Ìpolongo àṣà, oge àti kùdìẹkudiẹ tójú rí níbi ayẹyẹ Ojúde Ọba 2025

Aworan lati ayẹyẹ Ojude Oba
    • Author, Afolabi Akinlabi
    • Role, Journalist
    • Reporting from, Ijebu Ode, Nigeria
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ojọ Ṣatide, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹfa ọdun 2025 ni ayẹyẹ Ojude Oba waye niluu Ijebu Ode, lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede NAijiria, to si jẹ pe tilu tifọn ni awọn eeyan ṣe ajọyọ ọdun naa.

Yatọ si awọn ti wọn jẹ ọmọ ilu Ijẹbu ode, ọpọ eeyan lo wa lati origun mẹrin agbaye lati darapọ ayẹyẹ naa.

Yatọ si orisiirisii aṣọ to rẹwa ti awọn eeyan wọ, ọpọ nnkan miran lo tun waye ni gbagede Ojude Oba ọdun 2025.

Awon eeyan n ṣe ara logun lati gbaradi fun Ojude Oba.

Iroyin o to amojuba, Ileeṣẹ BBC naa gbera lati wa nibi ayẹyẹ yii, ṣugbọn o kọja ohun ti a lero.

Akojọpọ ohun ti a fi oju ganni ree nibi ayẹyẹ Ojude Oba 2025.

Ọpọ ero kaakiri agbaye

Ninu ọrọ rẹ nigba to n ba awọn araalu sọrọ nibi ayẹyẹ naa, Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ni ero to wa fun ayẹyẹ Ojude Oba ọdun yii pọ pupọ ju iye ti oun fi ọkan si lọ.

Ọjọ kẹta si ọjọ ti ọdun Ileya ba waye ni ayẹyẹ Ojude Oba maa n waye niluu Ijebu Ode.

Ọpọ ero lo tu sita, to si jẹ pe bẹrẹ lati aago mẹfa owurọ ni awọn eeyan ti wa ni gbagede ti ayẹyẹ ọhun ti waye.

Aworan lati ayẹyẹ Ojude Oba

Koda, o de akoko kan, awọn eeyan yii ni lati maa ti ara wọn ki wọn le ni anfaani lati ri ohun to n sẹlẹ. Bi awọn kan ṣe fẹẹ wọle sibẹ ni awọn kan si n gbiyanju lati jade sita.

A fi oju ganni awọn eeyan ti wọn tilẹ daku gbọnrangandan lasiko kan latari apọju ero ati oru, ṣugbọn iranlọwọ dide fun wọn lati ọwọ awọn eeyan to wa ni ayika naa.

Ọpọ ifọwọtẹara ẹni waye laarin ọkunrin ati obinrin, ti awọn eeyan ko si ni anfaani lati mọ ẹni to n fi ọwọ kan wọn ni awọn akoko kan.

Ole jija

Aworan ero ni gbagede Ojude Oba.

Bi o ti jẹ pe ọpọ ero lo wa ni gbagede ayẹyẹ yii, awọn alọkolohunkigbe pẹlu ko gbẹyin nibe, to si je pe ọpọ eeyan lo padanu ohun ini wọn.

Awọn to ṣe onigbọwọ ayẹyẹ Ojude Oba pese aabo pẹlu awọn ologun, ọlọpaa ati awọn ọkunrin onigẹ nlanla ti awọn eeyan maa n pe ni Bouncer ti wọn gba si gbagede yii. Sibẹsibẹ, ọpọ foonu atawọn dukia miran lo di awati.

Koda, awọn kan lara awọn agbofinro naa gan pẹlu padanu ẹrọ ibaraẹnisọrọ wọn ni akoko kan lasiko ti ayẹyẹ naa n lọ ni gbagede.

Asia ipinlẹ Ijebu

Aworan asia ipinlẹ Ijebu

Lati ẹnu ọna abawọle si iluu Ijebu ni a ti bẹrẹ si i ri asia nla to ṣafihan ipe fun idasilẹ ipinlẹ Ijebu lati ara ipinlẹ Ogun.

Ọpọ awọn idile, paapaa idile ẹlẹṣin to jẹ ti awọn Balogun ni wọn wọle si gbagede ayeyẹ naa pẹlu asia idile wọn ati asia ipinlẹ Ijẹbu.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹnikẹni ko wi ohunkohun nipa ipe yii lasiko ayẹyẹ naa.

Ẹrọ ayelujara dori korikodo

Baba kan n mu ẹlẹrindodo ni Ojude Ọba

Fun wakati mẹjọ ti BBC fi wa niluu Ijebu ni a fi ni iṣoro ẹrọ ayelujara, to si jẹ pe eyi ṣe ọpọ akoba nla fun iṣẹ wa.

Ohun to ba ni lọkan jẹ ni eyi, ọpọ eeyan ni eyi ṣe akoba fun latari bi wọn ko ṣe ri awọn eeyan pe lori ẹrọ ibaraẹni sọrọ tabi kan si wọn lori ayelujara.

Pẹlu bi ero ṣe pọ ni ọpọ sọ ara awọn wọn nu, ti onikaluku si ni lati maa wa ara wọn kiri ni gbagede naa.

Gbagede to kere

Aworan lati ayẹyẹ Ojude Oba

Eyi jẹ ohun to yani lẹnu pupọ nitori o de asiko kan, gbagede ti ayẹyẹ naa ti waye ko gba awọn eeyan to wa si ibi ayẹyẹ naa mọ.

Ọpọ igba ni awọn ẹlẹṣin lati idile Balogun fi ẹṣin wọn ti awọn eeyan ṣubu, tabi ki ẹṣin fi ibinu gba awọn eeyan ni ipa tabi tẹwọn mọle.

Ero naa pọ to bẹẹ gẹ to jẹ pe lati mi eemi sinu di inira fun ọpọ awọn to wa ni gbagede naa.

Ọna to wọ inu Ijebu Ode

Awọn agbofinro nibi Ojude Ọba.

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ṣe alaye pe ayẹyẹ ọlọdọọdun to maa n waye niluu Ijebu Ode, 'Ojude Ọba' ti di ọja ti gbogbo aye n na, ọja yii si ti pakun eto ọrọ aje ipinlẹ Ogun l'apapọ.

Ṣugbọn ọpọ awọn arin irinajo bu ẹnu atẹ lu bi awọn oju ọna to wọ inu ilu ijẹbu ṣe ri pẹlu, bi o tilẹ jẹ pe gomina ipinlẹ naa sọ pe ijọba n pa ọpọ owo wọle pẹlu Ojude Oba.

Ninu ọrọ to sọ nibi ayẹyẹ Ojude Ọba t'ọdun yii, Gomina Abiọdun ni gbogbo ile itura to n bẹ niluu Ijebu Ode ati ayika rẹ ni awọn alejo to wa fun ayẹyẹ naa gba tan, bẹẹ si ni awọn oniṣẹ ọwọ naa ri ti aje ṣe.

Abiọdun fi kun ọrọ rẹ pe ayẹyẹ Ojude Ọba t'ọdun yii lo tobi julọ lati igba ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ naa nitori ọkan ọpọlọpọ awọn ọdọ lorilẹede Naijiria ati ni oke okun ti fa si ajọdun naa.

Ẹṣin gigun

Aworan awọn ọkunrin kan lori ẹṣin.

Ẹsin gigun jẹ ohun pataki, to si jẹ pe ohun gan ni awọn eeyan fẹran lati ma wo lasiko ayẹyẹ Ojude Oba.

Ṣugbọn ni ti ọdun yii, ọpọ eeyan lo farapa latari bi ero ṣe pọ, ti awọn ẹlẹsin si n gbe ẹsin ṣumọ awọn eeyan, ti ọpọ si n sumọ ẹyin, to si fa ki awọn eeyan maa ti ara wọn subu lasiko ayẹyẹ naa.

Ọpọ awọn ẹsin yii ni wọn ko fẹran bi ọpọ eeyan ṣe wa ni ayika wọn, ti wọn si ni lati maa fi ẹsẹ wọn ja.

Ṣugbọn sibẹsibẹ, iwuri nla ni gbigbe aṣa wa larugẹ niluu Ijebu Ode.

Fifun awọn obinrin ni anfaani

Aworan ọmọ ọdun marun-un to gun ẹsin

Ni ti ọdun yii, ọpọ awọn eeyan lati idile Balogun ni wọn tu sita, koda wọn lewaju ẹsin gigun fun idile wọn.

Bẹrẹ lati ori awọn ọdọmọbinrin de agbalagba ni awọn obinrin to jade ti won si siwaju ẹsin gigun fun idile wọn.

Eyi jẹ ohun iwuri pupọ, o si fi pataki ati iwulo obinrin lawujọ ilẹ Yoruba han.

Ọdọmọbinrin ọmọ ọdun marun-un kan ni obinrin to kere ju to gun ẹsin nibi ayẹyẹ Ojude Oba ti ọdun 2025.

Pẹlu ifọkanbalẹ ni ọdọmọbinrin yii fi gun ẹsin yii, ti ọpọ si kan saara si igboya ati ọkan akin rẹ.

Eyi ṣe ṣafihan pataki obinrin ninu awọn idile Balogun niluu Ijebu Ode.