Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fọ́kùnrin márùn ún tó dáwọ́ jọ lu awakọ̀ 'taxi' pa n'Ibadan

Okun ti wọn maa n fi yẹgi fun ẹni ti ile ẹjọ ba dajọiku fun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo ti dajọ iku fun ọkunrin marun un lẹyin ti wọn jẹbi ẹsun iṣekupani awakọ taisin ikan, Akeem Shittu, niluu Ibadan lọdun 2024.

Nigba ti o n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Oyeyemi Ajayi, dajọ wi pe Segun Taiwo, Kehinde Ademola, Yahaya Adeniyi, Chinonso Samson ati Opadotun Michael gbimọ pọ lati ṣeku pa Shittu.

Adajọ sọ ninu idajọ rẹ pe ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ wi pe awọn maraarun un lo gbimọ pọ ṣeku pa Shittu.

Adajọ naa kọkọ ju ẹnikọọkan wọn si ẹwọn ogun ọdun lori pe wọn jẹbi ẹsun igbimọpọ lati ṣeka, ki o to dajọ iku fun wọn.

Idajọ ile ẹjọ lori koko ẹsun keji ti wọn fi wọn kan awọn maraarun un ni pe ki wọn lọ yẹgi fun wọn.

Ṣaaju ni agbẹjọro ijọba, K.K. Oloso, ṣalaye bi ijamba ọkọ ti ko mu ẹmi lọ ṣe yọri si ikọlu to gbẹmi eeyan.

''Awakọ 'taxi' naa gbiyanju lati sa asala fun ẹmi rẹ, amọ wọn le e mu, wọn si ṣa a pa pẹlu ada''

Agbọjọro to ṣoju ijọba ipinlẹ Oyo, Oloso, ṣalaye wi pe ''lọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin ọdun 2024 ni nnkan bii ago méjọ aabọ alẹ lopopona Elepe si Arulogun lagbegbe Ojoo niluu Ibadan lawọn ọkunrin marun un naa atawọn mii ti wọn ti salọ ṣekọlu si Shittu lẹyin ti ọkọ rẹ gba ọkada to gbero meji lẹyin.

Bayii ni gbogbo wọn lọ si ibi kan lati yanju ọrọ naa, nibẹ ni ẹni to gun ọkada naa atawọn alatilẹyin rẹ ti sọ pe ki awakọ taisin ọhun fawọn ni N50,000 lati lọ tọju awọn to farapa.

Amọ, N8,000 pere ni Shittu ri ko da silẹ, bayii ni wọn ko jẹ ko lọ ti wọn mu un mọlẹ.

Ka to wi ka to fọ, wọn ti ya aṣọ mọ Shittu lara, wọn si ja a si ihoho.''

Agbẹjọro ijọba ni bo tilẹ jẹ pe awakọ taisi naa gbiyanju lati sa asala fun ẹmi rẹ, o ni wọn le e mu, wọn si ṣa a pa pẹlu ada.

Awọn oluwadii fidi rẹ mulẹ pe niwaju ṣọọbu iyawo ọkan lara awọn to lu u pa ni wọn ti ri ọkọ ati aṣọ ilewọ rẹ.

Ile ẹjọ ni ẹṣẹ tawọn ọkunrin marun un naa ṣẹ lodi sofin ọdaran ipinlẹ Oyo abala 316, ijiya si wa fun iru ẹṣẹ bayii ni abala 319 ati 324 ofin yii ti ọdun 2000.