Àlàyé rèé lórí bí àwọn ère ìṣẹ̀mbáyé Naijiria ṣe dèrò mùsíọ́mù lókè òkun

Benin Art

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Adaobi Tricia Nwaubani
    • Role, Letter from Africa series
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile nla National Museum to wa niluu Eko lo kun fun oniruru awọn ere iṣẹmbaye, eyii to fi iṣẹ ọna ati aṣa Naijiria han.

Olugbile Holloway, ti wọn yan ninu ọdun yii gẹgẹ bii ọga agba ile nla naa ti sọ pe oun ko fẹ ki awọn ohun iṣẹnbaye ọhun kan a loju kan mọ.

O ni oun n fẹ maa ko wọn lọ awọn ilu to jẹ orisun awọn ere atawọn ohun iṣẹmbaye naa.

Ninu ọrọ rẹ, o ni o jọ bii pe kii ṣe ohun to bojumu nilẹ wa ki wọn kan ko awọn ere naa sinu ile kan ṣa.

Ọdun 1957 ni wọn da National Museum naa silẹ ninu eyii ti wọn ko oniruru awọn ere si lati igba aye awọn oyinbo amunilẹru.

Lara awọn ere to wa ninu National Museum ni eyii ti wọn ko lati Ile Ife, Benin, Ibibio, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

A person with a mask on walking next to someone holding a parasol

Oríṣun àwòrán, Herbert M Cole

Lọdun 1967, awọn ọmọ ilẹ Amẹrika meji, Charlie Cushman ati Herbert “Skip” Cole lọ kaakiri Naijiria lati ṣa awọn ere ati ohun iṣembaye naa.

Cushman, ti ọjọ ori rẹ ri ti to ẹni aadọrun ọdun bayii sọ pe o jẹ ohun idunnu fun oun lọdun n aa lọhun lati kaakiri agbegbe ila oorun Naijiria fun odidi oṣẹ meji gbako lati ṣa awọn ohun iṣembaye naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, lasiko naa, ojubọ ni wọn maa n ko awọn ere ọhun si tabi ki wọn ko wọn sinu iho apata.

Nigba naa, awọn olori ẹbi tabi mọgaji lo maa n ṣabojuto awọn ere naa lawọn irufẹ ojubọ bẹẹ.

Ọgbẹni Cole, ti oun naa ti to ẹni ọdun mọkadinlaadọrun sọ pe “ohun to ya mi lẹnu julọ nibẹ ni pe pupọ ninu awọn eeyan naa ko kọ lati jọwọ awọn ere atawọn ohun atijọ naa.

Cole ni “mo ni anfani lati ra ọpọ iboju fun dọla meji pere, iye owo iboju naa si to ọpọ dọla nilẹ Yuroopu nigba naa lọhun.

“Iye owo ti wọn jẹ ko fi bẹẹ ka awọn ẹya Igbo lara nigba naa.

“Wọn maa n lo awọn nnkan naa fun ayẹyẹ ibilẹ tabi ni ṣiṣe iranti awọn babanla wọn atawọn irunmọlẹ… boya eredi ree ti wọn fi le ta awọn ere naa latari pe ko wulo fun wọn mọ.”

A black and white photo of two men and some children standing on a bridge

Oríṣun àwòrán, Herbert M Cole

Àkọlé àwòrán, Herbert Cole (L) ati Charlie Cushman (R)
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọgbẹni Cushman kọ akọsilẹ nipa irinajo bo ṣe n lọ ṣa awọn ilu naa, akọsilẹ ọhun ṣi wa titi di oni yii lẹyin nnkan bii aadọta ọdun.

Cushman ati ekeji rẹ ni awọn rọ awọn to yipdada si ẹsin Kristẹni lọdun naa lọhun lati ma ba awọn ere naa jẹ latari igbagbọ wọn pe o jẹ ohun ti Satani.

Ninu akọsilẹ naa ni a ti ri olori ile ẹkọ ‘headmaster’ kan, ọgbẹni Akazi, to n dana sun gbogbo awọn ere ọhun latari itara rẹ fun ẹsin Krsitẹni.

Cole ni ọkunrin ọhun, ọgbẹni Akazi sọ pe “a ni lati dana sun gbogbo awọn ere wọnyii ki ọkan awọn eeyan wa le wa lọdọ Ọlọrun.”

Cole sọ pe gbogbo igbiyanju oun lati yi ọkan Akazi pada lo ja si pabo.

O ni “mo sọ fun un pe a n gbiyanju lati pa awọn nnkan yii mọ fun awọn iran to n bọ lọjọ ọla ṣugbọn o kọ jalẹ.

“Mo sọ pe a maa ko wọn lọ siluu Eko kaka ki wọn dana sun wọn nibi yii ti yoo ti maa dena ẹsin Kristẹni.”

O jọ bii ẹ ni pe ọkunrin naa yan lati ko awọn ere ọhun fun awọn ara ilẹ okere ju ko fi wọn silẹ laarin ilu lọ.

Wooden stature featuring several figures on display at museum

Oríṣun àwòrán, Adaobi Tricia Nwaubani

Àkọlé àwòrán, Ere Igbo

Akọroyin BBC to ba Cole ati ekeji rẹ sọrọ ni ọrọ naa mu oun ranti asiko ti oun lọ si Musium ilu London ti oun si n ya aworan nibẹ,

O ni awọn ọmọlẹyin Kristi kan nibẹ kọ lati ya aworan lẹgbẹ awọn ere iṣembaye ilẹ aulawọ to wa nibẹ niroti igbagbọ wọn ninu Jesu.

Latari bi wọn ṣe n ko awọn ere Naijiria lọ ilẹ okere lai bikita lo sokunfa iṣẹsidalẹ ajọ Nigerian Antiquities Service lọdun 1943.

Nigba ti yoo di ọdun 1945, wọn da musiọmu akọkọ silẹ ni Esie, niluu Jos wọn da musiọmu silẹ nibẹ lọdun 1952, ti wọn si da ti Ile Ife silẹ lọdun 1955.

Ọgbẹni Cole sọ pe apapọ awọn ere ati iboju iṣẹmbaye ti oun ri ṣa ni Naijiria le ni irinwo.

A woman paining a wall

Oríṣun àwòrán, Herbert M Cole