Obasanjo ki ijó mọ́lẹ̀ láàrin ọ̀pọ̀ èrò, bí ọdún Owu 2025 ṣe ṣọkutu wọ̀wọ̀
Ọdun Owu ti ọdun 2025 ti waye, o si ti kọja lọ.
Amọ ọpọ ohun ara meeriri to waye nibẹ ni yoo maa wa ni iranti ọpọ eeyan fun igba pipẹ.
Se ti ijo, ilu, asọ to n pe asọ ransẹ wa woran ati gele ara to wa lori awọn obinrin ni ka sọ ni abi awọn eekanlu to peju sibi ọdun Owu naa.
Koda, Oloye Olusegun Obasanjo, tii se Balogun ilu Owu ati Olowu naa wa lara awọn eekanlu to sọrọ nibi ọdun Owu naa.
Bakan naa, aarẹ ana ni orilẹede Naijiria wa naa tun fi ẹsẹ ra ijo lasiko ọdun Owu naa, eyi to wu ọpọ eeyan lori.

Bawo ni ọdun Owu se bẹrẹ?
Ọpọ eeyan lo n beere pe bawo gan ni ọdun Owu to n milẹ titi yii se bẹrẹ, igba wo si lo bẹrẹ.
Ninu ọrọ rẹ, alaga akọkọ fun ẹgbẹ gbogbo ọmọ bibi ilu Owu nilẹ Naijiria salaye pe ọdun 1984 ni ọdun Owu bẹrẹ.
"Oloye Akin Olugbade to ti di Oloogbe lo bẹrẹ ọdun Owu ni ọdun 1984.
Amọ ọdun 1992 ni Oloye Olusegun Obasanjo tẹwọ gbaa, to si n se ọdun naa daadaa.
Nigba ti oun naa n sọ pataki ọdun Owu, Oloye Sharafa Tunji Ishola ni ọdun Owu naa lo maa n fun awọn ọmọ bibi ilu Owu lati wa sile nibikibi ti wọn wa.
"Ọdun yii lo n mu kawọn ọmọ bibi Owu wale lati wa se ajọyọ, ti wọn yoo si tun wo awọn ohun meremere ti wọn le se silu Owu."

"Bi a ko ba jẹ ki diversity ti a fi da Abeokuta silẹ bajẹ, ilu naa yoo maa dara si ni."
Ninu ọrọ rẹ nibi ayẹyẹ ọdun Owu, Oloye Olusegun Obasanjo ni ẹya pupọ ni wọn fi da ilu Abeokuta silẹ.
"Diversity la fi da ilu Abeokuta silẹ, eyi si lo jẹ ki Abeokuta ni ilọsiwaju ju gbogbo ilu miran lọ.
Bi a ko ba si jẹ ki diversity naa bajẹ, ilu Abeokuta naa yoo maa dara si ni."
Lẹyin eyi ni Balogun Owu naa wa bọ sijo, to si n gbe ẹsẹ siwaju ati sẹyin.



