Àwọn ọmọ ogun wa nílẹ̀ Áfríkà ló dìde ìrànlọ́wọ́ láti kojú ìdìtẹ̀gbàjọba tó fẹ́ẹ́ wáyé ní Niger - Russia ṣàlàyé

Idanimọ asia ọmọ ogun ilẹ Niger

Oríṣun àwòrán, Reuters

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn alakoso orileede Russia ti sọ pe awọn ti ṣe iranlọwọ nla fun ilẹ Niger lati dabaru gbogbo eto iditẹgbajọba to fẹẹ waye nibẹ.

Russia sọ pe opin ọsẹ to kọja yii, tii ṣe ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni iditẹgbajọba fẹẹ waye lorileede Niger, ko to di pe awọn dide lati tete da si i.

Aarọ kutu ọjọ naa ni ado oloro ati awọn ibọn ogun bẹrẹ sii dun lakọlakọ ni olu-ilu ilẹ Niger tii ṣe Niamey, nibi ti ibujokoo agbara aarẹ wa, to fi mọ ileeṣẹ ọmọ ogun oju ofurufu.

Fun ọpọ wakati ni ọrọ fi di bi o ko le lọ, ki o yago lọna, nigba ti gbogbo eeyan bẹrẹ sii sa asala fun ẹmi ara wọn lasiko ikọlu ọhun.

Gbara ti ikọlu naa ti bẹrẹ ni awọn ọmọ ogun Niger naa ti koju rẹ, "nipa iranlọwọ ileeṣẹ ọmọ ogun orileede Russia ti wọn wa nilẹ Afrika," awọn alakoso lo sọ bẹẹ nilu Moscow lọjọ Aiku.

Ileeṣẹ ologun Russia sọ pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa ṣe iranlọwọ to ba yẹ, lati gbogun ti awọn to ba fẹẹ kogun ja wọn.

Bakan naa ni wọn sọ pe ohun gbogbo lo ti wa "labẹ akoso awọn adari bayii, labẹ iṣakoso Aarẹ Abdourahmane Tiani".

Awọn ọmọ ogun Russia nilẹ Afrika ti jẹ ọkan gboogi ninu atilẹyin fun awọn ijọba ologun lagbegbe Sahel, ti wọn ti n koju ipenija lati ọdọ awọn agbesunmọmi ti Jihadit.

Àwọn ológun kan lo dalẹ̀

Iṣọkan awọn ẹkun ipinlẹ Sahel to jẹ Niger, Mali ati Burkina Faso – sọ pe igbiyanju lati ditẹ gbajọba naa lo jẹ lati ọwọ awọn "ikọ ọmọ ogun ti wọn dalẹ, nipa erongba lati dabaru gbogbo eto lo ti wa."

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni awọn alakoso naa ko tii mẹnuba iye awọn ọmọ ogun ti wọn lọwọ ninu igbiyanju iditẹ gbajọba naa, tabi iye awọn to fara kaaṣa nibi ikọlu naa.

Bakan naa adari ijọba ologun nilẹ Niger, Tiani ti wọn bura fun lọdun to kọja lẹyin to gbajọba, ko tii jade sita lati sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa.

Lọjọ Aiku, ni ileeṣẹ iroyin orileede naa, NPA sọ pe ohun gbogbo lo ti n pada bọ sipo nigba ti awọn eeyan ti n ba eto ọrọ aje wọn lọ lakọtun.

Bẹẹ lawọn ologun ti wa kaakiri ilu lati gbogun ti oniruuru igbiyanju iditẹgbajọba to ba fẹẹ waye lorileede naa.

Ìjọba Niger sọ̀rọ̀ lórí ìgbìyànjú láti dìtẹ̀gbàjọba tó wáyé

Awọn ologun meji to gbe ibọn dani ni oju popo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ileeṣẹ amohunmaworan ti ijọba apapọ ni Niger ti sọ pe ikọlu to waye ni olu ilu orilẹ ede naa, Niamey lo jẹ igbiyanju lati dite gbajọba amọ ti iṣẹlẹ naa ti wa labẹ amojuto.

Ileeṣẹ amohunmaworan naa ni oriko ileeṣẹ Ologun kan to wa ninu ilu naa, Base 101 ni ikọlu naa ti waye.

Awọn iroyin to ti ṣaaju jade sọ pe awọn to fẹ ditẹ gbajọba naa gbiyanju lati fi awọn ọmọ ogun kan si ahamọ ti wọn si yinbọn mọ sawọn aaye to ṣe koko ni Niamey.

Niṣe ni iro ibọn n dun lakọlakọ, ti ado oloro si n dun kaakiri ni Niamey ni owurọ kutukutu ọjọ Abamẹta gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọn ni ikọlu naa waye ni ẹgbẹ papakọ ofurufu Diori Hamani, ileeṣẹ Ologun Base 101 ati ileeṣẹ aarẹ.

Olugbe Niamey kan sọ fun BBC pe awọn gbọ iro ibọn ati ikọlu ado oloro lati nnkan bii aago kan oru.

Niṣe ni ileeṣẹ amohunmaworan naa ko kọkọ ṣiṣẹ ni owurọ ọjọ Abamẹta ki wọn to bẹrẹ si ni ṣiṣẹ pada.

Awọn alaṣẹ ijọba ni Niger ti rọ awọn olugbe orilẹ ede naa lati fọkan balẹ, ki wọn si maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ, pe ohun gbogbo ti pada sipo.

Awọn fidio to gba ori ayelujara ṣafihan bi awọn araalu ṣe n tara si ikọlu naa.

Ileeṣẹ eto aabo sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe papakọ ofurufu ati awọn odi ti wọn fi yi ileeṣẹ aarẹ ka ni awọn to ṣe ikọlu naa koju si.

Asọfin AES sọ pe awọn ẹṣọ aabo tete ri akoso ileeṣẹ Ologun Base 101, ti wọn si juwe awọn to ṣe ikọlu naa bii agbeṣumọmi.

BBC ko I tii fidi eyi mulẹ.

Awọn alaṣẹ Niger ko i tii darukọ awọn ti wọn nigbagbọ pe o wa nidii ikọlu naa, ti ko si tii si atẹjade nipa iye eeyan to ba ikọlu naa lọ tabi farapa ninu iṣẹlẹ naa.