Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ obìnrin tó jí ọmọ tuntun gbé lọ́jọ́ ìsọmọlórúkọ

Police

Oríṣun àwòrán, @@NAS_PoliceNG

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa Nasarawa ti sọ pe oun ti fi ṣikun ofin mu obinrin kan, Khadija Aliyu, lori ẹsun pe o ji ọmọ ọjọ meje kan gbe lọjọ isọmọlorukọ rẹ.

Agbegbe Keffi ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Olukoro ileeṣẹ ọlọpaa Nasarawa, DSP Ramhan Nansel, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan loju opo X.

Ninu ọrọ ọlọpaa, obinrin naa dibọn bii alaboyun, o si fi ọgbọn alumọkọrọyi wọ inu ile ti isọmọlorukọ ọhun ti n waye lati ji ọmọ naa gbe nibi to sun si.

Iroyin ni ṣe afurasi ọhun gbe ọmọ naa pọn si ẹyin rẹ, to si fi aṣọ bo o naa mọlẹ ko to fi ẹsẹ fẹ.

Ọlọpaa sọ pe “ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ni awọn ọlọpaa to wa lagbegbe Keffi fi ṣikun ofin mu obinrin kan, Khadija Aliyu lori ẹsun pe o ji ọmọ ọjọ meje gbe lọjọ isọmọlorukọ rẹ niluu Keffi.

“Afurasi ọhun, to sọ pe alaboyun ni oun lọ sibi isọmọlorukọ naa to wa lẹyin ọọfisi ajọ INEC niluu Keffi.

“Lasiko ti ayẹyẹ isọmọlorukọ naa n lọ lọwọ lo yọ wọle to si ji ọmọ to sun gbe, o gbe ọmọ naa si ẹyin rẹ, fi aṣọ bo o, o si salọ ki ọwọ ofin to pada tẹ.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti iroyin jiji ọmọde gbe yo waye ni Naijiria.

Ninu oṣu Keje, ọdun 2023, ọwọ ọlọpaa tẹ obinrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan to ji ọmọ gbe ni ijọba ibilẹ Misau, nipinlẹ Bauchi.

Afuasri naa, Hajara Usman ji ọmọ ọhjn gbe pẹlu igbimọpọ pẹlu ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogun kan lagbegbe Dugurgama Hamlet.

Nnkan bii aago mẹrin abọ afẹmọju ni ọwọ tẹ afurasi naa.