Gbogbo nǹkan tí mo ní láyé ni mo ná sórí àrùn túmọ̀ inú ọpọlọ, Bisola Badmus sọ̀rọ̀ lórí àìsàn tó fẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Bisola Badmus/Instagram
Aja to rele ẹkun to bọ, ka ki aja naa ku ewu, bayii lọrọ ri pẹlu gbamọ oṣere tiata Yoruba, Bisola Badnus, to ṣiṣẹ abẹ tumọ inu ọpọlọ to si ti gbadun bayii.
Ni mẹsan mẹwaa ni Badmus n dupẹ lọwọ Eledua fun oore ọfẹ to ri gba lati ṣe ọjọ ibi rẹ mii lẹyin ilakọja rẹ lori arun tumo inu ọpọlọ.
Bisola sọ loju opo Instagram rẹ pe oun jẹ Ọlọrun ni gbese ọpẹ fun aanu, oore ọfẹ, Ibukun ati alaafia to fi da oun lọla.
''Ọwọ rẹ ni mo ri, ọwọ rẹ ni mo ri, igba ti aye dan mi wo, ọwọ rẹ ni mo ri.
Ko si nnkan ti mo le sọ ju ẹ ṣeun lọ, Agbanilagbatan,'' Bisola lo fi orin bọnu bẹẹ.
O ni nigba ti iṣoro de, Ọlọrun jẹwọ ara rẹ tori Esu gbogun ni gbogbo ọna.
'Amọ, Ọlọrun sọ pe rara, ma ṣe fọwọ kan ẹni ami ororo mi, ma ṣe wolii mi nibi- Oluwa ṣeun, Olọrun mo dupẹ o.''
Bisola ni irinajo naa bẹrẹ lọdun 2022 nigba ti aisan bẹrẹ sii ṣe oun, ti oun ko si ro pe nnkan to lagbara ni rara.
Gbajumọ oṣere naa sọ pe iyalẹnu lo jẹ foun pe nigba tawọn dokita ni oun ti larun tumọ inu ọpọlọ.
O ni gbogbo nnkan toun ti ṣiṣẹ fun laye loun na lori aisan naa.
''Diẹ loku ki ẹmi mi ba aisan naa lọ, ṣugbọn ọpẹ ni fun Eledua to dami si.
Mi o gbadura iru nnkan ti mo ti la kọja fun ẹnikẹni, koda, mi o gbadura iru rẹ fun ọta mi gan an.
Amọ, mo dupẹ, aye ọpẹ yọ, ara mi ti ya bayii, idi niyii ti mo fi wa nibi lonii lati fi ọpẹ fun Ọlọrun tori ara mi ti ya bayii.
Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun wi pe ko jami kulẹ,'' Bisola ṣalaye.
Gbogbo ẹyin ti ẹ duro ti mi, ẹ ṣe mo dupẹ o - Bisola
Bisola ko ṣai dupẹ lọwọ gbogbo eeyan to duro ti i lasiko to fi ṣe aisan naa.
Gbajumọ oṣere naa ni ''ahh ẹ ṣe mo dupẹ ooo, mi o le dupẹ tan lọwọ yin.
Mi o le maa darukọ gbogbo eeyan ni ọkọọkan, ṣugbọn Ọlọrun mọ gbogbo yin o si ri gbogbo yin.
Mi o ni fi iru e san fun yin ooo.''
Badmus tun dupẹ lọwọ awọn ẹbi, ọrẹ atawọn akẹgbẹ rẹ, ''ẹ ṣe mo dupe.''
''Mo tun dupẹ lọwọ ọmọkunrin mi, Abdul Malik Olasunkanmi Ayinde Marshal fun bi o ti duro ti mi lasiko ti ogun le.
Ọmọkunrin mi ọwọn, mo gbadura pe Ọlọrun yoo da ọ si ninu alaafia pipe.
Mo dupe fun ipa ribi ribi ti o ko lori ọrọ mi.
Iku ojiji ko ni ja ọ gba mọ mi lọwọ, Abdul Malik, o ṣe ọkọ mi.
Si gbogbo eeyan to ṣeranwọ owo fun mi, abudi lagbara Olohun oba, ẹ se mo dupe,'' Bisola lo sọ bẹẹ.
Badmus tun dupẹ lẹẹkan si lọwọ Eledua fun anfaani lati ri ọjọ ibi rẹ mii.
O ni titi lai loun yoo maa dupẹ lọwọ Eledua ti ko jẹ koun di oku
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post















