Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tíwà ìjínigbé tí gogò ní Nàíjíríà, kí ló dé tí ìjọba kò ṣe tí ì rẹ́yìn rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Ifeanyi Immanuel Bakwenye / AFP via Getty Images
Lọwọ yii, Naijiria n koju ijinigbe to fẹẹ buru julọ ninu itan rẹ lẹyin ti awọn agbesunmọmi ji awọn ọmọ ile ẹkọ to le ni 300 gbe lọ nile ẹkọ kan nipinlẹ Niger.
Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe nnkan bii aadọta ninu awọn akẹkọọ naa ti moribọ.
Ijinigbe yii ni ikẹta iru rẹ laarin ọsẹ kan ṣoṣo.
Jiji awọn eeyan gbe lati pa owo ti di iṣoro nla ti tọmọde-tagba n koju ni Najiria bayii.
O ti le ni ọdun mẹwaa bayii ti ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ti ji akẹkọọ 276 gbe nile ẹkọ wọn kan niluu Chibok, nipinlẹ Borno.
Ijinigbe ọhun milẹ titi lasiko naa to bẹẹ ti awọn eeyan kaakiri agbaye pe fun idapada awọn akẹkọbirin naa.
Bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu awọn akẹkọọ Chibok yii ni wọn ti gba itusilẹ tabi bọ lọwọ awọn to ji wọn gbe, nnkan bii ọgọrun ninu wọn lo ṣi wa ni ahamọ.
Wayi o, ọdun mẹwaa lẹyin ti wọn ji awọn akẹkọọ Chibok gbe, kilode ti ijinigbe ṣi n tẹsiwaju ni Naijiria?

Oríṣun àwòrán, John Okunyomih/ AFP via Getty Images
Awọn ile ẹkọ to wa ni igberiko
Pupọ ninu awọn ilu to wa ni ariwa Naijiria lo n koju eto abo to mẹhẹ, paapaa lawọn ilu to wa ni igberiko.
Ọna kan ti awọn agbebọn fi maa n kọlu awọn ilu ọhun – awọn agbesunmọmi naa yoo wa lori alupupu, wọn yoo bẹrẹ si n yinbọn lati ṣeruba awọn eeyan, wọn yoo sare tete ji awọn ti wọn fẹ ji gbe, ti wọn yoo si dari wọn sinu igbo to wa nitosi.
Awọn onimọ gbagbọ pe awọn ikọlu naa n waye lọna ati pa owo wọle ju nitori ọrọ ẹsin lọ, bẹẹ ni wọn si n kọlu awọn ile ẹkọ nitori eto abo ti ko si nibẹ.
Awọn onimọ tun ni awọn agbesunmọmi naa gbagbọ pe awọn obi ko ni kọ lati san owo itusilẹ ki wọn le tun awọn ọmọ wọn silẹ ni ahamọ.
Wayi o, ni ariwa ila oorun ti agbesunmọmi Boko Haram ti n ji eeyan gbe, kii ṣe owo nikan ni wọn n wa, ikọlu wọn tun ni ọrọ ẹsin Islam lọwọ latari bi wọn ṣe kọ iwe kika ti wọn si gbagbọ pe awọn ọmọdebinrin ko lẹtọọ lati kawe.
Gẹgẹ bii ohun ti UN sọ, Boko Haram ṣọṣẹ fun ọdun mẹwaa o le, wọn pa ọpọ eeyan, wọn tun sọ ọpọ awọn mi di alainilelori.
Awọn onimọ ni eto abo to mẹhe ni Naijiria ko ṣẹyin iṣubu Aarẹ Muammar Gaddafi lọpọ ọdun sẹyin, ti awọn agbesunmọmi ibẹ si n ko ohun ija oloro lati ilẹ naa wọ wọ Naijria.

Oríṣun àwòrán, Adam Abu-bashal/Anadolu via Getty Images
Ko si iwe kika lai si owo itusilẹ
Ijọba ni oun ti fofin de sisan owo itusilẹ fun awọn ajinigbe lọna ati din iye owo ti wọn n pa wọlu ku amọ igbesẹ naa ko fi bẹẹ so eso kankan.
Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti sun irinajo to yẹ ko ṣe silẹ okere siwaju lọna ati bojuto eto abo to mẹhẹ.
Bẹẹ lo tun paṣẹ ki wọn gbe ogoji ile ẹkọ giga to jẹ ti ijọba ti pa.
Amọ eto abo to mẹhẹ naa n bi ọpọ araalu ninu eyii to mu ki wọn maa bere fun igbesẹ akin lati ọdọ ijọba lati yanju iṣoro naa.
Ileeṣẹ ọmọ ogun n tiraka lati koju eto abo to mẹhẹ ni ariwa amọ o dabii pe apa wọn ko ka.
Lawọn ilu kan lawọn agbege naa, ijọba n gbojule awọn ori ade lati ba awọn agbesunmọmi naa ṣepade alaafia lati le yanju iṣoro ọhun.

Oríṣun àwòrán, Pius Utomi Ekpei/AFP via Getty Images
Ọrọ aje lo fa a
Awọn onimọ kan ti sọ pe iṣẹ ti ko si, paapaa lawọn agbegbe ariwa lo tun bọ jẹ ki ijinigbe maa peleke si.
Fun apẹrẹ, ina ijọba ti ko ṣe dede le ṣakoba fun awọn olokoowo kekeke.
Ninu arokọ kan ninu iwe iroyin BusinessDay, wọn ni pupọ awọn to n jinigbe lo jẹ pe wọn ko niṣẹ lọwọ.
Arokọ naa ni "ijinigbe ti di nnkan ti ọpọ ọdọ ti ko riṣẹ fi n ṣe iṣẹ ṣe."
Ileeṣẹ kan to n ri si eto abo, SBM Intelligence sọ pe ijọba gbọdọ wa ojutuu si iṣẹ ti ko si lọna ati yanju eto abo to mẹhẹ.
Ohun ti Trump sọ nipa Naijiira
Lẹyin ti ijọba Amẹrika sọ pe awọn alakatakiti ẹsin Islam n ṣekupa awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria ti ijọba si kawọ gbera ni wọn ji awọn akẹkọọ wọnyii lọ.
Fun ọpọlopọ oṣu lawọn oloṣelu ni Washington fi n fẹsun kan awọn alakatakiti ẹsin naa pe wọn n pa Kristẹni ni Naijiria amọ ijọba apapọ ni ko ri bẹẹ.
Ni ibẹrẹ oṣu yii, Trump ni oun yoo fi ọmọ ogun ṣọwọ si Naijiria toun ti ohun ija oloro ti ijọba Naijiria ko ba wa ojutu si iṣekupa awọn Kristẹni naa.
Oṣiṣẹ ijọba Naijiria kan sọ pe awọn agbesunmọmi ko wo boya eeyan jẹ Musulumi tabi ọmọlẹyin Kristi ki wọn to gbẹmi rẹ.
O ti le ni ọpọ ọdun ti awọn alakatakiti ẹsun ti n gbẹmi eeyan ni iha ariwa.
Awọn ajọ kan sọ pe pupọ ninu awọn to n padanu ẹmi wọn ninu awọn ikọlu naa lo jẹ Musulumi latari pe agbegbe naa ni Musulumi pọ si julọ ni Naijiria.
Ni aringbungbun Naijiria, awọn darandaran ti pupọ wọn jẹ Musulumi naa n ṣekọlu si awọn agbẹ, ti pupọ wọn jẹ ọmọlẹyin Kristi.
Amọ ṣa, awọn omimọ kan ti sọ pe ikọlu yii lo n waye latari ija ilẹ ti ko si ni nnkankan lati ṣe pẹlu ẹsin.
BBC News, BBC News Africa ati BBC Global Journalism lo ṣe akojọpọ iroyin yii.















