Ọba Famodun kì í ṣe ọba ìlú Igbajo, agbára ní Oyetola lò lé wa lórí -Àwọn afọbajẹ

Oríṣun àwòrán, BB
Awọn afọbajẹ iluu Igbajọ ni fi ẹsun kan Gomina ana nipinlẹ Osun lori iyansipo Oba Famodun gẹgẹ bii Owa ilu Igbajọ
Awọn afọbajẹ ni pe ọwọ agbara gomina ana naa lo le awọn lori ti wọn fi gbe Famodun si ori aga ọba.
Lọsẹ to kọja ni iroyin iku, Ọwa ti iluu Igbajọ Ọba Adegboyega Famodun, ẹni to ti fi igba kan jẹ alaga ẹgbẹ oselu APC, jade sita.
Oloye Olalekan Ogunmoyede, ẹni to jẹ olori awọn afọbajẹ iluu Igbajọ ba BBC news Yoruba sọrọ lori awọ to da rogbodiyan silẹ niluu naa.
Oloye Olalekan, ni awọn ti awọn jẹ afọbajẹ kọ lo fi Adegboyega Famodun jẹ ọba, to si jẹ pe ijọba gomina ana Adegboyega Oyetola lo lo ipo agbara lati yan ọba, ti ko si jẹ ohun to yẹ ko jẹ ati oro to yẹ ko ṣe lati fi di ọba, ki wọn to gbe ọpa asẹ le lọwọ.
"Ni iluu Igbajọ ọmọ Ọwa lo ma jẹ ọba, ti awọn ọmọ olufẹ si ma n jẹ oodo, ti awa ọmọ ẹjẹmu lo ma n fi ọba jẹ. Ti wọn si mọ n fi ọba bọ lẹnu ki ọba to kọja lọ si ọdọ awọn ilare Mẹfa.
"Awọn ilare Mẹfa ni wọn gbe papọ pẹlu ọba laafin nitori ẹjẹmu ko le lọ si aafin tori o ni iransẹ ti ẹjẹmu mọ ran lọ si aafin ti n ṣe ọbanla.
"Bii ẹjẹmu ṣe ni aafin ni oodo naa ṣe ni aafin ti ọwa naa si ni aafin ti wọn. Sugbọn ẹjẹmu lo mọ n fi ọba jẹ niluu Igbajọ ki ọba ko to pegede.
"Bii wọn ba mu ẹnikan wa, to wa lo agbara asilo lori gbogbo wa bi o ṣe mọn ri nu. O ku osu mẹta ni awọn idile ti ọba kan yoo ti mu ọmọ oye wa ti awọn afọbajẹ yoo si ti mọ ṣe oro ati etutu to ba yẹ ki awọn ṣe fun ọmọ oye bẹ ko to di ọba. Sugbọn Adegboyega Famodun ko ṣe gbogbo eeyi rara ṣe ni wọn lo ipo agbara to ni.
"Nigba ti o ku aarọ ọjọ ti wọn o fi Adegboyega Famodun jẹ ọba, ni wọn ni ki awọn afọbajẹ ma bọ lati wa ṣe oro ọba fun Famodun ti ko yẹ ko ri bẹẹ rara.
Nitori o yẹ ki ẹni to ba fẹ jẹ ọba iluu Igbajọ ko wọ ipẹbi sugbọn Famodun lo idọbalẹ dipo ko wọ ipẹbi. Ile ọlọkọ Ibadan kan ni Adegboyega Famodun ti ṣe ipẹbi. Ko da ko tun wọ igboro gẹgẹ bi ọba rara."
Oloye Olalekan wa bẹ awọn idile Famodun ki wọn mọ ṣe gbe oku rẹ wọ igbodu nitori ẹni ti ko ba ti jẹ ọba ni wọn ko lẹtọ lati sin oku rẹ si igbodu rara.
Wọn ko jẹ ka gbọ ki wọn to fi Adegboyega Famodun jẹ ọba. Idile afọbajẹ keji.
Osuolale John, ẹni to jẹ olori afọbajẹ idile keji naa ba BBC news Yoruba sọrọ lori awuyewuye to waye niluu igbajọ.
Alagba John, sọ wi pe awọn ti awọn jẹ idile afọbajẹ keji ko mọ ki wọn to fi Adegboyega Famodun jẹ ọba.
"Ilu ni mọ gbọ ni aarọ ọjọ ti wọn n fi Famodun jẹ ọba ti mo si beere wi pe kin ni wọn n ṣe, ti wọn si sọ fun mi pe Adegboyega Famodun ni wọn n fi jẹ ọba. Ọrọ naa ya mi lẹun gidigidi nitori wọn ko tẹle ọna ti wọn gba niluu igbajọ ki wọn to jẹ ọba.
Ọmọba ni Adegboyega Famodun lootọ sugbọn wọn ko gba ọna to yẹ ki wọn gba ko to di wi pe wọn gbe ọpa asẹ le lọwọ.
Alagba John, fikun pe awọn afọbajẹ ati araalu lo jẹ ki ijọba gomina Adeleke ko mọ wi pe Famodun ko tọ ọna to yẹ ko tọ ko to di ọba.
Awọn idile Famodun naa ba BBC news Yoruba sọrọ.
Ọmọba Adegbitẹ Adefikanra, ni idile ti oye kan lo mu ọmọba Adegboyega Famodun silẹ gẹgẹ bi Ọba. o ni awọn ṣe ohun to yẹ ki awọn ṣe ni asiko ifinijoye naa.
O ni olori idile awọn Famodun lo fa Adegboyega Famodun le awọn afọbajẹ lọwọ gẹgẹ bi ọmọ oye ti yoo jẹ ọba Ọwa ti iluu igbajọ ti wọn si bu ọwọ lu gẹgẹ bi ẹni ti ọba tọ si.
O tẹsiwaju pe lẹyin naa ni won gbe lọ si ọdọ gomina igba naa Adegboye Oyetola.
"Nigba ti gomina Adeleke bẹrẹ iṣejọba ipinlẹ Osun, ni awọn idile kan dide wi pe awọn ni ọba iluu igbajọ tọ si. Sugbọn gomina Adeleke ki ọrọ oselu bọ, ko ṣe iwadi kikun lori ọrọ naa, lo ṣe yọ Adegboyega nipo ọba to si fi ẹlomiran si bẹ.
"Eleyi lo mu ki awọn idile Famodun gba ile ẹjọ giga to wa ni iluu ile ifẹ lọ. Lẹyin ọrẹyin ni ile ẹjọ da Adegboyega Famodun pada si ori itẹ awọn baba nla rẹ.
Ọmọba Adegbitẹ wa rọ awọn afọbajẹ ki wọn jeburẹ ki wọn si gba awọn laaye lati sin oku Adegboyega Famodun sibi ti wọn mọ n sin awọn ọba to ba ti waja ni iluu igbajọ si.
Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori rogbodiyan to bẹ silẹ niluu Igbajo?
Kọmisana fun awọn ọlọpaa ipinlẹ ọsun Ibrahim Gotan naa ṣe abẹwo si iluu igbajọ.
Ninu abẹwo rẹ lo ti ba awọn afọbajẹ iluu igbajọ ṣe ipade to si bere fun atunṣe ati alaafia ni kiakia.
Gbogbo ile ati ile itaja lo wa ni titi pa ni iluu igbajọ ti awọn agbofinro si duro wamuwamu kaakiri iluu naa.















