Ondo state money: Ìjọba Ondo ṣàwárí N4.3bílíọ́nù tó farapamọ́ fọ́dún mẹ́wàá

Oríṣun àwòrán, Aketi
Ijọba ipinlẹ Ondo ni awọn ti ṣawari owo kan to le ni biliọnu mẹrin naira to pamọ sinu aṣuwọn ifowopamọsi idakọnkọ kan fun odindi ọdun mẹwaa.
Iroyin lawọn iwe iroyin abẹle n sọ pe lasiko iṣejọba oloogbe Oluṣẹgun Agagu ni wọn ti fi owo naa pamọ si aṣuwọn banki igbalode kan.
Ninu atẹjade kan, kọmiṣọna feto iroyin ni ipinlẹ Ondo, Donald Ojogo ni kọmiṣọna feto iṣuna lo ṣawari owo naa nibi to farasin si.
O ni ni kete ti kọmiṣọna feto iṣuna kansẹ ba owo naa lo fi to ijọba leti ti wọn si ti ṣe akọsilẹ rẹ.
O ni ko si ọrọ sisan owo fun agbaṣẹṣe kankan lori owo naa nitori ko si agbaṣẹṣe ti wọn gba fun eto gbigba owo naa pada.
Ondo Coronavirus: Akeredolu ní igbó ìpínlẹ̀ Ondo ló dára jùlọ lágbaye tí kò sì yẹ kó máa ṣòfò

Oríṣun àwòrán, other
Gomina Ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu tí ṣàlàyé nípa opo anfaani tó wa nídìí ọ̀gbìn igbó.Akeredolu, lásìkò to ń kopa lórí eto kan lórí ìkànnì BBC Yoruba taa pé ní 'Sọ tiẹ̀' ni opo owo wa nídìí lílo èròjà igbó fún eto oko-owo.Akeredolu ni "owó wá nibẹ, èwe ọlá sì lawa ń pè igbó. A fẹ́ wá ibi ti wọn yóò ti máa gbìn igbó, ti àjò to ń gbógun ti oogun oloro yóò sì mọ nípa rẹ, a máa sọ ibẹ tọsan toru, a gba àṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí yóò si dohùn, torí òpó anfaani lo wá nìdí rẹ."
- Ọlọ́run ló kọọ pé àwọn ọmọ mi yóò ṣiṣẹ tíátà, èmi kọ lo kàn-án nípa fún wọn - Ọga Bello
- Àwọn tó jí kọmíṣọ́nnà gbé l'Ekiti ń bèèrè fún N30 mílìọnù kí wọ́n tó le è tú u sílẹ̀
- Mo ṣetán láti ta ilé tí mo ń gbé, kí n le rí àwọn ìbejì mi padà - Akeugbagold
- Olórí ẹ̀ṣọ́ Adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Bola Ahmed Tinubu ti kú lẹ́yìn tó lùgbàdì àrùn Coronavirus
Nígbà tó ń ṣàlàyé lórí bí ẹ̀ka aladani àti àwọn ileeṣẹ ṣe leè kopa nìdí gbingbin èwe ọlá náà torí owó pupọ tó wá nídìí rẹ, Akeredolu ni àwọn gbọdọ gba àṣẹ na, láti rí dájú pé wọn kò loo nílò kulo. " Ọ̀pọ̀ biliọnu náírà ni idokowo náà yóò gbà, gbogbo agbaye sì ti ní èwe igbó tí wọn gbìn ni Ìpínlẹ̀ Ondo lo dára julọ lagbaye, kò sì yẹ ká máa sún wọn ni iná." Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí tó fi ń fi arákùnrin si ìbẹ̀rẹ̀ orúkọ rẹ dípò ọlọ́lá jùlo, Akeredolu ni orúkọ tí bàbá òun ń pè òun láti kékeré ni òun padà sí, òun kò si fẹ́ òye kankan.Akeredolu tún ṣàlàyé pé, òun fẹ́ràn ìpínlẹ̀ òun àti ìlú Ọwọ, tíì ṣe ìlú abinibi oun, ní òun ṣe dù ipò gomina, àwọn ará ìlú Ọwọ sì lo wà bẹ òun n'ilu Ibadan, láti wá dù ipò náà."Isẹ asofin tí mo ń ṣe tó mi, àmọ́ ìlú ko le è pé mi, kí n má jẹ́, ní mo ṣe dù ipo gómìnà, mo sì gbà pé Ọlọ́run fẹ ki n se ni".O fikùn pé, ara àwọn àfojúsùn òun gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ni lati mú amugbooro bá eto ọrọ aje nipinlẹ Ondo, èyí tó tọ́ tí fò sókè ga láti mílíọ̀nù lọ́nà eedegberin náírà si biliọnu méjì náírà báyìí."A ti pese ọpọ àwọn ohun èlò amayedẹrun si ìpínlẹ̀ Ondo, tá si tún ṣe àtúnṣe sì àwọn ilé ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ wá, a ti ṣe ọpọ nkan tó ṣe mú yangàn dáadáa, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run."

Oríṣun àwòrán, Aketi
Akeredolu, nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí tí Ìpínlẹ̀ Ondo ṣe fà sẹ́yìn nínú èsi idanwo asejade làwọn ilé ẹ̀kọ́ gírámà, ó ṣàlàyé pé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nipinlẹ náà ń ṣe daada àmọ́ ó ni bí ọmọ ṣe pọ sì láti jókòó ṣe idanwo asejade ilé ẹ̀kọ́ gírámà, ní wọ́n se n tó àṣeyọrí ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan sí.Lórí ajakalẹ àrùn Coronavirus, Akeredolu ni àjálù ńlá ni àrùn náà, ìpínlẹ̀ Ondo sì ti dangajia nítorí àwọn tí ni oriri tẹ́lẹ̀ nípa itọju ibà lassa, tó ti kọkọ bá wọn fínra."A ti pàṣẹ kí àwọn ọmọ má ṣe lọ sí ilé ẹ̀kọ́ nítorí Coronavirus, ó sì ti ṣe ìpalára fún ọrọ aje wá, a sì ti ń fún àwọn èèyàn ní èròjà oúnjẹ, láti mú kí ayé dẹrun fún wọn"O ṣàlàyé pé, àwọn ọlọ́pàá méjì tí wọn wá láti Eko sì Ondo lo mú kí owoja àrùn Covid-19 lè sì ni Ondo, tí àwọn fi ní alárùn mẹ́jọ, tí mẹta sì yí lọ sílè nínú wọn.

Oríṣun àwòrán, Aketi
"Bí àwọn ènìyàn ṣe ń wọ Ondo kò yẹ wá, a ti bá àwọn ọlọ́pàá ṣe ipade pé àwọn ènìyàn wọn ń gba owó láti jẹ ki awọn eniyan wọlé, tí wọn si ti ṣèlérí láti ja ọrọ náà kunra si, ọ̀rọ̀ tí aarẹ Buhari sì sọ lọ́jọ́ Aje sì ti mú kó nira bayii láti rinrin àjò láti ìlú kan si òmíràn." Gbógbo ohun tí aarẹ sọ ni àwa ń ṣe. Kódà ó ti di dandan láti lo ibomu, tá si ti ń rán ibomu lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ la tún yàgò fún ara wa pẹ̀lú ṣíṣe isede." Àmọ́ àwọn èèyàn wa kò gbọ́ràn pé, kí wọ́n mase lọ sí ọjà mọ. Sísun mọ́ra pọ leè ṣe àkóbá, ó sì dáa kí wọ́n máa patẹ síwájú ilé wọn, dípò lílọ sì ọjà.Nígbà tó ṣàlàyé ipò tí irẹsi tí ìjọba àpapọ̀ pín fun ìpínlẹ̀ Ondo wa, gomina ní ọrọ oselu kò sì níbi ọrọ Irẹsi náà rara."Iresi tá gba, a rí díẹ̀ nínú rẹ tí kò dáa, àmọ́ kò pọ rárá, wọn ní ká dá èyí tó ti bajẹ padà, ki wọn parọ́ rẹ fún wa. Kò si bí a ṣe máa gba tirela Irẹsi mẹta, tí a kò ní rí èyí tó ti bajẹ nibẹ nítorí wọn tí kò àwọn Irẹsi náà kalẹ, ọjọ́ tí pẹ.
Lórí ìpèsè ohun ìdẹ̀rùn fún aráàlú lásìkò igbele Coronavirus, Akeredolu ni òun kò ní kí ẹnikẹ́ni mase tá ọjà, àwọn wọn kan ni kí wọ́n má sú pọ ni.Ó ní awon onimoto tí kò leè ṣíṣe nìkan ni ọ̀rọ̀ yìí kan, táwọn sì ń ṣàn owó oṣù fún àwọn òṣìṣẹ́ ọba, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń ṣe ìpèsè oúnjẹ fún àwọn tí kò rí oúnjẹ jẹ.Nípa ṣíṣe ayẹwo fáwọn alárùn Coronavirus àti ẹ̀sùn pé àwọn gómìnà ń fi àrùn náà pá owó ni, Akeredolu ni ìjọba àpapọ̀ kò tii fún ẹnikẹ́ni lowo, bẹ́ẹ̀ sì ni banki agbaye lọ fẹ́ yà àwọn lowo, kii sì ṣe ọ̀fẹ́, àwọn yóò san owó náà padà.Gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ to ni epo robi àti eto eto idokowo, gomina ni ipo karùn-ún ni ìpínlẹ̀ Ondo wá, isẹ ribiribi tí àwọn sí ń gbé ṣe lo ń fà àwọn olokoowo wá sí Ondo.Lórí ìpèsè àwọn ohun èlò amayedẹrun si agbegbe Ikalẹ, gomina Akeredolu wa rọ awon ọmọ bibi agbegbe naa pé kí wọn fi ọkàn balẹ, nítorí wọ́n kò ní pẹ máa wa ohun àlùmọ́ọ́nì bítúmẹ́nì tó sodo sì agbegbe Ikalẹ, tí ibùdó ojú omi yóò sì tẹdo sí àgbègbè náà pẹlu.Lórí ọjà tó gbé owó lórí lásìkò Coronavirus yìí, gomina woye pe, "àwa ara ilu ko feran ara wa, ìdí di nìyí tí wón se n gbe owo lè èròjà gbogbo, ìwọ̀nba sì ni ìjọba leè ṣe lórí rẹ." Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí igbesẹ riro àwọn obìnrin lágbára àti ìwòsàn àrùn jẹjẹrẹ, Akeredolu gbé oriyin fun aya rẹ, Betty, fún isẹ takuntakun tó ń ṣe, pẹ̀lú àfikún pe ó tún ń kọ àwọn ọmọdébìnrin ni onírúurú isẹ ọwọ, kí wọ́n leè dá dúró fúnra wọn.Lórí ṣíṣe ṣáá kejì lórí aleefa, Akeredolu ni laipẹ ni ìpolongo ibo yóò bẹ̀rẹ̀, tí Ọlọ́run bá sì ní òun yóò ṣe ṣáá kejì, kò sì wàhálà, ohun tí Ọlọ́run yóò ṣe, ni òun ń dúró de.O wa pàrọwà sáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ondo láti fọkàn balẹ torí ohun rere sí ń bọ̀ nipinlẹ náà, tó sì rọ wọn láti jẹ ki itẹsiwaju wá nínú iṣejọba.













