Alùfáà ìjọ tí wọ́n jí gbé ní Kwara gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn tí ẹbí rẹ̀ san ₦10m owó ìtúsílẹ̀

Ẹni Ọwọ Adewumi àti onimọ ẹrọ Adeyemi tí àwọn ajinigbe ji gbe

Oríṣun àwòrán, Isaac Adeyemi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ajinigbe ti yọnda Oniwaasu ijọ (ECWA) kinni ti wọn ji gbeni ilu Olla, ipinlẹ Kwara, Ẹni ọwọ S.O Adeyẹmi lẹyin ọjọ marun-un to ti wa lakata awọn ajinigbe naa.

Miliọnu mẹwaa naira ni awọn ajinigbe naa gba ki wọn to tu alufaa ijọ naa silẹ.

Alẹ ọjọ Ẹti to re kọja lọ ni awọn ajinigbe ji Oniwaasu naa ati Onimọ ẹrọ Adeyemi gbe ni ilu Olla, ijọba ibilẹ isin ipinlẹ Kwara.

Ọkan lara awọn mọlẹbi alufaa naa, Ọgbẹni Adekunle fidi ẹ mulẹ pe awọn ajinigbe naa gba owo idoola Million mẹwàá náírà (#10, 000,000) ki wọn to yọnda Oníwàásù naa.

O fi kun pe ẹnìkejì ti wọn ji gbe pẹlu alufaa naa onimọ ẹrọ Adeyemi sa mọ awọn ajinigbe naa lọwọ lasiko ti wọn n ko wọn lọ lẹyin ti wọn ji wọn gbe.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejire Adeyemi Toun ṣeleri lati fesi sọrọ naa laipẹ nigba ti BBC News Yoruba kan si lori iroyin yii.

Iwa ijinigbe lati fi gba owo lọwọ awọn ẹbi onitọhun lo jẹ nnkan to ti gbilẹ ni Naijiria lati bii ọdun meloo kan sẹyin.

Bi o tilẹ jẹ pe sisan owo idoola fawọn ajinigbe lo jẹ ohun to lodi sofin ni Naijiria amọ ọpọ awọn eeyan ti wọn ba ji awọn eeyan wọn gbe lo maa n san owo yii.

Àwọn ajínigbé yawọ ilé ìgbé àlùfáà ìjọ, jí èèyàn méjì gbé ní Kwara

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn ajinigbe tun ti ṣọṣẹ ni ipinlẹ Kwara bi wọn ṣe yawọ inu ile ti wọn si ji eeyan meji gbe lọ.

Ni ilu Olla ni ijọba ibilẹ Isin, ipinlẹ Kwara ni iṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Ẹti.

Oniwaasu ijọ ECWA kinni ti ilu Olla, Ẹni ọwọ S. O. Adewumi ati Onimọ ẹrọ Adeyemi ni awọn ajinigbe naa ji gbe ninu ile wọn.

Ọkan lara awọn ara ilu naa to ba BBC News Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Yusuf Adekunle ṣalaye pe nnkan bii aago mẹjọ abọ alẹ ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ naa waye.

O ṣalaye pe ile alufaa ijọ ECWA naa awọn ajinigbe naa kọkọ lọ ka mọ ile ti wọn si jigbe nibẹ.

O ni nigba ti wọn n lọ ni wọn beere lọwọ alufaa naa pe, ta lo ni ọkọ to wa ni ita, ti Oniwasu naa si ni onimọ ẹrọ Adeyemi lo ni i.

“Àwọn ajinigbe sọ fun Alufaa Adewumi pe ki o lọ kan ilẹkun Adeyemi ko si maa bawọn sọrọ bii pe oun nikan lo wa nibẹ, ki o darukọ ara rẹ pe oun fẹ ri i.

“Eyi lo mu ki ti Onimọ ẹrọ Adeyemi ṣilẹkun fun wọn laimọ pe awọn ajinigbe tẹle lati ji awọn mejeeji gbe.”

O fi kun pe lati igba naa ni awọn ajinigbe naa ti gbe wọn lai tii gbọ ohunkohun nipa wọn.

Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, awọn ajinigbe ko i ti kan si mọlẹbi awọn eniyan ti wọn ji gbe, ti ẹnikẹni ko si le sọ pe nnkan bayii ni wọn n fẹ.

Awọn ara ilu Olla kọminu lori bi awọn ajinigbe ṣe maa n yọ awọn lẹnu ninu ile naa ati pe inu fu, aya fu ni awọn fi n gbe ile awọn.

Suraj Adeyemi ati Funmilayo Adeoti sọ pe bẹru bojo lawọn èèyàn ilu Olla ń gbe báyìí nitori gbogbo igba lawọn ajinigbe n yọ awọn lẹnu ninu ilu naa.

Wọn parọwa si Ijọba ipinlẹ Kwara lati ran awọn èèyàn ilu Olla lọwọ ki alafia le pada si ilu naa.

Wọn ni ọpọ awọn ọmọ bibi ilu Olla to n gbe ilẹ okere lo ti n kọ lati wa si ilu wọn tawọn mii si tun leri pe awọn o ni wa ilu naa mọ nitori ijinigbe naa ti n lagbara pupọ.

Nigba ti a kan si agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyemi Toun o ni oun yoo kan si wa pada lori iṣelẹ naa.