"Ẹ wo bí ẹ̀rí èké tí mo jẹ́ nílé ẹjọ́ ṣe sọ ọ̀dọ́ mẹ́ta tí kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn dèrò ẹ̀wọ̀n ódún 36"

Lati apa osi, Alfred Chestnut, Andrew Stewart, ati Ransom Watkins ya fọto papọ lẹyin ti ile ẹjọ dawọn silẹ lori ipaniyan ti wọn ohun kan nipa rẹ lọdun 1983 ti wọn ṣẹwọn le lori

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ron Bishop mọ ninu ara rẹ pe irọ loun n pa.

Ọmọ ọdun mẹrinla pere ni i ṣe nigba ti o n jẹrii niwaju adajọ nibi igbẹjọ ẹsun ipaniyan.

Ẹjọ naa da lori awọn ọdọ mẹta ti wọn fẹsun kan wi pe wọn ṣekupa ọrẹ rẹ timọ timọ, DeWitt Duckett, loṣu Kọkanla ọdun 1983.

Alfred Chestnut, Andrew Stewart ati Ransom Watkins ni Bishop n jẹrii tako nile ẹjọ.

Ẹjọ naa si ti n lọ daadaa pẹlu ẹlẹrii mẹta kan ti wọn ti jẹrii nile ẹjọ, eyi lo jẹ ki Bishop ronu pe ki ni yoo ṣẹlẹ toun ba sọ nnkan to tako ọrọ awọn to ti jẹrii.

''Awọn ẹlẹrii mẹta to ti sọrọ fidi rẹ mulẹ pe awọn ọdọ mẹta naa jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn.

Ero mi nigba naa ni pe ile ẹjọ le ma gbami gbọ ti mo ba sọ nnkan to yatọ si ohun tawọn to ti jẹrii tẹlẹ ti sọ,'' Bishop lo sọ bẹẹ.

Irọ ti Bishop pa yii lo ran awọn ọdọ alawọdudu mẹta lọ ẹwọn ni Baltimore.

O le ni ọgbọn ọdun ti ẹri ọkan Bishop fi n da a laamu wi pe irọ to pa lo ran awọn alaiṣẹ lọ sẹwọn.

Iṣẹlẹ ipaniyan nile ẹkọ

Oloogbe Dewitt Duckett, ọdọkunrin ọmọ ọdun mẹrinla wọ ewu alawọ dudu ati funfun.

Oríṣun àwòrán, Ron Bishop

Nigba ti Bishop n dagba ni kekere, o maa n ro pe aabo to peye wa nile ẹkọ fawọn akẹkọọ.

Amọ, wọn ti pa arakunrin rẹ lai ri ẹni to ṣiṣẹ laabi yii.

Ọrẹ meji ti Duckett jẹ ọkan ninu wọn ni Bishop maa n ba ni ajọṣepọ daadaa lasiko to ba wa nile ẹkọ.

'''Duckett ko laapọn, a si ni ọrẹ mii to ṣikẹta wa toun naa n gbe ladugbo,''Bishop lo sọ bẹẹ.

Harlem Park jẹ ile ẹkọ to tobi gan an ti o si le pẹlu, awọn ọrẹ mẹtẹẹta yii maa n wa ọna abuja lati ma le bọ si aarin ero.

Wọn gba ọkan lara awọn ọna abuja naa loṣu Kọkanla ọdun 1983.

Ron Bishop ọmọ ọdun mẹrinla ree niwaju ẹrọ kamẹra

Oríṣun àwòrán, Ron Bishop

''A n rin lọ ninu ọgba ile ẹkọ ni nigba ẹnikan ṣadeedee sọ pe ki Duckett bọ aṣọ ọrun rẹ wa.''

Aṣọ ẹgbẹ agbabọọlu alapẹrẹ Georgetown University ti gbogbo eeyan fẹran ni Duckett wọ lọjọ naa.

''Nigba ti mo yi wo ẹgbẹ mi, mo rii pe ẹnikan ti na ibọn si mi, bi mo ṣe sun sẹyin ni ẹni naa na ibọn sọrun Duckett.

Emi ati ọrẹ mi bérẹ sii salọ, bi a ti n salọ ni a gbọ iro ibọn.''

Bishop ni bayii lawọn ṣe sa de ile ounjẹ awọn akẹkọọ, o ni nibẹ ni DeWitt ti n di mọ ọrun rẹ ti o si ṣubu silẹ.

Iṣẹ iwadii bẹrẹ

Ami idanimọ ileeṣẹ ọlọpaa Baltimore.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pẹlu iyalẹnu gbogbo nnkan to ṣẹlẹ, gbogbo wọn pada lọ sile wọn.

Amọ, ko pẹ ko jina ni awọn ọlọpaa bẹrẹ sii wa gbogbo wọn kaakiri.

Ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, Donald Kincaid, to wọle wa bawọn lagọ ọlọpaa lo sọ fun wọn pe Duckett ti ku.

Bishop loun o mọ boun ṣe le ṣapejuwe nnkan to n ṣẹlẹ ninu ara oun nigba naa.

Afurasi kan di mẹta

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin ọjọ meloo kan ni ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọ sile Bishop.

O ni wọn fi ori'siiriṣii fọto awọn afurasi han oun, ṣugbọn oun sọ fun wọn pe oun ko ri ẹnikéni nibẹ to jẹ pe oun lo pa Duckett.

Bishop sọ pe nigba to ya ni ọlọpaa Kincaid mu oun wọ inu yara kan ti o si bẹrẹ si fọrọ wa oun lẹnu wo lori iku Duckett.

O ni Ọgbẹni Kincaid sọ pe irọ loun n pa wi pe oun ko fẹ jẹwọ nnkan to ṣẹlẹ ni.

Bishop ni ẹlẹrii tuntun mii ti darukọ afurasi mẹta wi pe awọn lo pa Duckett, ati pe ẹlẹrii meji mii naa sọ bẹẹ.

Amọ, Bishop mọ ninu ara rẹ pe ẹnikan ṣoṣo lo ṣekupa Duckett.

Bishop ni bayii ni ọlọpaa naa binu to si fẹẹ maa fi ibọn dẹru ba oun.

O ni nigba naa loun sọ pe oun ṣetan lati sọ nnkan ti wọn ba fẹ koun sọ.

Lẹyin o rẹyin, Bishop buwọlu iwe wi pe Chestnut, Stewart ati Watkins lówọ ninu iku ọrẹ rẹ.

Lẹyin naa ni wọn mawọn mẹtẹẹta ti wọn si ran wọn lẹwọn.

Bishop ni oun mọọmọ ma sọ fun ẹbi oun ni papaa julọ tori oun ko mọ bi mama oun ṣe maa gba ọrọ naa, ati pe koun ma baa bawọn ọlọpaa ninu.

Ileejẹ ilu Baltimore

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igbẹjọ

Bishop ni niṣe loun n gbọn nigba ti wọn ni koun wa jẹrii nile ẹjọ tori nnkan ti ko ṣẹlẹ ni wọn sọ pe koun maa sọ.

O ni irọ ni wọn sọ pe ko oun pa, ati pe oun loun jẹrii kẹyin dipo ki oun kọkọ jẹrii.

''Mo lero wi pe ile ẹjọ ro pe mo n parọ ni tori ọmọ ọdun mẹrinla ni mi nigba naa, bo tilẹ jẹ otitọ ni mo n sọ.

Ọlọpaa Kincaid ti dunkoko mọ mi ṣaaju pe emi naa lọwọ ninu iku Duckett pẹlu awọn afurasi to n jẹjọ,'' Bishop ṣalaye.

Lẹyin o rẹyin, Bishop sọ pe awọn afurasi mẹta yẹn naa lo wa nidi iku Duckett.

Ileejọ si dajọ iku ati ẹwọn gbere fun wọn.

Ron Bishop jokoo, o n wo ẹrọ kamẹra niwaju rẹ

Oríṣun àwòrán, Ron Bishop

Ẹri ọkan to n da eeyan lẹbi

Ọgbẹni Bishop sọ pe ni gbogbo igba ni ẹri ọkan oun maa n da oun laamu wi pe ẹri eke loun jẹ nile ẹjọ.

''O dami loju pe awon eeyan yii kọ lo pa Duckett, mo si mọ pe ẹlomiran lo ṣiṣẹ naa.

Mo tun maa n ro pe abi wọn le fẹ pa emi naa ni?''

Bishop pada lọ sile ẹkọ giga fasiti nibi to ti kọ nipa ero ẹro ati ihuwasi ẹda.

Amọ, nnkan kan to maa n wa lọkan rẹ ni pe oun yoo sọ nnkan to ṣẹlẹ lọjọ kan.

Ọdun 2019 ni akoko naa de lẹyin ọgbọn ọdun ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Awọn ọlọpaa pe Bishop fun ifọrọwanilẹnuwo, wọn si fidi rẹ mulẹ ileeṣẹ ọlọpaa lo fipa mawọn ọmọde lati jẹrii eke.

Wọn si tun fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣewadii afurasi mii ti wọn ri lẹgbẹ ile ẹkọ naa mọ lẹyin ti wọn ti mu afurasi mẹta ti wọn ran lọ sẹwọn.

Ẹlerii kan jẹrii nigba naa pe ọkunrin kan, Michael Willis lawọn eeyan kan ri lẹgbẹ ile ẹkọ naa lasiko iṣẹlẹ ọhun ti o si wọ aṣọ Georgetown sọrun.

Ọdun 2002 ni wọn yinbọn pa Willis, iku si ni ko jẹ ki wọn mọ ẹni to pa Duckett gan an.

In October 2023, the city of Baltimore reached a Loṣu Kẹwaa ọdun 2023 ni ilu Baltimore pinnu lati fawọn ọkunrin mẹtẹẹta naa ni 48-million gẹgẹ bii owo gba mabinu lori ẹwọn ti wọn ṣe lai ṣẹ.

Ọkan Bishop naa ti mọ bayii, koda, o ni oun ṣetan lati tọrọ aforijin lọwọ wọn ti oun ba le ri wọn.