Bí òyìnbó ṣe tàn wá gbé òògùn olóró - Àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi ṣàlàyé

Àkọlé fídíò, Bí òyìnbó ṣe tàn wá gbé òògùn olóró - Àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi ṣàlàyé
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Bii igba ti ala ọkunrin kan, Daniel Guerra, ọmọ orilẹede Brazil to ti n wa ọna lati di awakọ oju omi tipẹ, wa si imuṣẹ lẹsẹkẹsẹ ni ọrọ ri, nigba ti oyinbo ọlọkọ oju omi kan n wa eeyan meji ti yoo ba a wa ọkọ tiẹ loju agbami Atlantic, ọkan ninu awọn irinajo to lagbara ju lagbami aye.

Oyinbo to ni ọkọ oju omi yii ko ni i sanwo oṣu fun wọn fun iṣẹ naa, gẹgẹ bo ṣe sọ fun wọn. Ṣugbọn yoo gbọ gbogbo bukaata to ba rọ mọ irinajo naa. Paapaa julọ, Ọgbẹni Guerra yoo ni anfaani lati ni awọn iriri ti yoo sọ ọ di adari ọkọ loju omi.

" Àlá mi ni lati di adari ọkọ oju omi ki n si lọọ ṣiṣẹ ni Europe" .

"Fun idi eyi, inu mi dun gan-an nigba ti mo ri anfaani yii, mo ri i bii igba ti ala mi ti fẹẹ bẹrẹ si i wa si imuṣẹ."

Ọkan wọn ti ẹ tun balẹ si i nigba ti Guerra ati ẹnikeji rẹ ti wọn jọ fẹẹ lọ, iyẹn Rodrigo Dantas, foju kan oyinbo ọga wọn to fẹẹ gba wọn fun iṣẹ awakọ naa.

Awọn ti n ro o tẹlẹ pe o le lọọ jẹ ẹnikan ti ko ni i ko eeyan mọra, tabi ko kan jẹ agbenimọra kan lorii Instagram, ti yoo maa lo agbara ọga le wọn lori.

Ṣugbọn rara o, George Saul, oyinbo ọga wọn yii ko ri bẹẹ. Niṣe lo n rẹrin-in bo ṣe ri wọn, ara oyinbo naa yọ mọ wọn daadaa, ko si ni wọn lara rara. Koda, o ni wọn le maa pe oun lorukọ inagijẹ oun ti i ṣe "Fox".

"Mo ti ṣiṣẹ ninu awọn ọkọ oju omi kan ri to jẹ awọn to ni wọn ti dagba, wọn buru, wọn si maa n f'oju abuku wo mi. Ṣugbọn ọga eleyii ko ri bẹẹ. Ara rẹ balẹ, o si ko eeyan mọra daadaa. ''

Ọgbẹni Dantas, ikeji Guerra lo ṣe afikun bẹẹ nipa oyinbo ọga wọn tuntun to fẹẹ fun wọn niṣẹ ti wọn yoo fi rin lagbami okun.

George Saul (Fox) lo wa laaarin, Daniel Guerra; lapa osi ati Rodrigo Dantas lapa ọtun, ni 2017

Oríṣun àwòrán, Daniel Guerra

Àkọlé àwòrán, George Saul (Fox) lo wa laaarin, Daniel Guerra; lapa osi ati Rodrigo Dantas lapa ọtun, ni 2017

Ẹni ibi kò kọ ọ́ s'ójú

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Koda, nigba ti awọn obi Ọgbẹni Dantas n bẹru, pe ọmọ awọn fẹẹ ba ajoji rin irinajo to jinna to bayii, Fox, ni ki wọn fọkan balẹ. O ni ki wọn waa yọju soun funra wọn ki ọkan wọn le balẹ si i lori irinajo.

O pada ye wọn pe Fox ra ọkọ oju omi 'Rich Harvest' wa si Brazil fun atunṣe, o si n wa awọn akọṣẹmọṣẹ awakọ ti yoo ba a wa a pada si Europe.

Yatọ si Dantas ati Guerra, awọn eeyan meji mi-in naa yoo tun ba wọn lọ, pẹlu akọṣẹmọṣẹ adari ọkọ kan.

Ki wọn too gbera ni Brazil, awọn ọlọpaa ilẹ naa lo to wakati mẹfa ti wọn fi n yẹ ọkọ oju omi naa wo, pẹlu iranlọwọ aja oyinbo ti wọn tun lo fun iwadii naa.

Wọn ko ri ohun ti wọn n wa, awọn awakọ ti iwadii naa ṣoju wọn si ro pe awọn ọlọpaa wulẹ n ṣe ayẹwo to yẹ ki wọn ṣe naa ni.

Awọn naa ti gbọ nipa bi wọn ṣe maa n fi oogun oloro Cocaine pamọ sinu ọkọ oju omi, ṣugbọn ọkan wọn balẹ lorii tiwọn yii pe ko si ewu kankan.

"Bi eeyan ba fẹẹ wọ baaluu rin irinajo, bayii naa ni wọn yoo ṣe yẹ gbogbo ẹru rẹ wo pẹlu irinṣẹ ti wọn maa n lo fun ayẹwo. Iyẹn lemi fi ro pe nigba to jẹ irinajo ilẹ okeere ni tiwa yii naa, pe ko sohun to buru bi wọn ba yẹ wa wo finni-finni''

Ọgbẹni Dantas lo sọ bẹẹ nipa ayẹwo ti awọn ọlọpaa ṣe nipa ọkọ oju omi wọn.

Ọkọ oju omi Rich Harvest tawọn ọlọpaa yẹwo fun wakati mẹfa ki wọn too kuro ni Brazil ree.

Oríṣun àwòrán, Brazil police

Àkọlé àwòrán, Ọkọ oju omi Rich Harvest ti awọn ọlọpaa yẹwo fun wakati mẹfa ki wọn too kuro ni Brazil ree.

Ẹwọn ọdún mẹ́wàá wọlé wẹ́rẹ́

Nigba ti yoo fi di ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ ọdun 2017 ti wọn mu irinajo wọn pọn, awọn ibẹru bii eyi ti kuro lọkan awọn awakọ yii. Bi ere, bi ere ni wọn si bẹrẹ si i fi Brazil silẹ, ti wọn n tukọ lọ loju agbami.

Awọn ero ọkọ mi-in tun ba wọn rin irinajo yii, awọn bii Daniel Dantas (ko ba Rodrigo Dantas tan, orukọ wọn wulẹ papọ ni) pẹlu adari ọkọ ti wọn gba ni tuntun, Frenchman Olivier Thomas, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta.

Ṣugbọn o, Fox, to jẹ ọga patapata ko ba wọn rin irinajo yii, oun ti wọ baaluu lọ si Europe lọjọ meji ṣaaju awọn ikọ to n ba oju omi lọ yii.

" Nigba ti wọn n lọ, Ọgbẹni Guerra kọ ọrọ idupẹ si Fox loju opo Facebook rẹ, o ka bayii pe: "Mo dupẹ o, Fox, fun anfaani to o fun mi lati kọ ẹkọ yii, ati fun ajọṣepọ wa to tun gun rege si i . O ṣeun, akẹgbẹ mi.''

Lẹyin ọsẹ meji ti wọn ti n tukọ loju agbami, ọkọ oju omi wọn deede bajẹ, lo ba di dandan fun wọn lati duro ni Cape Verde, etikun kan to gba Iwọ Oorun Ilẹ Afrika kọja.

Erekuṣu ti ọkọ bajẹ si yii jẹ ibi ti awọn arinrin ajo afẹ ti maa n waa ṣe faaji, Fox naa si sọ fun wọn pe ki wọn ma mikan.

O loun yoo fi owo ranṣẹ si wọn ti wọn yoo fi ṣe faaji ara wọn lasiko ti wọn ba fi n tun ọkọ oju omi wọn ṣe nibi ti wọn n pe ni Marina.

Nigba ti ko si ti si ọlọpaa kankan to waa yẹ ọkọ to bajẹ naa wo tẹlẹ, Ọgbẹni Guerra naa ko bẹru kankan.

" Wọn ko ri nnkan ni Brazil, wọn o le ri nnkan kan ni Cape Verde naa."

Ohun ti Guerra sọ ni tiẹ niyẹn pẹlu ọkan rẹ to balẹ.

Ṣugbọn o, awọn ọlọpaa Cape Verde pada wa, wọn mura si ayẹwo ọkọ yii ju ti awọn akẹgbẹ wọn ni Brazil lọ, niṣe lawọn lo awọn irinṣẹ ara ọtọ, ti wọn si tu ọkọ oju omi to bajẹ naa yẹbẹyẹbẹ.

Nibi ayẹwo yii ni wọn ti ri oogun oloro to fẹrẹ to iwọn 1.2 tonnes, eyi ti owo rẹ to £100m ($134m), bi wọn ba ta a ni owo Europe.

"Niṣe lo da bii pe gbogbo ominira mi lo ti wọmi lọ, inu bi mi, o ṣoro fun mi lati gba ohun to n ṣẹlẹ gbọ. Emi ni wọn mu nigan-an bayii”Bẹẹ ni Guerra wi.

Ninu oṣu kẹta ọdun 2018, ikọ arinrinrin ajo yii jẹjọ ni Cape Verde, wọn lawọn ko mọ nnkan kan nipa ohun tawọn n tori rẹ kawọ pọnyin.

Wọn lawọn ko tiẹ gbọ nipa ọkọ oju omi Rich Harvest tabi olowo rẹ ri kawọn too gba iṣẹ naa latari ipolowo rẹ tawọn ri .

Ṣugbọn eyi ko ta leti adajọ, o ran wọn lọ sẹwọn ọdun mẹwaa ẹni kọọkan.

 Diẹ ninu awọn oogun oloro cocaine ti wọn ba ninu ọkọ oju omi naa ni Cape Verde ree.

Oríṣun àwòrán, Cape Verde police

Àkọlé àwòrán, Diẹ ninu awọn oogun oloro cocaine ti wọn ba ninu ọkọ oju omi naa ni Cape Verde ree.

Fox ṣe bẹ́ẹ̀ lọ mọ́ wọn lọ́wọ́

Ni 2018, wọn mu Fox ni Italy, nibi ti awọn ọlọpaa Brazil ti kọwe pe e lẹjọ. Wọn fẹẹ ki wọn gbe e pada wa si Brazil lati jẹjọ ẹsun ti wọn fi kan an.

Ṣugbọn iwe ti wọn fi pe e lẹjọ ko tete de, wọn si da a silẹ pe ko maa lọ.

Eyi bi awọn ọlọpaa Brazil ninu, paapaa Inspector Andre Gonçalves ti i ṣe ọga ọlọpaa wọn.

Ohun ti Andre n ro ni pe Fox sa lọ ni.

"Niṣe lo da bii pe gbogbo igbiyanju wa ko so eso rere, o dun wa gan-an". Andre lo sọ bẹẹ fun BBC.

O ni ẹni ti awọn n wa ni Brazil ni Fox ati ọkọ oju omi rẹ.

Atunṣe to waa ṣe lori ọkọ ọhun paapaa ki i ṣe nitori nnkan meji, bi ko ṣe ko le kọ ibi ti yoo ko oogun oloro naa si .

O ni oun ro pe awọn awakọ mẹrin yẹn naa mọ nipa rẹ tẹlẹ ni.

"Nigba ti ẹ ba ba eeyan ninu ọkọ pẹlu oogun oloro, ohun to maa wa si eeyan lọkan naa ni pe ẹni yẹn mọ nipa ẹ

Ṣugbọn bi a ṣe n ṣewadii lọ, a ri i pe ko sohun to fidi ẹ mulẹ pe wọn mọ nipa oogun oloro naa latilẹ.

''Eyi si jẹ ki ẹri to n tako Fox f'oju han si i."

Ni 2019, wọn yi idajọ yii pada, wọn si fi awọn ikọ ti wọn ti kọkọ ran lẹwọn ọdun mẹwaa naa silẹ pe ki wọn maa lọ sile.

Ṣugbọn Fox ni tiẹ ko jẹjọ lori iṣẹlẹ yii ri, niṣe lo pada si UK to n ṣe aye rẹ lọ.

Fox ree, ẹni ti orukọ rẹ gan-an n jẹ George Saul. Oju opo Instagram rẹ lo fi aworan yii si

Oríṣun àwòrán, George Saul

Àkọlé àwòrán, Fox ree, ẹni ti orukọ rẹ gan-an n jẹ George Saul. Oju opo Instagram rẹ lo fi aworan yii si

BBC mu Fox mọlẹ ni ile itura kan ni Norwic.

O kọ lati sọrọ nipa ọkọ oju omi rẹ ati awọn awakọ to koju iṣoro naa.

A tun beere ohun to ni i sọ nipa bawọn eeyan ṣe n pe e ni agboogun oloro, o si dahun pe, ''emi ki i gbe oogun oloro''.

Agbẹnusọ NCA kan sọ pe b'awọn ọlọpaa Brazil ba ṣi fẹẹ tẹsiwaju ninu ọrọ yii, wọn yoo ni lati kọ iwe ti wọn yoo fi pe e wa sile ni.

Ni ti ẹka idajọ Brazil, wọn ni awọn ki i da si ọrọ to ba ni i ṣe pẹlu ẹyọ eeyan kan.

Rodrigo Dantas ati Daniel Guerra to koju wahala nkọ, wọn n gbiyanju lati tun aye wọn to ni Brazil, wọn ti gbagbe erongba wọn lati di adari ọkọ oju omi!.

 Daniel Guerra ati Rodrigo Dantas nibẹrẹ ọrọ, nigba ti wọn n yọ ayọ irinajo naa ni 2017

Oríṣun àwòrán, Brazil police

Àkọlé àwòrán, Daniel Guerra ati Rodrigo Dantas nibẹrẹ ọrọ, nigba ti wọn n yọ ayọ irinajo naa ni 2017

Bí mo bá tún f'ojú kan Fox,ohun tí mo kojú lẹ́wọ̀n ni mà á fi hùwà sí i- Guerra

Nigba ti awọn to ṣẹwọn aimọdi yii pada sile ni Brazil, Ọgbẹni Dantas loun gbiyanju lati tun wa iṣẹ awakọ oju omi ṣe, ṣugbọn awọn agbani-siṣẹ kan n fi oju ẹni to jẹbi ẹsun oogun oloro wo oun.

Ni ti Guerra, o ni gbogbo erongba lati di awakọ oju omi oun parẹ si Cape Verde ni.

O ni o ṣoro foun lẹyin iṣẹlẹ naa lati gba ẹnikẹni gbọ mọ, nitori ohun ti oju oun ri lagbami iṣẹ aje ti oun ba lọ.

Koda titi di asiko yii, o ni iru eeyan ti Fox jẹ ṣi maa n ya oun lẹnu ni. Ọkunrin oyinbo Gẹẹsi ti oju rẹ tutu daadaa yẹn, ẹni ti oun figba kan fi ẹmi imoore han si, ẹni ti ipolowo iṣẹ rẹ da ori aye oun kodo.

Guerra sọ pe o maa wu oun ki idajọ ododo waye, ṣugbọn ko wu oun lati tun f'oju kan Fox mọ laye oun.

"Ti mo ba tun f'oju kan Fox, ki i ṣe emi ni mo maa ba a sọrọ, Daniel mi-in ni. Gbogbo iriri buruku ti mo ba pade lọgba ẹwọn ni ma a fi huwa si i. Mi o ni i le ba a ṣe bii ọmọluabi rara."