Diẹ lára àwọn jẹsí tó mi ìgboro tìtì ní agbo bọ́ọ́lù

Asiko yii lọ́dọọdún ni awọn ẹgbẹ́ agbabọọlu maa n mura lati safihan àwọn aṣọ agbabọọlu wọn fun saa to n bọ.O si seese ki o pẹ lasiko yii nitori coronavirus.
Nitori naa, ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo diẹ lara awọn aṣọ to ti logba ri. Nigeria (2018)Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eniyan nigba ti ẹgbẹ́ agbabọọlu orilẹ-ede Naijiria kede jẹsi tuntun fun idije ife agbaye lọdun 2018.
Ọpọlọpọ wakati ni awọn ololufẹ Super Eagles fi to ni ile itaja Nike nilu London lati ra jẹsi naa.
Miliọnu mẹta eniyan si lo ti sanwo silẹ ki aṣọ naa to jade fun tita.

Cameroon (2002)
Ko ṣẹlẹ ri ni Cameroon fi ọrọ jẹsi rẹ to gbe sita lọdun 2002.Aṣọ naa jẹ eyi ti ko ni apá. Gbogbo eniyan ni ko si f'oju ire wo o.
Koda ajọ FIFA fi ofin de wiwọ rẹ ni idije ife agbaye ọdun 2002 to waye ni Japan, nitori pe "ki i ṣe ṣaati, bikose awọtẹlẹ".
Celtic (1967)

Ẹgbẹ́ agbabọọlu Celtic 'Lisbon Lions' lọ wọ gbajugbaja jẹsi naa, lasiko ti wọn fi kọ orúkọ wọn sinu iwe ìtàn nipa lilu ẹgbẹ́ agbabọọlu Inter Milan pẹlu ami ayo meji sẹyọkan
Eyi to si sọ wọn di ẹgbẹ́ agbabọọlu Britain akọkọ to gba ife European Cup.
Brazil (1970)

Lootọ lo jọ ọpọ jẹsi ti Brazil ti maa n lo, sugbọn eyi tun peleke.
Ohun ni ẹgbẹ́ agbabọọlu naa wọ lọdun 1970 ti wọn gba ife idije agbaye.
Bakan naa lo jẹ pe ohun ni ogbontagi agbabọọlu, Pele, wọ gbẹyin ko to o fẹyinti lẹ́nu bọọlu gbigba.
Chelsea (1970)Ki aṣọ o ma ba a tako ara wọn, ni ẹgbẹ́ agbabọọlu Chelsea ṣe pa ààwọ̀ ibọsẹ ati awọn nkan miran to jẹ aawọ funfun, si ààwọ̀ ofeefe (yellow),ni asiko ifẹsẹwọnsẹ asekagba pẹlu Leeds.Ọdun naa gan-an si ni igba akọkọ ti wọn gba ife ẹyẹ FA Cup.Lati saami aadọta ọdun àṣeyọrí náà, Chelsea wọ jẹsi to jọ ọ idije kan pẹlu Nottingham Forest lọdun 2020.

Ajax (1971)

Isẹ ara rẹ ko pọ rara, sugbọn o rẹwa pupọ.
Inu aṣọ yii ni Ajax wa to fi na Panathinaikos ni Wembley pẹlu ami meji soodo.
To si tun jẹ igba akọkọ ti wọn bori ninu idije European Cup final.

Denmark (1986)Ara ni ẹgbẹ́ agbabọọlu orilẹ-ede Denmark fi aṣọ wọn da ni igba akọkọ ti wọn kopa ninu idije ife agbaye.
Bo tilej jẹ pe 'jẹsi' naa fa àríyànjiyàn nigba naa, Southampton ati Coventry wa lara awọn ẹgbẹ́ agbabọọlu to pada wọ nkan to jọ aṣọ naa.
Netherlands (1988)

Aṣọ naa jẹ ọkan lara eyi ti awọn eniyan n wárí fún ni gbogbo igba.
Aṣọ naa dùn ún wo lọrun wọn pẹlu bi wọn ṣe bori ninu idije European Championship fun igba akọkọ.

Manchester United (1990)
Lootọ ni ẹgbẹ́ agbabọọlu Man U ti maa n wọ aṣọ ti ko ṣe fọwọ́rọsẹyin, sugbọn eyi tun peleke.
Isẹ̀ ọnà 'Aztec-style' ti wọn se si ara aṣọ naa mu ko rẹwa pupọ. Àwọn ololufẹ wọn si gba ti ẹ titi di òní.
Arsenal (1991)

Aṣọ aláwọ̀ ofeefe yii jẹ ọkan lara awọn aṣọ manigbagbe ni nkan bi ọdun 1990.
Ó si gbajumọ lasiko náà.















