Ọdún Ọlọ́jọ tún gbérasọ ní Ile-Ife, bí ètò ayẹyẹ náà ṣe lọ rè é

Ooni Ile Ife, Ọba Enitan Ogunwusi Ojaja Keji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọdún ọlọ́jọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọdún tó gbajúmọ̀ nílẹ̀ Yorùbá pàápàá ní ìlú Ile Ife.

Ìran Yorùbá gbàgbọ́ pé ìlú Ilé Ife ni Olódùmarè kọ́kọ́ dá àti pé ọdún Ọlọjọ jẹ ọdún lati fi ṣami ọjọ ti Olodumare da ile aye, bẹẹ si ni o jẹ ọdún tó ti pẹ ni ilẹ̀ Yorùbá.

O jẹ ọdun to maa n waye ni iranti Ogun to jẹ akọbi Oduduwa.

Gẹgẹ bi igbagbọ awọn ọmọ Yoruba, irinwó ati ẹyọ kan ni awọn Òrìṣà to wa ní Ilé-Ife, ipinlẹ Osun àti pe gbogbo wọn ni wọn ni ọjọ́ ti wọn maa n bọ wọn.

Saaju ayajọ ọdun yii Ọọni Ile Ife yoo ti wa ni igbele fun ọjọ meje nibi ti yoo ti maa se adura fun iran Yoruba ati orílẹ ede Naijiria lapapọ.

Lẹyin eyi ni Ọọni maa jade sita pẹlu Ade Are eyi ti igbagbọ wa pe ohun ni Oduduwa kọkọ dé.

Laaarin oṣu Kẹsan-an si oṣu Kẹwaa ọdun ni ọdun Ọlọjọ maa n waye.

Ọpọlọpọ àwọn eniyan kaakiri agbaye ni wọn maa n pejupese si Ile-Ifẹ lati ṣayẹyẹ ọdun Ọlọjọ.

Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́
Àwọn tó wá kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́