Israel gba àwọn apá ibì kan ní Lebanon, ṣèkìlọ̀ fárá ìlú

Oríṣun àwòrán, EPA
Bi ogun ti ilẹ Israel n gbe koju Lebanon ṣe n gbilẹ si i, ikọ ologun Israeli ti yawọ awọn apa ibi kan ni Guusu Lebanon, pẹlu ero lati kọlu awọn Hezbollah.
Ni bayii, wọn ti kilọ fun awọn ara Lebanon pe ki wọn ma ṣe wọ ọkọ lọ si apa Guusu, kọja lọ si odo Litani, eyi ti i ṣe ogún maili si Ariwa aala Israel ati Lebanon.
Bakan naa ni wọn ti kilọ fun awọn ara abule mẹẹẹdọgbọn, wọn ni ki wọn kuro nibi ti wọn n gbe, ki wọn gba apa Ariwa lọ.
Gẹgẹ bi ikọ ologun Israel Defense Forces (IDF), ṣe wi, igbesẹ Israeli yii wa fun gbigba awọn nnkan amayedẹrun lọwọ awọn Hezbolla.
Wọn ni ewu loko Longẹ lo jẹ fun Isreali.
Ṣugbọn awọn Hezbollah sọ pe ko si awọn ologun naa niluu awọn.
Hezbollah to n jijagbara sọ pe awọn naa ṣetan lati koju ẹni to ba gbogun ti awọn, ṣugbọn wọn ko ti i pade Isreali lati ja.
Hezbollah tun sọ pe awọn paapaa nawọ ija si Mossad ti i ṣe ọfiisi awọn Israeli, bẹẹ ni wọn sọ fun Tel Aviv.
Ṣugbọn Lebanon ṣi n tẹsiwaju lati maa koju ikọlu lọ.
Yoav Gallant, ọga ologun Israel, sọ pe awọn ṣetan lati gbe ikọlu awọn gba inu afẹfẹ, oju omi ati ori ilẹ. O ni awọn Hezbollah ni awọn n wa bẹẹ.
Ninu ọrọ kan ti wọn gbe jade loju opo X, ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Iṣẹgun, ikọ IDF fidi ẹ mulẹ pe awọn ikọ ti kọja si ẹnu aala ilu, lẹyin ti awọn gbe ọkọ ologun kalẹ si Ariwa Israel.
‘Ọkan nínú àwọn àsìkò tó burú jù ni ìlu wa ń là kọjá yìí’

Oríṣun àwòrán, Getty image
Olootu ijọba Lebanon, Najib Mikati, sọ lọjọ Iṣẹgun, pe ọkan ninu awọn asiko to buru ju ninu itan ni orilẹede oun n la kọja bayii.
O ti fẹrẹ to miliọnu kan eeyan ti wọn ti fi ile wọn silẹ, ti wọn ko ri awọn mọlẹbi wọn mọ latigba ti Israel ti bẹrẹ ikọlu rẹ si Lebanon loṣu to kọja.
Olootu Lebanon lo sọ bẹẹ.
Nigba to n bẹbẹ fun aanu nibi ipade kan to waye pẹlu United Nations organisations, Mikati beere fun iranlọwọ ti ko ni i pẹẹ rara.
Akọwe ọrọ ilẹ okeere ni UK, David Lammy, pẹlu Antony Blinken, akegbe rẹ lati US, sọ lọjọ Aje, pe o ṣe pataki ki igun mejeeji yii dẹkun ogun.
Wọn fi kun un pe o yẹ ki Palestine ti i ṣe akẹgbẹ Hezbollah, da awọn eeyan to mu sigbekun lọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023 silẹ, ki wọn maa lọ silee wọn.
Bakan naa ni ajọ European Union ti pe fun ipade pajawiri pẹlu ajọ alaabo UN.
Joseph Borrel lati EU, sọ pe "b’awọn ologun ba fi le tun da si wahala yii, yoo da kun ohun to wa nilẹ ni, a si gbọdọ dena iru ẹ ".
Israel àti Hamas fìdi ikú olórí Hamas ní Lebanon múlẹ̀
Ikọ mejeeji, Israel ati Hamas, ti fidi ẹ mulẹ pe wọn ti pa olori Hamas ni Lebanon, iyẹn Fateh Sherif Abu el-Amin, ninu ikọlu Israeli to waye ni Guusu Lebanon.
Awijare Israel ni pe Sherif lo n dari ikọlu Hamas ni Lebaon, wọn ni Hezbollah lo n lo.
Eeyan mẹta mi-in lo tun padanu ẹmi ni Aarin gbungbun Beirut lọjọ Aje, lagbegbe Kola.
Awọn mẹta naa jẹ ọmọ ẹgbẹ Liberation of Palestine (PFLP).
Atẹjade to kede awọn eeyan mẹta naa pe orukọ wọn ni: Mohammad Abdel-Aal, Imad Odeh ati Abdel Rahman Abdel-Aal.
Ija ẹnu aala to n waye tẹlẹ laaarin Israel ati Hezbollah tun lagbara si i lọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa ọdun 2023.
Eyi jẹ ọjọ keji lẹyin ọjọ ti Hamas ṣigun si Israel lati Gaza, nigba ti Hezbollah dana ogun ya Israeli nitori Palestine to n gbeja.













