Nàìjíríà lọ́ bá Amẹ́ríkà ṣèpàdé lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ tí Trump pariwo rẹ̀, kókó àbọ̀ wọn rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìjọba Nàìjíríà ti ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti gbà láti ṣe iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà lójúnà àti wá ojútùú sí ìpèníjà ààbò tó ń bá orílẹ̀ èdè yìí fínra.
Ìfẹnukò yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ìpàdé alágbára kan tó wáyé láàárín àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè méjéèjì ní Washington D.C. ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Ààrẹ Tinubu, Bayo Onamuga fi síta lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ṣàlàyé pé ikọ̀ tí Nàìjíríà rán lọ sí Amẹ́ríkà lábẹ́ èyí tí olùdámọ̀ran ààrẹ, Nuhu Ribadu kó sòdí lo gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kó yé ìjọba Amẹ́ríkà pé kò sí èròńgbà láti pa ìran kan, ẹ̀yà kan tàbí ẹlẹ́sìn kan run ní Nàìjíríà.
"Ìjọba Amẹ́ríkà yóò ran Nàìjíríà lọ́wọ́ lórí ìpèsè ààbò, ohun èlò ìjà ogun àti níní àǹfàní sáwọn ohun èlò ìjà ogun Amẹ́ríkà"
Ó sọ pé wọ́n ṣe àfọ́mọ́ rẹ̀ pé làásìgbò tó ń bá Nàìjíríà fínra lọ́wọ́ yìí jẹ́ ohun tó ń wáyé látọwọ́ àwọn ọ̀daràn, àwọn alákatakítí ẹ̀sìn àti ohun tó nííṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ilẹ̀, tí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú kíkọ ojú oro sáwọn ẹlẹ́sìn kan pàtó.
Ó ní ìpàdé náà mú kí ìjọba Amẹ́ríkà jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹyìn láti ṣe ìrànwọ́ fún Nàìjíríà lórí ìpèsè ààbò tó fi mọ́ pípèsè ohun èlò ìjà ogun àti níní àǹfàní sáwọn ohun èlò ìjà ogun Amẹ́ríkà tí Nàìjíríà bá nílò rẹ̀ láti kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí.
Ó ṣàlàyé pé ìpàdé náà tún jẹ́ ojúnà láti fi jẹ́ kó yé àwọn ọmọ Nàìjíríà pé ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà ṣì ń tẹ̀síwájú àti pé ìjọba Nàìjíríà mọ pàtàkì kí gbogbo èèyàn le ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú láì sí ìbẹ̀rù kankan.
Ó fi kun pé ìjọba ń gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti ri dájú pé ààbò tó péye wà fún gbogbo aráàlú.
Kí ló mú ìjọba Nàìjíríà rán ikọ̀ ránṣẹ́ sí Amẹ́ríkà
Ẹ ó rántí pé ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí ni ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump dúnkokò láti kó àwọn ọmọ ogun wọ Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń pa àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni lọ́nà àìtọ́ àmọ́ ìjọba Nàìjíríà ti jiyàn ẹ̀sùn náà.
Trump tún kéde Nàìjíríà bíi orílẹ̀ èdè tó ń jẹ́ ìkọnilóminú fún òun àti pé òun máa ṣe ìkọlù sí Nàìjíríà tí ìjọba kò bá tètè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí ìpèníjà ààbò tó ń ba fínra.
Láti ìgbà tí Trump kéde ìdúnkokò rẹ̀ yìí ni àwọn ìkọlù lọ́kan-ò-jọ̀kan tún ń wáyé pàápàá lẹ́kùn àríwá Nàìjíríà.
Lẹ́yìn náà ni àwọn agbébọn ṣèkọlù sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ méjì ní ìpínlẹ̀ Niger àti Kebbi níbi tí wọ́n ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún gbé lọ, tí wọ́n sì pa ó kéré tán òṣìṣẹ́ méjì.
Bákan náà ni àwọn agbébọn tún ṣèkọlù sí ilé ìjọsìn CAC ní ìlú Eruku, ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti, ìpínlẹ̀ Ekiti níbi tí èèyàn mẹ́ta ti pàdánù ẹ̀mí wọn.
Ìjọba Nàìjíríà ní àwọn ti gbá àwọn olùjọsìn méjìdínlógójì táwọn agbébọn náà jí gbé lọ padà.
Àwọn wo ni ìjọba Nàìjíríà rán lọ sí Amẹ́ríkà?
Lẹ́yìn ìdúnkokò Donald Trump ni ààrẹ gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti jíròrò pẹ̀lú ìjọba Amẹ́ríkà tí wọ́n sì ṣàpàdé pẹ̀lú aṣòfin Riley Moore.
Lára àwọn tó lọ ibi ìpàdé náà ni:
- Mallam Nuhu Ribadu – Olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ààbò
- Her Excellency, Bianca Ojukwu – Mínísítà kejì fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè
- Kayode Egbetokun - Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Lateef Olasunkami Fagbemi, SAN – Agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà
- Ọ̀gágun Olufemi Oluyede - Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun
- Lt. Gen. Emmanuel Undiandeye - Chief of Defence Intelligence
- Ms. Idayat Hassan – Olùdámọ̀ràn sí ONSA
- Ambassador Ibrahim Babani – Adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ní ONSA















