Yoruba language: Báwo ni o ṣe gbọ́ èdè Yorùbá tó?

Aworan idanwo
Àkọlé àwòrán, Ajọ iṣọkan awọn orilẹede lo ya ọjọ naa s'ọtọ lati ṣe igbelarugẹ fun oniruuru ede

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu keji ,ọdọdun ni ayajọ ọjọede abinibi lagbaye.

Ajọ iṣọkan awọn orilẹede lo ya ọjọ naa s'ọtọ lati ṣe igbelarugẹ fun oniruuru ede to wa l'agbaye. Kini ipa ti gbigbọ ede ju ẹyọkan lọ n ko lori ede abinibi?

Gẹgẹ bi ọmọ ilẹ kaarọ, o jiire, bawo ni imọ rẹ ṣe to nipa ede rẹ.

Akọle ajọdun ti ọdun yii ni: "Ọjọ awọn ti wọn gbọ ede ju oyọkan lọ."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Idanwo kan ni yii.

Ẹ tẹẹ wo, ki ẹ gbiyanju idanwo naa wo ki ẹ le mọ boya ẹ dangajia ninu ede Yoruba tabi o ku diẹ ka'ato.

Àkọlé fídíò, Mike Ifabunmi: Òrìṣà ló gbè wà jù ni Brazil

Bi ẹ o ṣe ṣe idanwo naa niyii:

To ba jẹ wi pe foonu l'ẹ n lo, ẹ tẹ Yoruba to wa ni apa alaafia, lẹyin naa ki ẹ tẹ itumo rẹ ni ede Gẹẹsi ni apa ọtun.

Àkọlé fídíò, Kini Yoruba "international passport"?

Lori kọmputa, ẹ kọkọ tẹ Yoruba ni apa alaafia ki ẹ to tẹ itumọ rẹ ni apa ọtun.