Ìdìbò Amẹ́ríkà: Ta ni ó ń léwájú nínú Harris àti Trump?

- Author, By the Visual Journalism and Data teams
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kọkànlá ni àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà yóò dìbò láti yan ààrẹ tuntun.
Ètò ìdìbò náà ni kò bá wáyé láàárín Ààrẹ Joe Biden àti Donald Trump àmọ́ nínú oṣù Keje ni Biden ni òun kò ní díje mọ́, tó sì fa igbákejì rẹ̀, Kamala Harris lọ́wọ́ sókè gẹ́gẹ́ bí ẹni tgí yóò díje.
Ìbéèrè tó gbẹnu ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé ṣé Amẹ́ríkà yóò dìbò yan obìnrin sípò ààrẹ fún ìgbà àkọ́kọ́ àbí Donald Trump yóò padà fún sáà kejì?
Bí ọjọ́ ìdìbò ṣe ń súnmọ́, a máa ma ṣe àgbéyẹ̀wò bí ètò ìdìbò náà ṣe ń lọ àtiipa tí ìpolongo àwọn olùdíje yóò ní lórí àwọn olùdìbò.
Ta ni ó ń léwájú nínú àwọn méjéèjì?
Harris ni ó ń léwájú nínú àwọn àkójọpọ̀ ìbò tó wà lóde báyìí.
Ṣáájú kí Biden tó pinnu láti má díje fún ipò ààrẹ náà mọ́, Trump ni ó ń gba ìwájú àmọ́ tó ti yípadà láti ìgbà tí Harris ti ń díje pẹ̀lú Trump ni ó ti gba iwájú tó sì ń ba lọ títí di àsìkò yìí.
Àwọn olùdíje méjéèjì kópa nínú ìtàkurọ̀sọ kan lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán Pennsylvania ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kẹsàn-án tí èèyàn mílíọ̀nù mẹ́tàdínláàádọ́rin sì wò ó. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wo ìtàkurọ̀sọ náà gbàgbọ́ pé Harris ṣe dada ju Trump lọ.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àtẹ̀ ìbò tí wọ́n ṣe lẹ́yìn ìtàkurọ̀sọ náà ń ṣàfihàn pé Harris ń rí àtìlẹyìn àwọn olùdìbò ju ti àtẹ̀yìnwà lọ bí àlékún ṣe bá ìdá 2.5% tó fi ń léwájú Trump di 2.9% lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan.
Fún Trump, àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ tó ń lékún ṣáájú ìtàkurọ̀sọ náà ló já wálẹ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan.
Ẹ lè rí àwọn ìyàtọ̀ tó wáyé náà nínú àkójọ ìsàlẹ̀ yìí fún àwọn olùdíje kọ̀ọ̀kan.
Bí àwọn àtẹ̀ ìbò yìí ṣe wúlò láti mọ olùdíje tó gbajúmọ̀ jùlọ láàárín àwọn olùdíje, kìí ṣe ọ̀nà tó kójú òṣùwọ̀n láti mọ bí èsì ìbò yóò ṣe rí.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí Amẹ́ríkà ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò ìdìbò níbi tí wọ́n ti máa ń fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní iye ìbò tí wọ́n nílò láti ní ní ìbámu pẹ̀lú iye èèyàn tó bá ń gbé ní ìpínlẹ̀ náà. Àpapọ̀ àwọn kọ́lẹ́ẹ̀jì ìbò 538 ni ó wà báyìí, tí olùdíje kan sì gbọdọ̀ ní 270 kó tó jáwé olúborí.
Àádọ́ta ìpínlẹ̀ ló wà ní Amẹ́ríkà ṣùgbọ́n nítorí pé ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà ni ọ̀pọ̀ wọn máa ń dìbò fún, díẹ̀ ni ìpínlẹ̀ táwọn olùdíje ti máa ń làkàkà láti jáwé olúborí. Àwọn ìpínlẹ̀ yìí ni wọ́n máa ń pè ní ojú ogun, tó sì máa ń sọ ẹni tí yóò jáwé olúborí ìbò náà.
Ta ni ó ń gbégbá orókè láwọn ìpínlẹ̀ ojú ogun?
Lọ́wọ́ yìí, ó ṣòro láti sọ pé ẹni báyìí ló ń léwájú nítorí ìbò náà le láàárín àwọn olùdíje méjéèjì ní àwọn ìpínlẹ̀ méje tó jẹ́ ìpínlẹ̀ ojú ogun yìí.
Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn àkójọ ìbò ṣàfihàn pé bíi ìdá kan sí méjì ni àwọn olùdíje fi ń ṣíwájú ara wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpínlẹ̀. Lára àwọn ìpínlẹ̀ náà ni Pennsylvania tó ṣe kókó nítorí ibẹ̀ ni àwọn olùdìbò pọ̀ sí jùlọ àti pé ó lè mú kí ó rọrùn fún olùdíje láti ní ìbò 270 tí wọ́n nílò láti wọlé ìbò.
Pennsylvania, Michigan àti Wisconsin jẹ́ àwọn ìpínlẹ̀ tí ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat ti máa ń rí ìbò tó pọ̀ kí Trump tó yi padà nígbà tó wọlé ìbò lọ́dùn 2016. Biden gbà á padà lọ́dún 2020 láti wọlé ìbò, tí Harris náà bá lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dún yìí, ó ṣeéṣe kó wọlé ìbò Amẹ́ríkà láti di ààrẹ.
Láti ṣe àfihàn bí àyípadà ṣe ti wáyé lórí ìdibò náà láti ìgbà tí wọ́n ti kéde Harris gẹ́gẹ́ bí8 oloùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat, lọ́jọ́ tí Joe Biden kéde pé òun kò ní díje mọ́, bí ìdá márùn-ún ni Trump fi ń léwájú rẹ̀ ní àwọn ìpinlẹ̀ méje náà.
Báwo ni wọ́n ṣe ń ka àwọn nọ́mbà yìí?
Àwọn nọ́mbà tí a lò nínú ìròyìn yìí jẹ́ èyí tí polling analysis website 538, tó jẹ́ ará iléeṣẹ́ ìròyìn American, ABC News ṣe àkójọ rẹ̀. Láti ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀, 538 yóò ṣe àkójọ ọ̀pọ̀ àwọn ìbò tí àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe àkóso wọn ń kójọ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ìpínlẹ̀ méje náà.
Láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn ìbò tí wọ́n ń kó jọ kájú òṣùwọ̀n, ọ̀pọ̀ àwọn ìgbésẹ̀ ni wọ́n máa ń gbé bíi ṣíṣe àfihàn iye èèyàn tó dìbò, ibi tí wọ́n ti dìbò àti bí ètò ìdìbò náà ṣe lọ (bóyá pẹ̀lú ìpè, àtẹ̀jíṣẹ́, lórí ayélujára àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ).
Ẹ lè kà nípa àwọn ìlànà wọn ní ẹ̀kúnrẹ̀rẹ̀ níbí.
Ṣé àwọn èsì ìbò yìí ṣe é fọkàn tán?
Lásìkò yìí, àwọn ìbò tó ń jáde ṣàfihàn pé Kamala Harris àti Donald Trump ń ba ara wọn pò ó ní àwọn ìpínlẹ̀ méje yìí àti pé tó bá ti súnmọ́ ara wọn báyìí, ó ṣòro láti lè sọ pé ẹnhi báyìí ni yóò borí ìbò.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìbò tí wọ́n kójọ lọ́dún 2016 àti 2020 ló ní Trump kò rí àtìlẹyìn tó. Ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ló máa ṣiṣẹ́ láti ṣe àwọn àtùnṣe yìí lọ́pọ̀ ọ̀nà tó fi mọ́ láti ri pé èsì wọn papọ̀ mọ́ èsì ìbò gangan.













