Ìjọba kéde fífi òfin de lílo ojú òpó ayélujára fáwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún mẹ́rìndínlógún, ìdí rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Láti ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kejìlá, àwọn iléeṣẹ́ ojú òpó ayélujára ni orílẹ̀ èdè Australia yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà lábẹ́ orí ọdún mẹ́rìndínlógún kò ní ní àǹfàní láti ṣí ìkànnì láwọn ojú òpó náà mọ́.
Bákan náà ni wọ́n máa gbégi wọ́gilé àwọn ojú òpó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ti ṣí tẹ́lẹ̀ ṣáájú àkókó yìí.
Ìjọba Australia ní ìgbésẹ̀ fífi òfin de àwọn ojú òpó yìí, èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn obí faramọ́, jẹ́ ojúnà láti mú àdínkù bá ìpèníjà táwọn ọmọdé ń kojú lójú òpó ayélujára
Wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ohun tí àwọn ọmọdé ń rí lórí ayélujára ló le ṣàkóbá fún ìlera àti ìgbáyégbádùn wọn.
Ìwádìí kan tí iléeṣẹ́ ìjọba kan ní orílẹ̀ èdè náà ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ṣàfihàn rẹ̀ pé ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ùn (96%) àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún ni wọ́n ti ń lo social media tí wọ́n sì ń ṣe alábàápàdé àwọn nǹkan tí kò dára tó lójú òpó náà.
Lára àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe alábàápàdé lórí ayélujára ni ìwà ìfìyàjẹni, àwọn ìlànà jíjẹun tí kò dára àti ìwà pípa ara ẹni.
Greg Attwells, adarí ikọ̀ ìpolongo 36 Months, àjọ tó ń pè fún fífi ọjọ́ orí tí ọmọdé le ṣí ojú òpó ayélujára sí ọdún mẹ́rìndínlógún sọ fún BBC pé ìgbésẹ̀ náà yóò jẹ́ kí àwọn ọmọdé mọ ohun tí wọ́n ń fẹ́ fúnra wọn kí wọ́n tó máa lo ojú òpó ayélujára.
Àwọn ojú òpó wo ni ọ̀rọ̀ kàn?
Ìjọba Australia ní àwọn ojú òpó tí òfin náà kan ni Facebook, Instagram, Snapchat, Threads, TikTok, X, YouTube, Reddit àti Kick.
Bákan náà ni ìjọba tún ń kojú ìpè pé kí wọ́n fòfin de àwọn ojú òpó tí wọ́n ti máa ń ṣe eré pàápàá Roblox àti Discord.
Ìjọba ní àwọn yóò máa ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn iléeṣẹ́ tí òfin náà dè yẹ̀wò, tí àwọn yóò sì ohun mẹ́ta tó ṣe pàtàkì láti fi ṣe àgbéyẹ̀wò wọn.
YouTube Kids, Google Classroom àti WhatsApp kò fara gbá nínú òfin yìí, tí àwọn yóò sì máa ṣiṣẹ́ lọ. Bákan náà láwọn ọmọd;e yóò máa ní àǹfàní láti máa lo YouTube lọ nítorí òun kò nílò ìlànà fífi orúkọ sílẹ̀.
Báwo ni wọ́n ṣe máa ṣe àmúṣẹ òfin yìí?
Àwọn òbí àtàwọn ọmọdé kò ní fara gbá tí wọ́n bá ṣẹ̀ sófin yìí. Àwọn iléeṣẹ́ tó ní àwọn ojú òpó yìí ni wọ́n gbọdọ̀ ri pé ó fẹsẹ̀ múlẹ̀.
Iléeṣẹ́ tó bá ṣẹ̀ sófin yìí máa san owó ìtanràn £49.5mílíọ̀nù (US$32 million, €25 million).
Ìjọba gbàgbọ́ pé àwọn iléeṣẹ́ ló gbọdọ̀ gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn ọmọdé kò ní àǹfàní láti ṣí ojú òpó wọn.
Onírúurú ìlànà ni wọ́n ti là kalẹ̀ láti ri pé òfin náà fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó fi mọ́ lílo àwọn ìwé ẹ̀rí nígbà tí wọ́n bá fẹ́ forúkọ sílẹ̀ lórí ayélujára.
Meta, tó ni ojú òpó Facebook, Instagram àti Threads sọ pé láti ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kejìlá ni àwọn máa bẹ̀rẹ̀ sí ní ti ojú òpó tó jẹ́ àwọn ọmọdé tó wà lórí ìkànnì náà.
Wọ́n ní ẹni tí àwọn bá ṣe àṣìṣe láti fi ti ojú òpó máa nílò láti ṣe fídíò láti fi hàn pé òun kìí ṣe ọmọdé.
Àwọn iléeṣẹ́ míì kò ì tíì sọ bí wọ́n ṣe fẹ́ ṣe àmúṣẹ ti wọn.
Ṣé ó máa ṣiṣẹ́?
A ò lè sọ bóyá ìgbésẹ̀ náà máa so èso rere nítorí kò ì tíì sí ìlànà kan gbòógì táwọn iléeṣẹ́ náà fẹ́ lò nítorí àwọn kan ń bẹ̀rù pé lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ láti fi mọ ọjọ́ orí èèyàn le ṣe àṣìṣe nígbà míì.
Àbọ̀ ìwádìí ìjoba Australia ní lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ láti fi wo ojú ẹni tó bá fẹ́ ṣí ojú òpó ayélujára kò kájú òṣùwọ́n tó láti fi ṣàwárí àwọn ọmọdé.
Bákan náà ni àwọn èèyàn kan sọ pé owó ìtanràn tí ìjọba ní àwọn iléeṣẹ́ tó bá rúfin yóò máa san kéré.
Stephen Scheeler, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí ní Facebook sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Australia Associated Press pé Meta ń pa owó tó $50m láàárín wákàtí méjì.
Àwọn lámèyítọ́ míì wòye pé fífi òfin de àwọn iléeṣẹ́ yìí kò ní mú àdínkù bá ewu táwọn ọmọdé ń kojú lórí ayélujára nítorí òfin náà kò kan àwọn ojú òpó tó wà fún fífẹ́ ara ẹni àtàwọn tí wọ́n ti máa ń ta géèmù.
Bákan náà ni wọ́n ní kò kan AI, èyí tí wọ́n ló ń kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè pa ara wọn àti tí wọ́n ń lò láti fi máa sọ̀rọ̀ ìbáraẹnilòpọ̀.
Àwọn mìíràn wòye pé ó sàn láti kọ́ àwọn ọmọdé bí wọ́n ṣe lè máa lo àwọn ojú òpó yìí dípò fífi òfin dè é pátápátá.
Mínísítà fọ̀rọ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní Australia, Annika Wells sọ pé ìgbésẹ̀ náà le jẹ́ èyí tí kò dára jù ṣùgbọ́n tó máa ní ipa rere.
Kí ni àwọn iléeṣẹ́ tó ni social media sọ?
Àwọn iléeṣẹ́ tó ni social media kò faramọ́ ìgbésẹ̀ yìí nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kéde rẹ̀ nínú oṣù Kọkànlá, ọdún 2024.
Wọ́n ní ó máa ṣòro láti ṣe àmúṣẹ rẹ̀ àti pé àwọn ọmọdé le wá ọ̀nà láti lùgbàdì òfin náà.
Wọ́n ní ó máa mú kí àwọn ọmọdé máa ṣe àwọn ohun tí kò tọ́ lórí ayélujára, tí kò sì ní fún wọn ní àǹfàní láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ wọn.
Google, tó ni iléeṣẹ́ YouTube ní àwọn ṣì ń gbèrò láti pe ẹjọ́ lórí bí wọ́n ṣe ka àwọn pọ̀ mọ́ àwọn iléeṣẹ́ náà. Wọn kọ̀ láti fún BBC lésì sáwọn ìbéèrè.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Meta ní àwọn máa ṣe àmúṣẹ òfin náà, wọ́n ní ìgbésẹ̀ náà kò tọ̀nà tó.
TikTok àti Snap náà sọ pé àwọn máa ṣe àmúṣẹ rẹ̀ bí í tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn náà kò faramọ.
Ṣé àwọn ọmọdé kò ní máa lo ọgbọ́n míì?
Àwọn ọmọdé tó bá BBC sọ̀rọ̀ sọ pé àwọn máa ṣí ojú òpó ayélujára míì pẹ̀lú píparọ́ ọjọ́ orí wọn kó tó di pé òfin náà máa fẹsẹ̀ múlẹ̀.
Àmọ́ ìjọba ní àwọn nírètí pé àwọn iléeṣẹ́ tó ní àwọn ojú òpó náà máa mọ èyí tí wọ́n sì máa wọ́gile.
Lórí ayélujára, àwọn ọmọdé ń fún ara wọn lámọ̀rà lórí ojú òpó míì tí wọ́n ti lè máa kàn síra àti èyí tó máa ṣe ìrànwọ́ fún wọn lórí òfin náà.
Àwọn ọmọdé míì ti ń darapọ̀ mọ́ ojú òpó àwọn òbí wọn.
Ṣùgbọ́n Atwell sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdé ń wá ọ̀nà láti yẹ̀ kúrò lórí òfin yìí, ohun tó dájú ni pé òfin náà ti wà nílẹ̀. "A ní òfin láti dá ààbò bo wọn."















