Ọmọ òṣèré tíátà, Saidi Balogun, Zainab jáde láyé

Oríṣun àwòrán, saidibalogun/INSTAGRAM
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Saidi Balogun ti pàdánù ọmọ rẹ̀, Zainab.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹwàá ni Saidi Balogun fi àtẹ̀jáde kan sórí ìkànnì Instagram rẹ̀ láti fi kéde ikú ọmọ náà.
Àwòrán àbẹ́là tó ń jó àti àwọn òdòdó sójú òpó náà.
Bákan náà ló fi àwọn àwòrán sábẹ́ rẹ̀ láti ṣàfihàn pé ọkàn òun gbọgbẹ́.
Lábẹ́ àwòrán náà ni àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ bíi Allwell Ademola, Adeniyi Johnson, Kunle Afod, Wunmi Ajiboye, Funke Etti, Woli Àgbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ti ń ki pé kí ó mú ọkàn.
Ọ̀pọ̀ wọn ló gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tẹ́ ọmọ náà sí afẹ́fẹ́ rere àti pé kó fún bàbá rẹ̀ ní ọkàn láti gba àdánù náà.
Àwọn òṣèré bíi Fathia Williams, Allwell Ademola ló tún ti gbé àwòrán irú èyí tí Saidi Balogun gbé sójú òpó rẹ̀ sójú òpó Instagram wọn náà.
Allwell Ademola ní òun gbàdúrà pé kó jẹ́ pé ojú àlá ni òun wà.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1

End of Instagram post, 2