“Kò sí ohun tí yóò yẹ ìwọ́de Oct 1 tí a fẹ́ ṣe”

Aworan awọn oluwọde lasiko ìwọde niluu Ibadan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn onigbọwọ ìwọde #FearlessOctober ti kede síta pe ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ologun ati awọn ẹka agbofinro lorilẹede Naijiria ko ni le da awọn duro lati ma le ṣe ìwọde tako ijọba.

Awọn alasẹ ìwọde naa ti kọ lẹta si ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Kayode Egbetokun pe ko pese aabo lasiko ìwọde naa nitori ṣíṣe ìwọde jẹ ẹtọ gbogbo ọmọ Naijiria.

Orilẹede Naijiria yoo se ayẹyẹ ominira ọdun Kẹrinlelọgọta ni ọjọ Isẹgun, Ọjọ kini oṣu Kẹwaa, ọjọ ti ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti pinnu lati se ìwọde tako ilana eto ijọba Tinubu.

Awọn alasẹ ìwọde naa, Juwon Sanyaolu ati Damilare Ademola ni awọn araalu tí n sarajọ kaakiri orilẹede Naijiria fun ìwọde ọhun.

Wọn ni "A ti kọ lẹta si ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa pe ibi tí a ti fẹ ṣe ìwọde ree ati pe ofin Naijiria ni eto wa ni lati se ìwọde ti ileeṣẹ Ọlọpaa si ni lati pese aabo to peye," Sanyaolu salaye.

Ẹgbẹ naa ni ìwọde ti ilu Abuja yoo waye ni gbọngan Eagle Square, to jẹ ibudo ka naa tí ayẹyẹ ominira yoo ti waye.

Bakan naa ni ipinlẹ Eko, ìwọde naa yoo waye ni Ikeja ni abẹ afara.

Awọn alasẹ ìwọde naa ni ìwọde yoo waye ni gbogbo ipinlẹ lorilẹede Naijiri, ti wọn si fikun pe dídá owo iranwọ pada nìkan lo le da ìwọde naa duro.

Eeru ko ba wa rara - Sowore, Adeyanju

Ẹwẹ, ọkan lara awọn olori ìwọde naa, Omoyele Sowore ni awọn ọdọ kaakiri orilẹede Naijiria ko bẹru ileeṣẹ Ọlọpaa rara, to si jẹ ko di mimọ pe ìwọde naa waye bi wọn ṣe tí n gbero.

Ọga fun ileeṣẹ Ọlọpaa, Kayode Egbetokun ti paṣẹ fun awọn ọmọ ologun ileeṣẹ Ọlọpaa pe ki wọn duro digbi ni awọn ibudo tí ìwọde naa ti fẹ waye.

Sowore ninu alaye rẹ ni irọ to jina sotọ ni iroyin to ni wahala yoo bẹ silẹ lasiko ìwọde naa.

"Ẹnikẹni ninu wa ko ni ibẹru nitori a ki ṣe onijagidijagan boya kí a bere lọwọ ijọba."

Agbẹjọro fun ẹgbẹ naa, Deji Adeyanju ni o lodi si ofin pe ileeṣẹ Ọlọpaa ransẹ pe awọn oluwọde to n ṣe ẹtọ wọn.

"Ileeṣẹ Ọlọpaa ko ni àṣẹ lati ransẹ pe awọn oluwọde sugbọn isẹ wọn ní lati pese aabo lasiko ìwọde."

O ni ero ìjọba ni lati mu awọn oluwọde si ahamọ lati le ṣe ìwọde naa.

"Awọn oluwọde to kopa ninu ìwọde ninu oṣu kẹjọ si wa ni ahamọ sugbọn eyi ko ni ṣe idaduro fun wa."