Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ níbi ìwọ́de ebi-ń-panú tí yóò wáyé ní Oct 1?

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Lọla, ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 ni awọn ọmọ Naijiria kan yoo ṣe iwọde nilu Abuja.
Ọjọ naa gan lo tun jẹ ayajọ ọjọ ti orilẹede Naijiria gba omira lọwọ ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi.
Gbagede Eagles Square to wa niluu Abuja ni iwọde naa yoo ti waye, gbagede yii kan naa si ni ayẹyẹ ayajọ ọdun kẹrinlelọgọta ti Naijiria gba ominira naa yoo waye.
Yatọ si Eagles Square, igbagbọ wa pe iwọde naa yo tun waye lawọn agbegbe mii lawọn ilu nla ni Naijiria.
Wayi o, awọn oluwọde naa ti sọ pe ko si ohunkohun ti yoo yẹ iwọde naa nitori bi ijọba fẹ, bo kọ, awọn yoo ṣe iwọde naa dandan ni.
Awọn wo lo n ṣagbatẹru iwọde Oct 1?
Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan kan lo wa nidi iwọde naa.
Lara awọn adari iwọde ọhun ni Omoyele Sowore, to jẹ ajafẹtọ ati oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC; Juwon Sanyaolu, to jẹ adari ajọ Take It Back Movement ni Naijiria; Damilare Ademola, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn ẹgbẹ wọnyii ti n ṣabatẹru iwọde ilu le ni Naijiria.
Ilẹ ti ta si ti awọn eeyan bii Sowore atawọn alatilẹyin rẹ ti n ṣe iwọde ni Naijiria, Sowore si ti foju ba ile ẹjọ lọpọ igba, koda o ti fi ọpọ oṣu wa ni ahamọ ijọba latari ijagbara rẹ.
Lara awọn iwọde ti Sowore ti ṣe onigbọwọ rẹ lẹnu ọdun diẹ si asiko yii ni ‘’Buhari Must Go, End Bad, Governance,” atawọn iwọde mii.
Ohun ti ifẹhonuhan Oct 1 da le lori
Nigba ti Sowore n sọrọ, o ni iwọde ọhun ko ṣẹyin ebi ọpagba to n pa araalu, eto abo to dẹnukọlẹ ati inira ti araalu n dojukọ lati igba ti Aarẹ Bola Tinubu ti gori alefa.
Sowore sọ pe “kaakiri gbogbo Naijiria ni iwọde naa yoo ti waye latari ebi to wa nigboro, eto abo to dagẹgẹ ati iya ti ijọba yii fi n jẹ araalu.”
Ajafẹ ọmọniyan naa ṣalaye pe awọn oluwọde ọhun ko ni fa wahala kankan lasiko iwọde naa, bẹẹ ni wọn ko ni da igboro ru.
O fi kun pe awọn ko ni wọgi le iwọde naa nitori idunkoko ijọba apapọ.
Sowore pari ọrọ rẹ pe awọn oluwọde ti ṣetan lati tu si igboro bẹrẹ lati aago meje aarọ ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun2024 yii lati fi ehonu wọn han.

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Igbesẹ wo ni ijọba n gbe?
Ileeṣe ọlọpaa ti bẹrẹ si n ko awọn agbofinro sawọn agbegbe to ṣeeṣe ki awọn oluwọde korajọ si bẹrẹ lati ọla lọ.
Ti iwọde ọhun ba waye, yoo jẹ iwọde keji ti yoo waye laarin oṣu meji pere ni Naijiria.
Ninu iwadii kan ti ileeṣe iroyin abẹle Punch ṣe, o jabọ pe ọlọpaa ti bẹrẹ si n ṣeto abo to nipọn kaakiri Naijiria.
Lara awọn ibi ti ọlọpaa ti bẹrẹ si n ṣọ lojulẹsẹ bayii ni agbegbe Eagle Square ilu Abuja ti ayẹyẹ ọjọ ominira yoo ti waye, to fi mọ awọn agbebe mii kaakiri awọn ilu nla nla ni Naijiria.
Ki ni yoo ṣẹlẹ lọla?
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọlọpaa fi ṣikun ofin mu ọpọ eeyan lasiko iwọde ilu le to kọja.
Yatọ si awọn ti ọlọpaa mu, ibọn ọlọpaa tun ṣekupa awọn mii lagbegbe Ariwa Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa sọ pe awọn ko pa oluwọde kankan, nigba ti Aarẹ n ba awọn araalu sọrọ, o ba awọn mọlẹbi awọn to ku kẹdun, eyii to mu ki awọn eeyan maa bere pe ti ọlọpaa ko ba ṣekupa ẹnikẹni, Aarẹ ko ni maa ba awọn eeyan kẹdun.
Wayi o, ko si ẹni to tii mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ nibi iwọde Oct 1 ọla, o di igba ti ilẹ ọla ba mọ.















