Àwọn jàǹdùkú kọlu Obesere lágbo eré ní Okitipupa, ariwo sọ

Obesere jòkòó lórí àga, wọ aṣọ olómi aro, mú ọ̀pá dání, wọ ṣéìnì sọ́rùn

Oríṣun àwòrán, Obesere/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajúmọ̀ olórin Fuji nnì, Abass Akande Obesere ti képe ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo láti bá òun ṣàwárí àwọn jàǹdùkú tó ṣe ìkọlù sí òun, tí wọ́n sì ba ohun èlò orin òun jẹ́.

Ohun tá a gbọ́ ni pé ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ni Obesere lọ ṣeré níbi ètò ayẹyẹ òkú kan ní ìlú Okitipupa, ìjọba ìbílẹ̀ Okitipupa, ìpínlẹ̀ Ondo táwọn jàǹdùkú kan sì ṣed ìkọlù si.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Obesere fi síta Ayonla Althentic fi sórí ìkànnì Facebook lọ́jọ́ Àìkú sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ba Obesere lọ́kàn jẹ́, tó sì ń rọ àwọn aláṣẹ ní ìpínlẹ̀ Ondo láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ tí irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò fi ní máa wáyé mọ́.

Kí ló ṣẹlẹ̀ gan?

Ó ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde náà pé, lẹ́yìn tí àwọn ṣeré tán, tí àwọn ń kúrò níbi òde àríyá náà ni àwọn jàǹdùkú náà tí wọ́n pọ̀ bìbà yabo àwọn.

"Àwọn kan wá sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀dọ̀ mi nítorí ọwọ́ mi ni owó wà. Gbogbo ìgbìyànjú wa láti ri pé a kúrò níbẹ̀ láyọ̀ ló já sí pàbó, tí wọ́n sì ń sọ pé kí n gbé báàgì owó ọwọ́ mi wá.

"Wọ́n lù mí, èjìká mi yẹ̀, tí wọ́n sì fi ọ̀bẹ gún mi nígbà tí mò ń gbìyànjú láti sá wọ inú ọkọ̀ lọ. Gbogbo ara ló ń dùn mí báyìí."

Althentic fi kun pé apá àwọn jàǹdùkú náà padà ká òun tí wọ́n sì gbé báàgì owó lọ.

Ó ní bí wọ́n ṣe ń ṣèkọlù sí òun ni àwọn míì ń ṣèkọlù sí Obesere kódà lẹ́yìn tó gbìyànjú láti fi owó tú àwọn jàǹdùkú náà ká.

Ó sọ pé àwọn ṣá à gbìyànjú láti gbé ara àwọn dé ìdí ọkọ̀ láti dá ààbò bo ara àwọn àti láti ri pé àwọn lọ tọ́jú ara àwọn.

Ó wá rọ àwọn aláṣẹ láti ṣàwárí àwọn tó ṣe ìkọlù náà, kí wọ́n sì fojú winá òfin lójúnà àti dènà irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

A ti nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́ta - Alága ìjọba ìbílẹ̀

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Okitipupa ní ìpínlẹ̀ Ondo, Andrew Ogunsakin ti wá sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù tó wáyé sí Obesere ní ìlú Okitipupa.

Ogunsakin nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sójú òpó Facebook rẹ̀ sọ pé ọwọ́ ti tẹ àwọn afurasí mẹ́ta tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ìkọlù tó wáyé sí Obesere, tí wọ́n sì ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.

Ó sọ pé àwọn rí àwọn nǹkan gbà padà lọ́wọ́ àwọn afurasí náà àti pé gbogbo àwọn afurasí tó kù ni àwọn ṣì ń dọdẹ wọn, tí àwọn yóò sì ri dájú pé ọwọ́ tẹ̀ wọ́n láìpẹ́.

Ó ṣàlàyé pé ní kété tí òun gbọ́ ìròyìn ìkọlù náà ni òun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti ri dájú pé àlááfíà jọba ní agbègbè náà àti láti ri dájú pé àwọn ṣe ohun tó yẹ.

Bákan náà ló ní pé òun ti kàn sí àwọn aláṣẹ Obesere láti pe ìpàdé pẹ̀lú òun àti ikọ̀ rẹ̀.

Ogunsakin tún gbóríyìn fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò fún bí wọ́n ṣè tètè dìde sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti ọ̀nà tí wọ́n gbà yanjú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Ó tẹmpẹlẹmọ pé ìṣèjọba tó wà lóde kò ní fi ààyè gba ìwà jàgídíjàgan, tí àwọn sì ní ìfarajìn láti mú ìgbéga bá àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Ikale.

Ta ni Obesere?

Obesere wọ aṣọ olómi aro, wọ ṣéìnì sọ́rùn, tó sì tẹ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Obesere/Instagram

Ní ogúnjọ́ oṣù Kìíní ọdún 1965 ni wọ́n bí gbajúgbajà olórin Fújì Abass Akande Obesere.

Obesere àti Ọmọrapala ni orúkọ tí àwọn èèyàn mọ̀ ọ́ sí jùlọ.

Ọmọ bíbí ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ni Obesere tó sì gbajúmọ̀ fún àwọn àṣà tó máa ń dá nínú àwọn orin rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwò orin ni Obesere ti gbé jáde tó fi mọ́ Omorapala Overthrow, Egunun Be Careful, Obaadan, Old Skool Lape, Mr Magic, Introduction àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Obesere ti kọrin káàkiri ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà àti lókè òkun.

Bákan náà ló ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ nílé àti lẹ́yìn odi.