Israel ṣekúpa olórí Hezbollah, Hassan Nasrallah

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba Israel ti kede pe oun ti ṣekupa olori ọmọ ogun Hezbollah, Hassan Nasrallah.
Ileeṣẹ ọmọ ogun orilẹede naa, Israel Defense Forces (IDF), lo kede bẹẹ lọjọ Abmẹta.
Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ, IDF sọ pe “Hassan Nasrallah ko ni le maa ṣeruba awọn orilẹede agbaye mọ.”
Atẹjade naa lo waye lẹyin ti Israel sọ oniruru ado oloro siluu Beirut ti Nasrallah wa.
Israel sọ ṣaaju pe eredi awọn ado oloro ti oun fi ranṣe naa ko ṣẹyin ati gbẹmi Nasrallah atawọn olori Hezbollah mii.
Ta ni Hassan Nasrallah olori Hezbollah?
Sheikh Hassan Nasrallah, jẹ ọkan gboogi lara awọn gbajumọ ẹlẹsin Islam lagbegbe Middle East.
Fun ọpọlọpọ ọdun lawọn eeyan ko foju ganni rẹ laarin igboro, ti ọpọ si gbagbọ pe awọn ọmọ ogun Israel ti gbẹmi rẹ.
Labẹ idari Nasrallah, Hezbollah ti ṣe idanilẹkọọ fun ọpọ awọn jagunjagun Hamas lati Palestine.
Oun lo dari ẹgbẹ Hezbollah lati bẹrẹ si n kọju ija si Israel, o si ti pẹ ti Israel ti n gbiyanju lati gbẹmi rẹ.
Ọdun 1960 ni wọn bi Hassan Nasrallah, o si dagba lagbegbe Bourj Hammoud niluu Beirut nibi ti baba rẹ ti n ta ọja.
Oun ni akọbi awọn obi rẹ, o si ni aburo mẹjọ lẹyin rẹ.
Nigba to pe ẹni ọdun mejilelọgbọn lo di adari ẹgbẹ Hezbollah lọdun 1992 lẹyin ti ọkọ ofurufu ẹlikọpita Israel gbẹmi aṣaaju rẹ, Abbas al-Musawi.
Ohun to kọkọ ṣe lẹyin to di adari Hezbollah ni sisọ ado oloro si Israel lati gbẹsan iku Abbas al-Musawi.












