Yorùbá Homograph: Àmì èdè ló mú káwọn ọ̀rọ̀ yìí ní ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Awọn onijo ibilẹ

Ede Yoruba rẹwa pupọ, ko si si ohun ti a ko lee fi ede naa da lara nitori pe o rọrun lati fi mu ko ba aye yi, bi aye ba se n yi.

Ninu ede Yoruba, gẹgẹ bo se wa pẹlu awọn ede miran lorilẹ aye, awọn ede kan wa ti akọsilẹ wọn jọra, amọ iro wọn ko papọ rara.

Ojulowo ọmọ Yoruba kọọkan si lo yẹ ko mọ akọsilẹ awọn gbolohun ede naa ati iro ti ikọọkan wọn ni, ka ma baa maa fi Ojo pe Aina.

Gẹgẹ baa se mọ pe ede Yoruba jẹ ede to ni ami, ami ori awọn ede kọọkan lo si n jẹ ka mọ iro wọn leti, bẹẹ si lọrọ ri pẹlu awọn ede ti akọsilẹ wọn jọ ara wọn.

Ni ọtẹ yii, iro ede ti a salaye lori rẹ ni gbolohun ogun eyi to pin si orisirisi, ti a si mu itumọ rẹ fun yin ni ẹyọ kọọkan.

Awọn ede Yoruba ti iro wọn jọ ara wọn amọ ti akọsilẹ wọn yatọ:

OGÚN:

Ogún ni awọn oloyinbo n pe ni Twenty, ti ami rẹ si jẹ re mi.

Ogún jẹ ami isiro, ti onka rẹ bẹrẹ lati ookan de ogun, eyi si ni ara onka ni ede Yoruba.

ÒGÚN:

Ògún (do mi) ni orukọ ti wọn fun orisa kan nilẹ Yoruba.

Awọn eeyan to n bọ orisa ogun pọ aja, si ni eroja kan gboogi ti wọn fi n bọ

Awọn eeyan to jẹ olorisa Ogun lo maa n jẹ Ogungbemi, Ogunlana. Ogunrinu ati bẹẹ bẹẹ lọ

OGÚN:

Ogún yii naa tun tumọ si dukia tabi imọ ti a ri gba lati ọwọ ẹnikan.

Ami ori rẹ jọ ti onka ogún amọ itumọ rẹ yatọ pupọ.

A saba maa n jẹ ogun awọn eeyan to jẹ ẹjẹ wa bii obi, ẹgbọn tabi ibatan wa, ti a si maa n jẹ ogun imọ lati ọdọ olukọ tabi awọn asaaju ẹsin wa.

ÒGÙN:

Ògùn jẹ orukọ odo kan nilẹ Yoruba, o san lati ipinlẹ Ọyọ lọ si ilu Abẹokuta.

Orukọ odo yii si ni wọn fi n pe ipinlẹ kan nilẹ Yoruba taa mọ si ipinlẹ Ogun, eyi to sunmọ ilu Eko pupọ.

Àkọlé fídíò, Àrìnfẹsẹ̀sí - Ìbéèrè ni a bèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn, ika òṣì ni wọ́n ń ta dànù

OGUN:

Ogun yii jẹ orukọ ti wọn fun aawọ ati iporogan to ba n waye laarin ilu meji tabi ju bẹẹ lọ.

Ogun yii, (ti ami rẹ jẹ re re) si tun tumọ si rogbodiyan, pakaleke ati aisi alaafia to peye.

Ogun buru jai, to si maa n ba ọpọ dukia jẹ, tabi mu ẹmi eeyan lọ.