Wo ìpínlẹ̀ méje tó lè pinnu ẹni tí yóò di ààrẹ Amerika ninu ìdìbò ọdun 2024 yìí

Aworan ilẹ America pẹlu Arizona, Georgia, Michigan, Nevada, North Carolina, Pennsylvania ati Wisconsin.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

O fere to ojilenigba miliọnu eeyan (240 million) ti wọn lẹtọọ lati dibo ninu idibo ilẹ America ninu ọdun 2024 yii, ṣugbọn onka perete ninu wọn lo lẹnu nibẹ, ti wọn le pinnu ibi ti eto idibo naa yoo wo si, ati ẹni ti yoo di aarẹ gan-an.

Awọn amoye gbagbọ pe ipinlẹ to le mu Kamala Harris tabi Donald Trump, jawe olubori ko to nnkan ninu ẹgbẹ Democrats abi ti Republican ti kaluku wọn n ṣe.

Meje ninu awọn ipinlẹ alẹnulọrọ ọhun ni - Arizona, Georgia, Michigan, Nevada, North Carolina, Pennsylvania ati Wisconsin

O ṣee ṣe ko jẹ awọn ni wọn yoo pinnu ẹni ti yoo wọle bii aarẹ sile agbara ilẹ America.

Ni bayii ti idibo ti n sunmọle, ipolongo ibo ti lagbara si i nigun mejeeji.

Wọn n gbiyanju lati gbe awọn eeyan ti ko ti i mọ ẹni ti wọn yoo dibo fun mọra, ti awọn naa yoo fi dibo.

Arizona

Iranlọwọ ati atilẹyin ipinlẹ Arizona yii, ran ẹgbẹ oṣelu Democrats lọwọ lati depo aarẹ ni 2020. Wọn dibo naa fi ṣatilẹyin fun ẹni ti wọn fẹ, ibo ti wọn si di gbẹyin ko too di 2020 yii, laaarin ọdun 1990 ni.

Bi Arizona ṣe jinna si Mexico to, bii pe o ba a pa aala ni. O si jẹ ibi kan ti awọn arinrinajo ki i yee sọ nipa rẹ.

Trump ti fi ọpọ igba ko Kamala Harris loju lorii bawọn eeyan ṣe n rin irinajo lọ si ilu naa, nitoriAarẹ Joe Biden fun niṣẹ lorii bi wọn yoo ṣe din ija ẹnu aala naa ku nigba yẹn.

Bakan naa ni Trump tun ti leri lati pe boun ba fi le di aarẹ, oun yoo le awọn ti ko ba yẹ ki wọn wa l'America jade niluu naa.

Ati pe ko ni i si iru ẹ ninu itan, oun yoo le wọn tan ráúráú ni.

Ọrọ oyun ṣiṣẹ naa tun jẹ ohun kan ti Arizona n fa, ọrọ naa si ti di ariyanjiyan kaakiri ilu, lati 2022 ti ile ẹjọ to ga ju lọ l'America ti yi ofin to fun awọn obinrin ni anfaani lati ṣẹyun pada.

Ẹka aṣọbode ati eyi to n ri si aabo ẹnu ibode l'America lo gbe atẹ yii jade di oṣu keje ọdun 2024.
Laarin ọdun 2020 si 2023,awọn onka kan ko si nibẹ nitori arun Korona.

Georgia

Awọn ipinlẹ ti a pe ni alẹnulọrọ yii ni Trump naa mu lasiko ibo ọdun 2020, ibẹ ni awọn eeyan Trump ti fẹẹ yi Biden lagbo da sina nigba naa.

Ilu Georgia ni Trump ti lugbadi awọn ẹjọ mẹrin ti wọn n ka si i lẹsẹ (Wọn ti da a lẹbi ninu ẹjọ kan, awọn yooku ṣi n lọ lọwọ.)

Trump ati awọn mejidinlogun mi-in ni wọn fẹsun kan, pe wọn ditẹ lati da oju ọrọ ru, wọn ni wọn fẹẹ gbe ibo Biden fun Trump nibẹ.

Trump ni ko sohun to jọ bẹẹ. O loun ko ṣẹ ẹṣẹ kankan, ẹjọ naa si n fara jọ pe wọn ko ni i le gbọ ọ ki idibo too de.

Ida mẹta awọn eeyan to n gbe ni Georgia ni wọn jẹ ẹya Africa-America, awọn eeyan dudu si pọ nibẹ gidi. Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe akojọpọ awọn eeyan naa to dibo fun Biden ni 2020 lo jẹ ki ọkunrin naa di aarẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan n sọ pe awọn kan le ma dibo ninu awọn eeyan dudu naa lọtẹ yii, ṣugbọn Kamala Harris ni afojusun ati ri nnkan mu nibẹ.

Aworan Trump ti wọn fi ọwọ ya nile-ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Michigan

Aworan obinrin kan to gbe akọle to n kede ikọyin si Biden dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ipinlẹ ti a tun mọ si Great Lakes state yii ti yan oludije sipo aarẹ lẹẹmeji ninu ibo to waye kọja, wọn si yege.

Wọn ti n koro oju si Biden bayii ṣaa, nitori atilẹyin ti wọn lo n ṣe fun Israel lasiko ogun Gaza.

Ninu idibo abẹle Democratic, loṣu keji, o le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan ondibo to diidi jẹ ki ibo wọn ṣofo, wọn ṣe eyi lati jẹ ki ijọba America dawọ atilẹyin to n ṣe fun Israel duro.

Awọn eeyan ti wọn jẹ apa kan Larubawa (Arab-Americans) pọ ni Michigan. Wọn ko fifẹ han si Biden mọ, ṣugbọn awọn ajijagbara kan ni Gaza sọ fun BBC pe awọn lero pe Kamala yoo dẹrun fun awọn.

Ni ti Trump, oun ti la alakalẹ bi Michigan ṣe ṣe pataki to fun aṣeyọri oun.

Nigba to n ṣorọ nipa awọn ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe Middle East, o ni ki Israel tete pari ipolngo rẹ lorii Hamas ni Gaza.

Nevada

Ẹgbẹ oṣelu Democrat ni ipinlẹ ti wọn n pe ni Silver State yii dibo fun ninu awọn ọpọ ibo to ti waye, ṣugbọn òye ti n foju han bayii pe o ṣee ṣe ki nnkan yi pada si ti Republican.

Abajade awọn esi nipa bi wọn ṣe n wadii ibo lasiko yii fi han pe Trump lo n lewaju Biden, ṣugbọn iyẹn ti yi pada nigba ti Kamala Harris ti de.

Awọn oludije mejeeji lo n wa ọna bi wọn yoo ṣe ri ọpọ ibo mu nipinlẹ yii.

Pẹlu bi ọrọ aje America ṣe gunke agba si i, ti ipese iṣẹ pọ si i pẹlu latiba ti Biden ti de ori aleefa, idagbasoke Nevada ko ya kankan bii ti awọn ibo mi-in mọ lẹyin ti Korona ṣọṣẹ.

Ida marun-un le diẹ ( 5.1%,) ni awọn eeyan ti ko niṣẹ lọwọ nipinlẹ naa, lẹyin California ati agbegbe Columbia, gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ to n ṣe onka l'America ṣe sọ.

Bi Trump ba wọle pada, o ti leri pe oun yoo pada si sisan owo ori ti ko to nnkan, ati ofin ti ko ni i kọja afarada ti yoo maa ri si owo ori sisan ọhun.

Aworan obinrin to de fila ate ati ibomu ti wọn kọ "Biden Harris" si .

Oríṣun àwòrán, Getty Images

North Carolina

Nnkan ṣe bii ẹni yipada nipinlẹ yii lẹyin ti Kamala Harris gba ipo rẹ loke tente , awọn awoye kan si ti sọ pe apẹrẹ daadaa ni .

Eyi ṣee ṣe ko jẹ idi ti Trump ko ṣe tun fẹẹ lọ sibẹ mọ, lẹyin ti ẹnikan ti fẹe pa a loṣu keje to lọọ polongo ibo nibẹ.

“Ipinlẹ yii tobi pupọ lati rọwọ mu". Bẹẹ ni Trump sọ fun awọn ero to pejọ sibẹ nigba naa.

North Carolina paala pẹlu Georgia, ohun to ba si n ṣẹlẹ ni Arizona n ṣe rẹgi pẹlu awọn naa ni.

Trump lo gbe North Carolina ni 2020, ṣugbọn ibo ti ko ju ẹgbẹrun lọna aadọrin lọ naa ni. Eyi ti mu ki awọn ọmọ ẹgbẹ Democrats maa ro o pe o ṣee ṣe ki nnkan ṣe ẹnu ire ninu ibo ọdun yii.

Pennsylvania

Donald Trump ree lẹyin ti ẹnikan fibọn ge e leti lasiko ipolongo ibo ninu oṣu keje.

Oríṣun àwòrán, EPA

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igun mejeeji lo n ja raburabu lati ri ipinlẹ yii mu, nibi ti Donald Trump ti bọ lọwọ awọn to fẹẹ pa a.

Ipinlẹ yii ko ipa to jọju ninu idibo ọdun 2020, Joe Biden ni wọn si ṣatilẹyin fun.

Omọ ile ni Biden nibẹ, niluu Scranton to dagba si.

Ọrọ aje lo jẹ nnkan pataki nibi, gẹgẹ bo ṣe ri lawọn ibo mi-in naa. Ọwọngogo ọja gbode kan labẹ iṣakoso Biden, ko too di pe o bẹrẹ si i dẹrun diẹdiẹ.

Kedere lo foju han pe awọn Pennsylvania yii jẹ nnkan pataki laarin awọn eeyan America, pẹlu ohun ti oju wọn ri nipasẹ ọwọngogo.

Ilu yii ni awọn nnkan eelo ati ọja gbogbo ti wọ́n ju l'America, gẹgẹ bi akọsilẹ wọn ti i ṣe Datasembly ṣe sọ.

Ṣaaju ni BBC ti royin nipa bawọn eeyan ṣe n daamu lati gbele aye ni Erie - apa ibi kan ni Pennsylvania, nibi ti ẹnikan ninu eeyan mẹjọ ko ti le da ''ọwọ mu lọ sẹnu.''

Ọwọngogo ọja yii le ma jẹ ki nnkan ṣe ẹnu ire fun Kamala Harris nibi ibo, nitori inira ọrọ aje to n koju awọn eeyan.

Trump ni tiẹ la gbọ pe o ti loun yoo se Harris pa mọ ọrọ aje ti Biden n lo ni.

Wisconsin

Donald ati Melania Trump,pẹlu JD ati Usha Vance

Oríṣun àwòrán, EPA

Ipinlẹ yii naa yan aarẹ to yege ni 2016 ati 2020, ibo bi ẹgbẹrun lọna ogun ti ibẹ wa.

Awọn akọṣẹmọṣẹ amoye ti sọ pe kekere kọ ni ipa ti ibo agbegbe yii le ni, nibi ti awọn eeyan ti a le pe ni Lagata n gbe, ti wọn si n polongo tako awọn agba ọjẹ meji to n dije.

Idibo ṣaaju ti fi han pe awọn ti wọn ṣatilẹyin fun Robert F Kennedy Jr le din ibo Harris ati Trump ku.

Awọn Democrat ti n gbiyanju lati lati yọ Jill Stein, ọmọ ẹgbẹ Green Party kuro ninu ibo lagbegbe yii, wọn ni ẹgbẹ naa ko tẹle awọn ofin idibo.

Bẹẹ ni wọn si tun lawọn ko fẹ Cornel West, ibudo igbẹkọ kan.

Ninu ilu naa ni Kamala ti n ṣe ipolongo tẹlẹ, ki wọn too fa a kalẹ gẹgẹ bii oludije fun ẹgbẹ wọn.

Kamala Harris ati Tim Walz, duro niwaju ọpọ eeyan ni Milwaukee.

Oríṣun àwòrán, Reuters

A red and blue divider graphic