itẹ Awujale ilẹ Ijebu to ṣófo, ni ibamu pẹlu ofin ilẹ Ijebu ati ti oye jijẹ ipinlẹ Ogun."
Bẹẹ ni apa kan lẹta Wasiu Ayinde naa ka.
Olorin Fuji naa fidi ẹ mulẹ, pe idile Oba Jadiara, ni orirun oun.
O ni eyi fun oun ni anfaani lati jẹ Awujalẹ tuntun labẹ ilana oye jijẹ ipinlẹ Ogun.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ti le lọdun marun-un toun ti n fi ara oun jin fun igbelarugẹ ilẹ Ijebu, iran Yoruba ati aṣa Naijiria lapapọ, nipasẹ orin ati awọn ìṣe ibilẹ miran.
'Mo ti jẹ Mayegun ilẹ Yoruba, Olori Omo -Oba, Otunba Afidipotemole tí Akile Ijebu, gba oye MON'

Oríṣun àwòrán, @Wasiu Ayinde
Nigba to n tẹsiwaju nipa idi rẹ ti oun naa le fi jẹ Awujalẹ, Wasiu Ayinde sọ ninu lẹta rẹ naa pe:
"Ninu irinajo iṣẹ́ mi, mo ti gba ọpọ oye idalọla bii Mayegun ilẹ Yoruba (2020), oye ijọba ti i ṣe Order of the Niger – MON (2022), ati Olori Omo-Oba, pẹlu Otunba Afidipotemole Akile Ijebu (2023), eyi ti Awujale to waja fi mi jẹ."
"A bi mi ni ọjọ kẹta, oṣu Kẹta ọdun 1957, ojulowo ọmọ ile oye Fusengbuwa, Agunsebi Quarters si ni mi, lati igun idile Oba Jadiara, eyi to mu mi kunju oṣuwọn lati fa ara mi kalẹ pẹlu ofin ilẹ."
Ilé tẹ́wọ́ gba lẹ́tà Wasiu Ayinde

Oríṣun àwòrán, Others
Alaga ile ọmọ oye ti Wasiu fiwe ranṣẹ si, Abdul Lateef Adebayo Owoyemi, fidi rẹ mulẹ pe ile ti gba lẹta naa.
Bakan naa lo fun olorin naa ni aaye di ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila ọdun 2025 lati lati to gbogbo iwe to yẹ .
Ninu atẹjade to fi sita lanaa ọjọ Ẹti, Owoyemi, sọ pe: "Mo rọ gbogbo awọn ọmọ ẹbi wa nile ati lẹyin odi, lati ṣe suuru ki wọn si ni fọkanbalẹ.
"Laaarin wakati meji ti mo ti gba lẹta ti wọn kọ si mi ati awọn eeyan mẹfa mi-in lati ọdọ Olori Omo Oba Akile Ijebu, mo ti fesi pada bo ṣe yẹ, gẹgẹ bi mo ṣe ṣe fun awon yoku naa ti wọn ti fi erongba wọn han ṣaaju.''
Ikede ti Wasiu ṣe yii n waye lẹyin oṣu karun-un ti Awujale tẹlẹ, Oba Sikiru Kayode Adetona, waja.
Latigba ti lẹta erongba rẹ naa si ti de ori ayelujara ni ọpọ eeyan ti n fi iha ti wọn kọ si han, bawọn kan ṣe n sọ pe igbesẹ to daa ni Wasiu fẹ gbe, bẹẹ ni awọn kan n sọ pe ala ti ko le wa si imuṣẹ ni.














