Àwọn ajínigbé fún ìlú ní ọ̀sẹ̀ kan láti san 300m owó ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n jí gbé, tàbí kí wọ́n padà wá láti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ aráàlú

Aworan awọn ajinigbe ti wọn n fi nnkan boju

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ajinigbe kan ti wọn ya wọ ilu Isapa ni ijọba ibilẹ Ekiti ni Ipinlẹ Kwara ti kan si ilu naa, ti wọn si n bere fun owo Ń300 million gẹgẹ bi owo itusilẹ fun awọn ti wọn wa lakata wọn.

Ko tan si bẹ o, ṣe ni wọn tun fun ilu naa ni gbendeke ọsẹ kan lati san owo yii tabi ki wọn pa gbogbo awọn ti wọn ji gbe.

Lẹyin eyi ni wọn tun leri leka lati ya bo ilu naa lẹẹkan si lati pa ọpọlọpọ araalu, ti wọn kọ lati san owo naa laarin igba ti wọn fun wọn.

Olórí Ọdẹ ìlú Ìsapá ṣàlàyé ohun tí àwọn ajínigbé náà sọ

Olori-Ọdẹ ilu Isapa, arakunrin Adeyeye lo sọ eyi di mímọ loni ọjọ Ọjọru nigba ti BBC News Yoruba kan sii lori iṣẹlẹ ijinigbe ọhun.

Arakunrin Adeyeye sọ pe "wọn ti kọkọ pe, ti wọn bere fun N500m, sugbọn iduna-dura n lọwọ lori rẹ.

"Sugbọn ni ọjọ Aiku, wọn pe pada, wi pe ki a san N300 million.

"Ilu bẹbẹ lati san N5 million amọ wọn yari kanlẹ, wọn ni irufẹ owo bẹ kii se tawọn.

"Wọn ni awọn fun ilu ni ọsẹ kan lati san owo naa tabi ki awọn pa awọn ti wọn ji gbe.

"Wọn ni awọn yoo tun ya wọ ilu lati pa ọpọlọpọ eniyan ti a o ba san owo naa ni aarin igba ti wọn fun wa.

"A o mọ boya irọ ni tabi ootọ, awọn ajinigbe naa sọ pe awọn lo lọ sọsẹ ni ilu Ejiba ni Ipinlẹ Kogi.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aiku ni awọn ajinigbe ya wọ sọọsi C&S kan ni Ejiba ni Ipinlẹ Kogi, ti wọn si gbe pasitọ ati iyawo rẹ, ati awọn mii lọ.

Gbogbo akitiyan lati kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa lo jasi pabo

Ohun tó ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀

Saaju ni ọjọ kẹẹdọgbọn osu to kọjá ni BBC News Yoruba gbe pe awọn ajinigbe naa ya wọ ilu Isapa lẹba Eruku, ti wọn si ji awọn eeyan gbe lọ.

Iroyin naa gbe pe ọdẹ ibilẹ kan lo kọkọ koju wọn, wọn si yinbọn lu u, amọ ko wọle si i lara.