Ẹ̀yin tí pásítọ̀ yín kò bá bèèrè fún ìdámẹ́wàá, ẹ máa dá ọrẹ àmọ́... - Adeboye

Oríṣun àwòrán, pastoreaadeboyeofficial/Instagram
Pasitọ agba ijọ Redeemed Christain Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye, ẹni ti ọpọ mọ si Daddy G.O tun ti sọrọ lori awuyewuye to n lọ lọwọ lori sisan idamẹwaa ni ṣọọṣi.
Pasitọ Adeboye to sọrọ yii nibi ipejọpọ ijọ RCCG kan sọ wi pe ẹbẹ loun n bẹ gbogbo kristẹni pe ki wọn jẹ ki gbogbo ariyanjiyan to n lọ lori ọrọ idamẹwaa wa sopin.
Pasitọ Adeboye sọ pe ‘’mo mọ wi pe ọpọ eeyan lo loye ju mi lọ, bakan naa ni mọ pe awọn pasitọ kan mọ ju mi lọ.
Ṣugbọn ẹ jẹ ka ṣe e bayii, papaa julọ ẹyin ti ẹ jẹ ọmọ ijọ, ti pasitọ yin ba sọ pe oun o gba idamẹwaa, ẹ ma tori iyẹn fi ṣọọṣi silẹ o.
Ti pasitọ yin ba sọ pe ọrẹ nikan loun fẹ, ẹ fun un ni ọrẹ to n fẹ.
Amọ, ti ọkan rẹ ba sọ fun ọ wi pe o ni lati fun Ọlọrun ni idamẹwaa, wa ṣọọṣi kan ti ko jina si ọ nibi ti pasitọ ti n gba idamẹwaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ti iru pasitọ naa ba sọ pe oun maa n gba idamẹwaa, ijọ si maa n lo o fun ogo Ọlọrun, gbiyanju lati fun iru pasitọ bẹẹ ni idamẹwaa rẹ.’’
Baba Adeboye ni ṣiṣẹ eleyii ‘’ko ni jẹ ki o ba pasitọ rẹ ja, ko si tun ni jẹ ki o ba Ọlọrun ja pẹlu.
Ti o ba si ṣe eleyii, ẹri ọkan rẹ yoo da ọ lare, ẹbẹ yii ni mo bẹ gbogbo eeyan.
Ṣé lóòtọ́ ni Pásítọ̀ àgbà ìjọ RCCG, Enoch Adeboye túúbá lórí ọ̀rọ̀ tó sọ pé ẹni tí kò san ìdámẹ́wàá kò lè dé ọ̀run?

Oríṣun àwòrán, Pastor E.A Adeboye/X
Pasitọ agba fun ijọ Redeemed Christain Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye, ẹni ti ọpọ mọ si Daddy G.O ti tọrọ aforijin lọwọ awọn olujọsin ijọ naa atawọn ọmọlẹyin Kristi kaakiri agbaye nipa ọrọ kan to sọ sita lori sisan owo ida mẹwaa fun ile ijọsin.
Nigba to n sọrọ nibi apero awọn ọdọ ati agbalagba kan ni ile ijọsin naa, Pasitọ Adeboye tọrọ aforijin, to si ni oun se asise nipa ọrọ yii ni pe, “Onibagbọ ti kii ba n san owo ida mẹwaa rẹ, ko le ri ijọba ọọrun wọ." lawọn asiko kan sẹyin.
Ọrọ yii fa ọpọlọpọ awuyewuye nigba to sọ ọrọ naa lawọn akoko diẹ sẹyin. Bi ọpọ ṣe n sọ pe lootọ ni o sọ lawọn kan n ta ko ọrọ yii nigba naa.
Amọṣa bayii o, ilumọọka iranṣẹ ọlọrun naa ti ni ọrọ ti oun sọ naa ko ri bẹẹ nitori naa ki awọn eeyan o darijin oun ni o.
“Mo tọrọ aforijin fun ọrọ yii pe ti ẹ ko ba san owo ida mẹwaa, ẹ ko le wọ ijọba ọrun. Eyi ko bojumu, ko si ninu Bibeli,”
O ni oun ti Bibeli sọ ni pe ki a gbe igbeaye alaafia laarin ara wa ki a le ri Ọlọrun Ọba.
Bawo lọrọ ṣe bẹrẹ gan an?

Oríṣun àwòrán, RCCG
Ọdun 2020 ni Adeboye sọ ọrọ yii sita nigba to n se waasu kan pe sisan owo ida mẹwaa jẹ ọkan ninu ohun ti yoo mu onigbagbọ wọ ijọba ọrun.
“Ẹnikẹni ti ko ba san owo ida mẹwaa, ko le ri ijọba ọrun wọ,” Adeboye sọ nigba naa.
Sugbọn ọrọ yii pada nibi apero kan to wa ninu oṣu kẹwaa ọdun 2024 nigba to n ba awọn ọdọ sọrọ.
Adeboye ni ọpọ awọn eeyan lo n fun Ọlọrun ni ida mẹwaa tipatipa ati ọpẹ tipatipa.
O tẹsiwaju pe oun yoo bọ sita lati ba awọn eeyan sọrọ lori mọrọ ida mẹwaa nigba ti Ọlọrun ba ti fun oun ni aṣẹ lori ọrọ naa.
Bakan naa, o ni o seese ki eeyan se n ohun to tọ ati oun to kuna nigba kan naa.
Lati tan imọlẹ si ọrọ naa, Adeboye ni o kuna lati ni ki awọn olugbagbọ ma san ida mẹwaa nigba ti o yẹ ki wọn ma san ida ogun, ọgbọn, ogoji.
“Ida mẹwaa wa fun awọn to sẹsẹ bẹrẹ. Mo gbagbọ pe ohun yoo fun mi ni anfani lati ṣalaye ni ẹkunrẹrẹ.
O ni fun awọn eeyan to fẹ wa loke, ẹnikẹni to fẹ ma paṣẹ owo, ẹni yoo san ju ida mẹwaa lọ, “O kuna fun mi lati sọ fun yin pe ki ẹ san ida mẹwaa.”
'N ko sọ fun awọn Kristẹni pe ki wọn maa san ida mẹwaa'

Oríṣun àwòrán, RCCG
Pasitọ agba, Enoch Adeboye ni oun ko fi igba kankan sọ fun awọn kristẹni pe ki wọn san ida mẹwaa.
O ni otitọ ni pe oun tọrọ aforijin lori ọrọ ti oun sọ nipa ida mẹwaa, ti oun si gbagbọ pe ọpọ eeyan si oun gbọ.
Sugbọn ohun iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti oun bẹrẹ si ni ma ri iroyin ofege to n lọ kaakiri nipa sisan owo ida mẹwaa.
“Ọrọ yii ni agbara, ti mo si piinu lati tọrọ aforijin nipa ọrọ ti mo ti sọ ti ko bojumu.
“Laarin wakati kan, wọn ti n gbe kiri ori ayelujara pe mo sọ fun awọn ọmọ ẹlẹsin Kristẹni pe ki wọn ma san ida mẹwaa mọ,” Adeboye ṣalaye.
O tẹsiwaju pe oun gba awọn onigbagbọ ni imọran pe ki wọn fi ohun to ju ida mẹwaa lọ silẹ, to si se apẹẹrẹ ohun to ba pade ni ile ijọsin Kenneth Hagin nibi ti ọkunrin kan ti sọ bi ayipada se de ba lẹyin to sun ida mẹwaa rẹ si ida aadọrun.
“Loni, mo ti n sumọ fifi ida aadọrun silẹ. Ti mo si jina si ida mẹwaa. Ohun ti mo n sọ n sọ ni pe o lodi pe ki eeyan jọwọ ara silẹ si ida mẹwaa nigba ti Ọlọrun si le fa lori soke.
“Ninu gbogbo ohun ti mo sọ, ohun kan pato ti wọn gbe sori ayelujara ni pe Adeboye tọrọ aforijin, to si sọ pe ki awọn eeyan ma san ida mẹwaa mọ.















