₦13b owó ìlú tí àwọn kan jí kó ni a gbà padà nínú oṣù Kẹsàn án ọdún yìí nìkan – ICPC

Oríṣun àwòrán, ICPC
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, ICPC ti sọ pe owo to le ni biliọnu mẹtala ti awọn kan lu ni ponpo lawọn ti gba pada ninu oṣu Kẹsan an ọdun 2024 nikan ṣoṣo.
Alaga ajọ naa, Musa Aliyu lo sọrọ naa niluu Abuja lasiko ti wọn n ṣi oju eto ajọ ọhun fun ọdun 2024 si 2028.
Aliyu ni awọn ko sinmi lati maa gba owo ilu lọwọ to n ji ko lọ bo tilẹ jẹ ko mẹnuba orukọ awọn ti wọn gba N13b naa lọwọ wọn.
O ni “laarin ọdun kan sẹyin, ICPC ti ṣe ọpọ aṣeyọri ninu iṣẹ rẹ; fun apẹrẹ, a ri biliọnu mẹtala owo ilu ti awọn kan ko sapo ara wọn gba pada ninu oṣu Kẹsan an ọdun 2024 nikan ṣoṣo.
“Diẹ lara awọn iṣe takuntakun ti a n ṣe niyi lati ri daju pe a ko ba ojuṣe wa ku.”
Ọga ICPC naa sọ siwaju si pe awọn n lo imọ ẹrọ lati gbena woju iwa ibajẹ lawujọ Naijiria.
O ni “awọn atunto wọnyii yoo mu wa jẹ aṣaaju ninu awọn to n lo imọ ẹrọ lati koju iwa ibajẹ, eyii ti yoo mu wa leke awọn onijibiti ode oni.”
Bakan naa lo mẹnuba ohun ti wọn n ṣe lori idanilẹkọọ fun awọn oṣiṣẹ wọn lati le ṣiṣe to munadoko.
Aliyu sọ pe “igbesẹ yii yoo ro awọn oṣiṣẹ wa lagbara lati yanju awọn iwa ọdaran ati jibiti.”
O fi kun pe awọn tun n gbe igbesẹ lati ṣawari awọn kudiẹkudiẹ to wa lawọn ileeṣẹ ijọba nibi ti awọn eeyan ti n kowo ilu sapo lati le yanju awọn kudiẹkudiẹ naa.
O pari ọrọ rẹ pe ICPC n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹka mii bii Anti-Corruption and Transparency Units (ACTUs) lati le ri pe iwa ibajẹ di ohun atijọ ni Naijiria.















