Ìpè fún ìpàdé àwọn ọ̀dọ́, ọ̀rọ̀ àbò, ọ̀rọ̀ ajé àtàwọn kókó míràn tí Ààrẹ Bola Tinubu sọ fáwọn ọmọ Nàìjíríà àyájọ́ òmìnira

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti kede ipade gbogbogbo fun awọn ọdọ kaakiri Naijiria yoo waye laipẹ nibi ti wọn yoo ti jiroro lori awọn iṣọro to n dojukọ wọn atawọn ohun ti wọn reti lọdọ ijọba.

Tinubu lo sọ ọrọ naa lasiko to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ laaarọ oni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024, lati sami si ayẹyẹ ọdun kẹrinlelọgọta ti Naijiria gba ominira lọwọ oyinbo amunisin.

Aarẹ ni “a n dari loni lọna ati fun awọn ọmọ wa ni ọjọ iwaju to dara, ṣugbọn a mọ pe a ko ni le fun wọn ni ọjọ iwaju rere lai jẹ ki wọn lọwọ ninu rẹ.

“Fun idi eyii, inu mi dun lati kede fun yin pe ipade awọn ọdọ ni Naijiria yoo waye.

“Ipade naa yoo fun wọn lanfani lati jiroro lori idojukọ awọn ọdọ wa ti wọn jẹ ida ọgọta araalu.”

Tinubu sọ pe pade naa ti yoo waye fun ọgbọn ọjọ gbako, yoo si mu irẹpọ waye laarin awọn ọdọ kaakiri Naijiria lati le jiroro papọ lori awọn ọrọ bii eto ẹkọ, igbanisiṣẹ, eto abo, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O fi kun pe ijọba yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn aṣoju ọdọ lati yan awọ ti yoo ṣoju wọn fun ijiroro naa, ijọba yoo si ṣe ohun ti wọn ba bere lẹyin ipade naa.

Iwọnyii ni awọn koko ohun ti Aarẹ tun mẹnuba

  • Ijọba n ṣaṣẹyọri ninu igbiyanju rẹ lati ṣẹgun awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram lati ọdun kan sẹyin
  • Laarin ọdun kan sẹyin, ijọba ti ṣekupa olori Boko Haram ti iye wọn to ọọdunrun, bẹe naa lo tun ṣegun awọn janduku atawọn ajinigbe
  • Latari akitiyan ijọba, awọn oniṣowo ilẹ okeere ti ko owo to le ni biliọnu mọkanlelọgbọn dọla wa si Naijiria lati ṣowo
  • Ijọba n ṣamulo idajọ ilẹ to ga julọ ni Naijiria lati fun ijọba ibilẹ lagbara lori owo rẹ ati eto iṣuna rẹ
  • Ijọba n ṣe ohun gbogbo to yẹ lati fopin si ọwọngogo ounjẹ atawọn nnkan mii lawujọ
  • Ṣiṣamulo gaasi SNG fun awọn ọkọ ero igboro ki owo ọkọ le walẹ, fun idi eyii ijọba n ṣi awọn ojukọ ti araalu ti le lọ sọ ọkọ wọn di eyii to n lo gaasi CNG, bẹẹ ni ijọba tun n ko awọn ọkọ akero CNG wọle lati oke okun
  • Ipade gbogbogbo fun awọn yoo waye fun ọgbọn ọjọ, nibẹ ni wọn yoo ti jiroro nipa ohun ti wọn n fẹ lọwọ ijọba, ijọba yoo si ṣẹ ohun ti wọn ba bere lọwọ rẹ
  • Agbẹkalẹ eto Renewed Hope Labour Employment and Empowerment Programme (LEEP), eyii ti yoo pese iṣẹ to le miliọnu meji abọ fun awọn ọdọ