Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà yọ ọmọogun ojúomi tí wọ́n tìmọ́lé fọ́dún mẹ́fà, àlàyé tí wọ́n ṣe rèé

Oríṣun àwòrán, BEREKETE FAMILY
Ileeṣẹ eto abo lorilẹede Naijiria ti yọ ọmọogun oju omi kan ti orukọ rẹ n jẹ Seaman Haruna Abbas kuro niṣẹ.
Ohun ti wọn ka silẹ gẹgẹbi idi ti wọn fi gbe igbesẹ yii ni pe o tapa si aṣẹ ologun.
Alukoro fun ileeṣẹ ọmọogun alaabo Naijiria, Ọgagun Tukur Gusau ṣe alaye pe wọn yọ Abbas Haruna nipo lẹyin ti ọgagun agba fun ileeṣẹ ọmọogun oju omi Naijiria, Emmanuel Ogalla buwọlu idajọ ileeṣẹ ologun ti olu ileeṣẹ ọmọogun alaabo gbe kalẹ lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹsan an ọdun 2024.
Haruna Abbas to jẹ ọmọogun ojuomi ileeṣẹ ologun Naijiria ti wa ni atimọle lati nnkan bi ọdun mẹfa nitori aṣẹ ọgagun oju omi kan; amọṣa bayii wọn ti tu u silẹ.
Hussaina, to jẹ iyawo Haruna ati ọkọ rẹ di gbajugbaju loju opo iroyin gbogbo ni Naijiria lẹyin ti oju wọn han ni oju opo ileeṣẹ gbohungbaroye kan ti wọn n pe ni Berekete family ni ilu Abuja laarin oṣu kẹsan an ọdun 2024.
Hussaini Iliya ke gbajare lọ si oju opo eto naa, nibi to ti ṣe alaye lẹkunrẹrẹ bi wọn ṣe fi ipa gbe ọkọ rẹ ati pe wọn ti yọọ niṣẹ.
Tomijetomije lo fi sọ ohun gbogbo ti oju oun ati ọkọ rẹ ri to bẹẹ ti ọkọ rẹ pẹlu ni lati dide diimu pẹkipẹki to si n bẹ ẹ pe ko maa binu.
“Ṣebi mo ti sọ fun ẹ pe ki o maa binu? O ti maa n sunkun ju!” ni ọrọ ti Haruna sọ fun iyawo rẹ.
O sọ pe lati ọdun 2018 ni ileeṣẹ ologun ti fi ọkọ oun si atimọle lai si idi kan pato.
Amọṣa Ọgagun Gusau ṣalaye pe arakunrin naa foju ba ile ẹjọ ologun lori ẹsun mẹta to da lori titapa si ofin, titako awọn to fẹ fi si atimọle ati biba dukia ileeṣẹ ologun jẹ.
O ni awọn ẹsun wọnyii tako abala iwe ofin ileeṣẹ ologun Naijiria.
Bakan naa lo sọ pe Haruna gba pe oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun nibi igbẹjọ ologun naa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọmọogun alaabo naa tun ṣalaye siwaju sii pe ile ẹjọ ologun naa rii pe o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ni wọn fi gba iṣẹ lọwọ rẹ bẹrẹ lati ọjọ keje oṣu keji ọdun 2023.












