Ọkùnrin tó jí ara rẹ̀ gbé láti gba owó lọ́wọ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ l'Ondo dèrò àtìmọ́lé

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo pẹlu ibọn ilewọ lọwọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Ondo Police Command

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan to parọ fun awọn mọlẹbi rẹ pe wọn ji oun gbe lati gba owo lọwọ wọn.

Mathew Ekele ni ọwọ tẹ niluu Ogbese to wa loju ọna marosẹ ilu Akure siluu Owo.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Ayanlade Olayinka Olushola lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan niluu Akure.

Bi aṣiri Mathew atawọn ẹmẹwa rẹ ṣe tu

Gẹgẹ bii atẹjade ọlọpaa, agbarijọpọ akitiyan ọlọpaa, ẹgbẹ OPC atawọn ọdẹ ibilẹ lo jẹ ki aṣiri ọrọ naa tu.

O ni asiko ti awọn agbofinro ọhun n ṣiṣẹ ninu igbo Kashimola/Agunla ni wọn pade ọkunrin meji kan, John Peter ati James Peter lori alupupu lati abule Igbodudu to wa lẹba Daada Ala.

Ayanlade sọ pe asiko ti wọn yẹ ara awọn ọkunrin naa wo ni wọn ba owo ti iye rẹ jẹ ₦800,000 lọwọ wọn, paali siga Benson kan to fi mọ igo Aromatic Schnapps kan.

Nigba ti awọn gbofinro fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, wọn ni ajinigbe to ji aburo awọn gbe lawọn fẹ lọ gbe owo naa fun lati gba itusilẹ rẹ.

Lẹyin eyii ni ọlọpaa fi ogbọn tan ẹni to fẹ wa gba owo itusilẹ naa ti wọn si ko ṣẹkẹkẹṣẹkẹ sọwọ rẹ.

Ninu iwadii ọlọpaa ni akara tu sepo pe wọn ko ji Mathew gbe amọ oun funra rẹ lo da bii ọgbọn lati gba owo lọwọ awọn mọlẹbi rẹ.

Lẹyinorẹyin, ọwọ ọlọpaa tẹ Matthew lẹba igbo kan niluu Ogbes nibi to n duro si lati gba owo itusilẹ ti awọn mọlẹbi rẹ fẹ san.

Ọlọpaa wọgile banga yinyin lasiko ọdun

Ninu iroyin miran, ileeṣẹ naa ti sọ pe ko si ni aaye fun ohunkohun to farajọ banga yinyin atawọn ohun amuṣere bii iru rẹ lasiko ọdun yii.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa ni igbesẹ naa ko ṣẹyin oniruru iṣẹlẹ ijinigbe to gbode, to fi mọ eto aabo to mẹhẹ.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, Adebowale Lawal, tun kilọ fun awọn to n ji ara wọn gbe lọna ati gba owo lọwọ awọn mọlẹbi wọn ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ ki wọn ma ba rija ofin.

O pari ọrọ rẹ pe ileeṣẹ naa ko ni la oju rẹ silẹ ki awọn ọdaran fi ipinlẹ Ondo ṣe ibuba.