Messis vs Ronaldo: Jurgen Klopp ní àràmọ̀ndà agbábọ́ọ̀lù tó ń jẹ Messi, ó ju Ronaldo lọ lórí pápá

Lionel Messi ati Cristiano Ronaldo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp naa ti da si arayinjiyan "ta lo dara ju" laarin Lionel Messi ati Cristiano Ronaldo.Ko tii si opin si ariyanjuyan yii lẹyin tawọn mejeeji ti tayọ ju awọn akẹgbẹ wọn lagbaaye lọ fun bi ọdun mẹwaa sẹyin bayii.Ronaldo ati Messi jọ dabira ninu idije La Liga nibi ti wọn ti jọ gba ami ẹyẹ loriṣiiriṣii fun ẹgbẹ agbabọọlu wọn, Real Madrid ati Barcelona ki Ronaldo to darapọ ikọ Juventus.