Arsenal rántí "Invincibles," ó pé ọdún mẹ́rìndínlógún tí Arsenal gba ife Premier League

Arsenal

Oríṣun àwòrán, @GilbertoSilva

Àkọlé àwòrán, Ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlaadọta ni Arsenal gba lai padanu ọkankan ninu wọn.

O ti pe ọdun mẹrindinlogun bayii ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal gba ife ẹyẹ Premier League lai fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan ni saa bọọlu ọdun 2003/2004.

Nigba naa si ni Arsenal gba ife ẹyẹ idije Premier League kẹyin.

Arsene Wenger ni akọnimọọgba ikọ Arsenal nigba naa.

Arsenal

Oríṣun àwòrán, @AFTVMedia

Patrick Vieira ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu ikọ naa ninu eyi tawọn agbaọjẹ agbabọọlu bi Thierry Henry, Robert Pires, Dennis Beckamp, Sol Campbell, Arshley Cole ati Kanu Nwankwo wa.

Ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlaadọta ni Arsenal gba lai padanu ọkankan ninu wọn.

Lori ifẹsẹwọnsẹ aadọta ni wọn de ki ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United to fẹyin wọn gbolẹ ti wọn si da wọn duro.

Arsenal padà sórí pápá, Premier League lè bẹ̀rẹ́ padà lóṣù kẹfa

Awon ọmọ agbabọọlu Arsenal

Oríṣun àwòrán, Mikel

Àkọlé àwòrán, Coronavirus: Arsenal padà sórí pápá, Premier League lè bẹ̀rẹ́ padà lóṣù kẹfa

O ṣeeṣe ki idije Premier League bẹrẹ pada laipẹ, lẹyin ti o ti wa ni idaduro lati inu oṣu kẹta nitori ajakalẹ aarun coronavirus.

Ajọ UEFA ti fawọn alaṣẹ idije naa atawọn idije liigi bọọlu mii kaakiri ilẹ Yuropu di ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu karun un lati ṣeto igba ti wọn fẹ bẹrẹ saa bọọlu yii pada.

Àkọlé fídíò, Kini Yoruba "international passport"?

Awọn alaṣẹ Premier League fẹ bẹrẹ liigi ọhun pada lọjọ kẹjọ oṣu kẹfa, eyi ti wọn fẹ ko pari ninu oṣu keje ọdun yii.Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Tottenham, West Ham ati Brighton ti ṣi papa iṣere wọn fawọn agbabọọlu wọ lati ma ṣe igbaradi ọlọdanni.