Iye ìgbà tí Sowore ti dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tó gbéná wojú ìjọba Naijiria

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti sọ pe oun yoo wọgile beeli to fun Omoyele Sowore to ba tun pada sọ ọrọ ti wọn gbagbọ pe o le da omi alaafia Naijiria ru.
Adajọ Mohammed Umar lo sọ ọrọ naa lẹyin ti DSS pe e lẹjọ llori ọrọ to ṣo nipa Aarẹ Bola Tinubu lori ayelujara.
Umar sọ pe niwọn igba ti Sowore jẹ oludie sipo Aarẹ nigba kan ri, ti ile ẹjọ naa si ti fun ni beeli to tun gba iwe irinna rẹ lọwọ rẹ, ile ẹjọ ọhun lẹtọọ lati fun ni beeli.
Sowore lọ ile ẹjọ lasiko yii lẹyin ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS fẹsun kan an pe o tabuku Aarẹ Bola Tinubu lasiko to pe Aarẹ ni "ọdaran" loju opo X ti Facebok rẹ.
Ẹsun marun un ọtọtọ ni DSS fi kan Sowore to dije du ipo Aarẹ Naijiria lọdun 2019 ati ọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC.
DSS tun pe ileeṣẹ Meta to ni Facebook toun ti ileeṣẹ X lẹjọ lori bi wọn ṣe kọ lati yọ ọrọ naa ti wọn ni o ba orukọ Aarẹ jẹ lori ayelujara kuro loju opo wọn.
Iye igba ti Sowore ti dero atimọle lori ọrọ to sọ si ijọba Naijiria
Ọpọ igba ni Omoyele Soworo maa n ko si gbaga ijọba latari bo ṣe jẹ ajafẹtọọmọniyan to si maa n gbena woju ijọba Naiiria.
Fun idi eyii, o le ṣoro diẹ lati ṣe akojọpọ iye ni pato ti ọkunrin naa ti sọ oko ọrọ si ijọba to si dero atimọle nitori rẹ nitori ọkẹ aimoye igba lo ti ṣe bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Ọdun 1992 ni UNILAG
Lọdun 1992 ni Sowore kọkọ ko awọn ọmọ ile ẹkọ UNILAG ti iye wọn to ẹgbẹrun marun sọdi ti wọn si ṣe ifẹhonuhan lodi si ijọba ologun asiko naa.
Nibi iwọde ọhun ni ọlọpaa ti yinbọn pa eyan mẹjọ. Wọn fi ṣikun ofin gbe Sowore lọdun naa lọhun fun ipa to ko ninu iwọde naa, wọn si fi iya jẹ ninu atimọle.
Inu oṣu Kẹjọ, ọdun 2019
Lọdun 2019, ajọ DSS fi sikun ofin gbe Sowore lẹyin to ṣagbatẹro iwọde #RevolutionNow, ninu eyii to ti fẹsun ajẹbanu ati fifi iya jẹ araalu kan ijọba Aarẹ ana, Muhammadu Buhari.
Oṣu Kinni ọdun 2021
Ninu oṣu Kinni ọdun 2021, oloṣelunaa tun ko si gbaga ijọba Naijiria lori iwọde kan to ṣagbatẹru rẹ.
Ti ẹ ko ba gbabe, iwọde naa lo n waye lẹyin iwọde EndSARS inu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 to mi gbogbo Naijiria titi.
Ọrọ oju op X ati Facebook Sowore lọdun 2025
Lọdun 2025 ti a wa yii, Sowore kọ awọn ọrọ kan loju opo Facebook ati X rẹ ninu eyii to ti pe Aarẹ Bola Tinubu ni "ọdaran."
Lẹyin ọrọ naa ni ijọba Naijiria sọ fun ko yọ ọrọ naa latari pe o tabuku Aarẹ, ati pe o le da rugudu silẹ laarin ilu amọ Sowore kọ jalẹ.
DSS tun kan si Sowore ko yọ ọrọ naa amọ o ko jọ.
Ko pẹ lẹyin rẹ ti ijọba Naijiria kan ileeṣẹ X pe ki wọn yọ ọrọ ọhun ṣugbọn X ni oun ko ni yọ ọrọ naa nitori ko tapa si ofin awọn.
Ka ma fa ọrọ gun, ọrọ yii lo gbe Sowore lẹ ile ẹjọ lọtẹ yii.
Yatọ si awọn ti a mẹnuba loke yii, gbogbo igba ni Sowore maa n gbena woju ẹkun ijọba ti kii si foya ti wọn ba fẹ fi ofin gbe.
O ni afojusun oun ni lati gba agbara lọwọ awọn to n da Naijiria ru fun awọn araalu funra wọn fun anfani gbogbo mutumuwa.















