Ojude Oba wáyé, àmọ́ kí ló fà á tí Kábíyèsí Awujale kò fí bá wọn péjú lọ́dún yìí?

Aworan awọn obinrin ati Awujale.

Oríṣun àwòrán, BBC/others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ni ọjọ Aiku ni ajọdun Ojude Ọba, waye nilu Ijẹbu ode, ipinlẹ Ogun lẹkun iwọ oorun Gusu orilẹede Naijiria.

Ajọdun yii ti di gbajugbaja kaakiri agbaye lẹyin ti itan ti fi idi rẹ mulẹ pe agba oye kan ni ilu naa, Balogun Kuku ti bẹrẹ ajọdun naa lọdun.

Ninu gbogbo pọpọṣinṣin to waye lasiko ọdun naa, ohun kan ti awọn eeyan ko ṣai kiyesi ni aisi Kabiyesi ilu Ijẹbu Ode, Ọba Sikiru Adetọna to jẹ Awujalẹ ti Ijẹbu lori ijoko lasiko ajọdun naa.

Kabiyesi Awujalẹ kii pa ọdun yii jẹ bi o ti wulẹ o mọ, eleyi lo si n mu ki ọpọ maa beere pe ki lo ṣe Kabiyesi Awujalẹ Sikiru Adetọna to fi pa ti ọdun yii jẹ.

Awọn ẹlẹsin ibilẹ maa n lọ ki ọba Awujalẹ lasiko ọdun wọn ni ọdọọdun amọ bi Kuku ati awọn eeyan Ijebu Ode ṣe di Musulumi, ni wọn yi ikini naa pada si abẹwo si ọdọ ọba ni ọjọ kẹta ọdun Ileya.

Abẹwo asiko ọdun Ileya yii ni wọn pe ni Ojude Oba, ti Balogun Kuku yoo si lewaju awọn araalu lati lọ ki Awujalẹ.

Ọjọ kẹta ọdun ni wọn maa n ṣe ajọdun yii ti wọn si maa fi n tẹ pẹpẹ aṣa ilẹ Ijẹbu fun gbogbo eeyan.

Iyawo rẹ, Olori Kẹmi Adetọna lo ṣoju rẹ nibi ayẹyẹ ọdun naa.

Ko si atẹjade kankan lati aafin Awujalẹ lori idi ti Kabiyesi Adetọna ko fi bawọn peju sibi ajọdun Ojude Ọba ọdun yii, amọṣa ohun ti ọpọ n di mu ni pe, Kabiyesi Awujalẹ kii ṣe ọmọde mọ lẹni ọdun mọkanlelaadọrun nitori naa o ṣeeṣe ko jẹ wi pe ipa ọjọ ogbo ti n han lara Ọbalaye naa ni.

Ninu ọrọ ti awọn agbaagba meji kan ti wọn sun mọ Ọbalaye naa ati Aafin Awujalẹ fi to BBC Yoruba leti, ọjọ ogbo ati awọn ipenija ilera to rọ mọ ọjọ ogbo kun ara awọn ohun ti ko jẹ ki Kabiyesi naa le darapọ mọ ajọdun naa.