Èèyàn 78 jáde láyé lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi dojúdé

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Ken Mungai & Danai Nesta Kupemba
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Ko din ni eeyan mejidinlọgọrin to jade laye lẹyin ti ọkọ oju omi kan doj de sinu odo Kivi lorilẹede Democratic Republic of Congo.
Iroyin ni nnkan bii iṣẹju perete lo ku ki ọkọ oju omi naa de ibi to n lọ ko to dojude.
Ilu Minova, to wa lagbegbe ila oorun Kivu ni ọkọ naa naa ti n bọ ko to danu lẹba eti omi ni Goma lọjọbọ.
Gomina ipinlẹ ti iṣẹlẹ naa ti waye, Jean Jacques Purisi, sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe yoo ṣoro lati mọ iye eeyan ti ọrọ naa kan ni pato.
O ni “o kere tan, yoo to ọjọ mẹta ki a to mọ iye eeyan ti iṣẹlẹ naa kan ni pato, nitori kii ṣe gbogbo oku naa ni wọn ti ri.
Ajafẹtọ ọmọniyan kan, Aaron Ashron ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun BBC pe oun ri ọpọ oku ti wọn gbe jade ninu odo ati pe wọn ti ko awọn farapa lọ sile iwosan.
Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe ọmọde meji lo ku lẹyin ti wọn ko wọn dele iwosan tan.
Nigba to n sọrọ lori ibusun to ti n gbatọju lọwọ, ẹni ọdun mọkanlelaadọta kan to moribọ nibẹ, Alfani Burolo Byamungu sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe odo naa ko jọ eyii ti yoo ru lati da ọkọ nu.
O fikun pe “mo ri awọn eeyan to n ri, ọpọ ni omi bo ori wọn mọlẹ. Mo ri ọmọde atawọ obinrin ti wọn n ri sinu omi, diẹ lo ku ki emi funra mi gan ri ṣugbọn Ọlọrun lo ran mi lọwọ.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ leti odo naa to kopa ninu didoola awọn eeyan, Bahati Selemani sọ pe “a ri ọkọ oju omi to fẹ danu, a tun ri pe afẹfẹ ori omi naa pọ, bẹẹ ero to wa ninu ọkọ ọhun kọja iye to yẹ ko jẹ.
O sọ fun AFP pe “bi ọkọ naa ṣe n ri lẹgbẹ kan ni awọn to wa loke bẹrẹ si n bẹ sinu omi, lẹyin naa ni ọkọ ọhun danu patapata.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti ọkọ oju omi yoo danu ni DR Congo latari pe ero inu ọkọ maa npọ ju iye to yẹ ki ọkọ ko lọ.












