Agboolé Akọni: Sodeke, jagunjagun tó kó àwọn aráàlú Egba àti adé wọ ilú Abeokuta
Jagunjagun to gbona ni Sodeke, bi o si se tẹ ilẹ Ẹgba do, naa lo gba ẹsin Kirisitẹni laaye nigba ti wọn de
Lori Agboole Akoni ti ọtẹ yii, BBC Yoruba gbera lọ siluu Abeokuta, to jẹ olu ilu ipinlẹ Ogun lati lọ mọ nipa jagunjagun, to ko awọn ọmọ Egba wọ ilu Abeokuta, to si jẹ pe a le pe ni ẹni akọkọ to kọkọ tẹwọgba ẹsin Kristẹni niluu Abeokuta.
Alake ti Ilu Egbe Oba Michael Adedotun Aremu Gbadebo ṣalaye pataki Sodeke ninu itan Egba ati ọna ti wọn n gba lati yẹ si i
BBC Yoruba bawọn arọmọdọmọ Sodeke meji, Adesina Adisa Sodeke ati Moruf Oloyede Sodeke sọrọ nipa bi ẹsin Krisitẹni se di itẹwọgba nilẹ Ẹgba.
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Moruf Oloyede Sodeke ni baba nla oun naa lo ko awọn Ẹgba wa silu Abeokuta lati wa tẹdo si.
"Ifa ni wọn fi rin lati inu Igbo Ẹgba ti wọn ti n bọ, ti wọn si n beere lọwọ Ifa pe se awọn ti de ibi ti awọn maa tẹdo si.
Wọn rin rin rin de ibi ti wọn fi de oke kan gagara, tii se oke Olumọ ti Ifa ni ki wọn tẹdo si.
Jagunjagun to gbona ni Sodeke, bi o si se tẹ ilẹ Ẹgba do, naa lo gba ẹsin Kirisitẹni laaye nigba ti wọn de."





