Makinde buwọ́lu ₦4.08b fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí àti dúkìá wọn nínú ìbúgbàmù Bodija

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Oṣu mejidinlogun lẹyin iṣẹlẹ ibugbamu nla to waye ni agbegbe Bodija, niluu Ibadan, awon kan lara awọn to padanu dukia ati mọlẹbi wọn ti bẹrẹ si i gba owo iranlọwọ lati ọdọ ijọba ipinlẹ Oyo.
Agbenusọ fun ẹgbẹ awọn olugbe Bodija Estate, Alufaa Muyiwa Bamgbose lo fidi iroyin naa mulẹ nibi ipade awọn akọroyin ti wọn ṣe ninu gbagede Pentorise, to wa ni Bodija niluu Ibadan.
Bamgbose ṣalaye pe ₦4.08 biliọnu ni ijọba ipinlẹ Oyo buwọlu gẹgẹ bii owo iranwọ fun awọn to lugbadi nigbati ibugbamu naa sẹlẹ.
O fi kun pe awọn ti ile wọn wa ni ẹẹdẹgbẹta mita yika ibi ti ibugbamu naa ti sẹlẹ nikan ni wọn lẹtọ si gbigba owo iranlọwọ ọhun.
Ti ẹ ko ba gbagbe, alẹ ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni ibugbamu naa waye.
Eeyan maarun lo padanu ẹmi wọn nibẹ, ti ọkọ ayọkele mẹtadinlogoji si ba a lọ.
Iṣẹlẹ naa tun sọ eeyan mejilelọgọrun di alainilelori.
Alufaa Bamgbose sọ pe o le ni milliọnu marundinlogoji naira ti awọn ẹlẹyinju aanu fi ranṣẹ lati ṣeranwọn fun awọn to lugbadi nibi iṣẹlẹ ọhun.
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ti ipinlẹ Oyo ati ti ijọba apapọ, NEMA naa tun fi awọn ohun elo idẹrun ọlọkan-o-jọkan ranṣẹ.
Bamgbose ni awọn olugbe Bodija ti fi ẹka kan lole ti yoo ṣe abojuto aabo, iwọlewọde ati amojuto agbegbe Bodija lati gbogun ti irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.















