Àkójọpọ̀ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbi ọdún Ojude Oba 2025

Àkọlé fídíò, Gọngọ sọ nibi ọdun Ojude Oba 2025 niluu Ijebu Ode
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọdun Ojude Oba 2025 dun yungba, o mi igboro titi, koda ọpọ eeyan lo n si n sọ nipa rẹ titi di oni ọjọ kẹsan an oṣu Kẹfa bo tilẹ jẹ pe ayẹyẹ naa ti waye lati ọjọ Aiku ti i ṣe ọjọ kẹjọ oṣu yii.

Ṣe ti oriṣiiriṣii aṣọ olowo iyebiye tawọn eeyan wọ nibi ọdun naa ni ki a sọ ni, abi tawọn ẹṣin ti wọn ṣe lẹṣọọ nibi ayẹyẹ naa?

Awọn eeyan jankan jankan to wa nibi ọdun ọhun nkọ? Kaakiri gbogbo agbaye lawọn eeyan ti wa fun ọdun Ojude Oba eyi to mi ilu Ijebu Ode titi.

Abajọ ti Gomina Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun fi sọ pe Ojude Oba ti di ọja agbaye bayii.

Nigba ti gomina n sọrọ nibi eto naa lo tun sọ pe ijọba yoo wa nnkan ṣe si gbagede ti wọn maa n lo fun ọdun naa eyi ti ko gba ero mọ.

Taa ni Balogun Kuku, bàbá olówó tó mú ẹ̀sìn Islam wọ ilẹ̀ Ijebu, tó tún bẹ̀rẹ̀ ọdún Ojude Ọba?

Aworan Balogun Kuku

Oríṣun àwòrán, BBC/Kuku Family

Odu ni Balogun Kuku nilẹ Ijẹbu, ti ọpọ eeyan si mọ ile awodamiẹnu to kọ silu Ijẹbu Ode, eyi ti ọpọ awọn elere tiata ma n lo fun ere wọn lasiko yii.

Eyi lo gbe BBC Yoruba de ilu Ijebu Ode lati foju gan ni ile Balogun Kuku, ka si mọ nipa itan igbesi aye rẹ.

BBC Yoruba ba Asiwaju fun idile Balogun Bello Kuku nilu Ijebu Ode, to tun jẹ Ọgbeni Ọja tilẹ Ijebu, Olorogun Ọmọwe Sunny Folorunso Kuku, sọrọ nipa itan aye akọni jagunjagun yii.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Olorogun Kuku, ti i se iran kẹfa si akọni jagunjagun naa ni, apetan orukọ baba nla idile awọn naa ni Bello Odueyungbo ( Ifa ko lọ sinu igbo) Bórogún.

Wọn fun un ni orukọ naa nitori bi iya rẹ ṣe bi, lo ku.

Orukọ naa wa lati ara gbolohun "iya Kú, ọmọ Kù". Apapọ rẹ lo di Kuku.

"Mama to bi baba nla wa yii ku laarin ọjọ mẹta to bi, mama mama rẹ lo tọ ọ dagba, to si kọ Kuku ni ọna okoowo.

Kuku n se okoowo karakata, to si n ta nnkan ijagun nilẹ Yoruba. Eyi lo sọ ọ di olowo tabua, milọnia, ko to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun.

Bi ogun ba wa nilẹ Yoruba, ẹni ti Kuku ba se atilẹyin fun pẹlu nnkan ijagun, ni yoo bori ogun naa, to si ni orisirisi ọta ibọn to maa n ta fun ẹni kọọkan.

Ogbeni Ọja salaye siwaju si pe idi katakara eroja ijagun yii ni Balogun Kuku ti di jagunjagun nitori o ni ibọn ati ọmọ ogun pupọ ti yoo daabo bo awọn to ba kọwọrin pẹlu rẹ.

"Bi ogun ba de, Balogun Kuku lo ma siwaju ogun fun ilẹ Ijẹbu, o lowo lọwọ, onisowo ni, to si maa n doju kọ awọn adigunjale.

Oun si ni Awujalẹ maa n lọ lati jagun bii ogun Kiriji, ohun si ni Olori awọn Parakoyi onisowo to di ẹgbẹ awọn onisowo Chambers of Commerce loni yii."